ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 5/8 ojú ìwé 9-12
  • Yíyan Ìkọ̀sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yíyan Ìkọ̀sílẹ̀
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ẹ Bá Ti Bímọ
  • Ọ̀ràn Ìnáwó àti Ọ̀ràn Òfin
  • Ipò Ìbátan Tó Yí Padà
  • Gbígbìyànjú Láti Kọ́fẹ Padà
  • Má Ṣe Sọ̀rètí Nù
  • Ohun Mẹ́rin Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—2010
  • Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ohun Táwọn Tọkọtaya Àgbàlagbà Lè Máa Ṣe Tí Wọn Ò Fi Ní Kọra Wọn Sílẹ̀
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ṣé Ìkọ̀sílẹ̀ Ló Máa Yanjú Ìṣòro Yín?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 5/8 ojú ìwé 9-12

Yíyan Ìkọ̀sílẹ̀

“Bí ẹnì kejì ẹ nínú ìgbéyàwó bá kú, ọ̀rọ̀ ẹ á yé àwọn ènìyàn, bí o kò tilẹ̀ fìgbà kan rí jẹ́ ìyàwó rere. Ṣùgbọ́n bí ọkọ ẹ bá já ẹ sílẹ̀—àwọn kan á rò pé o kò ṣe dáadáa tó ni. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jọ̀wọ́, Ẹ GBÀ MÍ O!”—Ẹnì kan tó máa ń ka Jí! ní Gúúsù Áfíríkà.

ÀÌṢÒÓTỌ́ nínú ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀ lè dani lórí rú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ti rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ẹnì kejì wọn kí ìgbéyàwó wọn sì máa wà nìṣó, àwọn mìíràn ní ìdí pàtàkì láti yan ohun tí Ọlọ́run là sílẹ̀ pé kí wọ́n jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún ẹnì kejì wọn tó ṣe panṣágà náà. (Mátíù 5:32; 19:9) Fún àpẹẹrẹ, ààbò, ipò tẹ̀mí, ire ìyàwó tó ṣe olóòótọ́ náà àti ti àwọn ọmọ rẹ̀ lè wà nínú ewu. Ó tún lè máa bẹ̀rù pé òun lè kó àrùn abẹ́ lára rẹ̀. Tàbí bóyá ó ti dárí panṣágà tí ọkọ rẹ̀ ṣe jì í, àmọ́, kí ó má fi bẹ́ẹ̀ rí ìdí láti retí pé àwọn ṣì lè fọkàn tán ara àwọn dáadáa àti pé òun ṣì lè máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ bí ọkọ òun.

Aya kan tí ọkàn rẹ̀ dàrú sọ pé: “Ìpinnu yìí ló ṣòro jù lọ fún mi láti ṣe láyé mi.” Ìpinnu tó ṣòro ni lóòótọ́—kì í ṣe kìkì nítorí pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ náà dùn ún gan-an ni ṣùgbọ́n nítorí pé aburú tó ń gbẹ̀yìn ìkọ̀sílẹ̀, tí yóò nípa lórí gbogbo ìgbésí ayé onítọ̀hún, pọ̀. Nítorí náà, bóyá ó yẹ kí ìyàwó kan kọ ọkọ rẹ̀ tó hùwà àìṣòótọ́ sílẹ̀ tàbí kó má kọ̀ ọ́ sílẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ ara ẹni. Ó yẹ kí àwọn ẹlòmíràn bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ tí ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà ní láti ṣe ìpinnu yẹn lójú ìwòye ohun tí Ìwé Mímọ́ wí.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń kù gììrì jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ láìkọ́kọ́ ronú dáadáa nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. (Fi wé Lúùkù 14:28.) Kí ni díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì tó ní í ṣe pẹ̀lú yíyan ìkọ̀sílẹ̀?

Bí Ẹ Bá Ti Bímọ

Ìwé Couples in Crisis sọ pé: “Àwọn òbí tí ìṣòro wọn ti dà láàmú gan-an sábà máa ń gbàgbé àìní àwọn ọmọ wọn tàbí kí wọ́n ṣàìnáání rẹ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, tí o bá ń ronú nípa jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀, má gbàgbé ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ àti bí ìgbésí ayé wọn ṣe máa rí. Ọ̀pọ̀ àwọn olùwádìí sọ pé bí ìkọ̀sílẹ̀ bá ṣe lọ nírọ̀wọ́-ǹ-rọ̀sẹ̀ tó ni ìyà kò fi ní lè jẹ àwọn ọmọ. Kódà, lábẹ́ àwọn ipò tó ṣòro, ìwàtútù yóò ran ẹnì kan lọ́wọ́ ‘láti má ṣe jà, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi.’—2 Tímótì 2:24, 25.a

Bí ẹnì kan bá yàn láti jáwèé ìkọ̀sílẹ̀, ó yẹ kí ó ní in lọ́kàn pé ọkọ àti ìyàwó ló ń kọra wọn sílẹ̀ kì í ṣe àwọn ọmọ. Àwọn ọmọ ṣì nílò Mọ́mì àti Dádì. Lóòótọ́, àwọn ìṣòro kan wà tó kọjá sísọ, bí ìgbà tí ewu híhùwà àìda sí ọmọ náà bá wà lórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò gbọ́dọ̀ sọ pé nítorí pé ìsìn àti èrò wa yàtọ̀ síra kí a wá máa fi àǹfààní níní òbí méjì du àwọn ọmọ.

A tún ní láti ronú nípa bí ìmọ̀lára àwọn ọmọdé ṣe jẹ́ ẹlẹgẹ́ tó àti bí wọ́n ṣe fẹ́ kí a máa mú nǹkan dá wọn lójú, kí a máa fi ìfẹ́ àti ìfẹ́ni hàn sí wọn léraléra. Ìwé kan sọ pé: “Ìfẹ́ tí a kò yé fi hàn sí wọn yìí yóò pèsè àlàyé nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn fún wọn àti ìpìlẹ̀ láti kojú ipò tuntun náà.” Ní àfikún sí i, fífiyèsí àwọn àìní wọn nípa tẹ̀mí lójoojúmọ́ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti forí tì í.—Diutarónómì 6:6, 7; Mátíù 4:4.

Ọ̀ràn Ìnáwó àti Ọ̀ràn Òfin

Ìkọ̀sílẹ̀ kì í ṣàìgba owó àti ohun ìní díẹ̀, ìwọ̀n ìdẹ̀ra díẹ̀, àti bóyá ibùgbé kan tí a fẹ́ràn dáadáa kúrò lọ́wọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tọkọtaya kan. Níwọ̀n bí ó ti lè ṣẹlẹ̀ pé kí owó tí ẹnì kan ń ná pọ̀ sí i nígbà tí owó tí ń wọlé kò sì tó nǹkan, ó dára láti ṣàkọsílẹ̀ ìwéwèé ìnáwó tó bọ́gbọ́n mu kan ní ìbámu pẹ̀lú bí àwọn ohun tí a fẹ́ náwó lé ti ṣe pàtàkì tó. A ní láti yẹra fún rírọni láti sanwó gbà-máà-bínú nítorí àdánù àti ẹ̀dùn ọkàn tí a fà nípa nínáwó púpọ̀ jù tàbí jíjẹ gbèsè.

Bí ẹ bá pinnu láti kọ ara yín sílẹ̀, ó tún pọn dandan láti dórí ìpinnu kan pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ nípa bí ẹ ó ṣe ṣe àwọn àkáǹtì tí ẹ fi orúkọ ẹ̀yìn méjèèjì ṣí ní báńkì. Fún àpẹẹrẹ, láti dènà lílo owó tó wà nínú àkáǹtì kan tí ẹ fi orúkọ ẹ̀yin méjèèjì ṣí nílòkulò, ó lè bọ́gbọ́n mu láti ní kí máníjà báńkì náà máa béèrè pé kí ẹ̀yin méjèèjì buwọ́ lùwé tí ẹ bá fẹ́ gba owó níbẹ̀ títí ìgbà tí olúkúlùkù yóò fi dá ní àkáǹtì tirẹ̀.

Ó tún bọ́gbọ́n mu láti máa ṣàkọsílẹ̀ pípéye nípa àwọn owó tí ń wọlé àti owó tí a ń ná, ní ìmúrasílẹ̀ fún ṣíṣètò gbígba owó ìgbọ́bùkátà. Bákan náà, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, òfin béèrè pé kí àwọn ènìyàn máa fi tó ilé iṣẹ́ owó orí létí tí ipò wọn bá yí padà.

Ní àfikún, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń jàǹfààní láti inú lílọ sọ́dọ̀ amòfin kan—ọ̀kan tó ní ìrírí pàtó nínú ọ̀ràn ìkọ̀sílẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè kan fàyè gba kí ẹni tó jẹ́ bí olùlàjà bá àwọn tọkọtaya dá sí ọ̀ràn wọn kí wọ́n lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tó ṣètẹ́wọ́gbà tí ó sì lálàáfíà, tí ilé ẹjọ́ yóò wá fọwọ́ sí. Níbi tí ọ̀ràn ọmọ bá ti wọ̀ ọ́, ọ̀pọ̀ òbí ń yàn láti fa iṣẹ́ náà lé amọṣẹ́dunjú kan tí kò ní gbè sẹ́yìn ẹnì kan. Dípò kí òbí kọ̀ọ̀kan máa wá bí ohun ìní tó pọ̀ jù lọ yóò ṣe bọ́ sọ́wọ́ òun, dídín ìforígbárí àti ìpalára kù ló ń jẹ wọ́n lógún jù. Àwọn ohun ìní kan tí yóò bọ́ síni lọ́wọ́ kò tó ẹ̀dùn ọkàn tí yóò kó báni àti owó tí yóò náni.

Ipò Ìbátan Tó Yí Padà

Olùwádìí kan sọ pé: “Kò yẹ kí a fojú kéré iyè méjì àti èrò tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ní pé àwọn ọ̀rẹ́ àwọn tí a kọ̀ sílẹ̀ kò mọ̀ ọ́n ṣe.” Kódà bí ẹnì kejì tó ṣe olóòótọ́ náà bá ní ẹ̀tọ́ sí ohun tó ń ṣe lábẹ́ òfin, ní ti ìwà rere, àti níbàámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́, àwọn kan lè wà tí wọ́n a máa rò pé òun ló fà á tí ìgbéyàwó náà fi tú ká. Wọ́n lè ṣíwọ́ kíkíni dáadáa tàbí kí wọ́n máa sá fúnni. Èyí tó burú jù lọ ni pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí wọ́n sún mọ́ni gan-an tẹ́lẹ̀ lè wá múni lọ́tàá lójú méjèèjì.

Ọ̀pọ̀ ni kò wulẹ̀ mọ bí ẹnì kan ṣe nílò ìtìlẹ́yìn tó nígbà tó bá ń kojú ọ̀ràn ìkọ̀sílẹ̀; wọ́n lè rò pé lẹ́tà tàbí káàdì kékeré kan ti tó. Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ kan máa ń wà tí ìwé Divorce and Separation sọ pé, “wọ́n mọ ohun tí a nílò gan-an, wọ́n á wá láti mọ̀ bóyá o fẹ́ kí wọ́n tẹ̀ lé ọ lọ síbikíbi, bóyá ó fẹ́ kí wọ́n bá ọ ṣe nǹkan tàbí bóyá ó wulẹ̀ ṣe ọ́ bíi pé kí o rí àwọn ènìyàn bá sọ̀rọ̀.” Ní gidi, ní irú àwọn àkókò yẹn nínú ìgbésí ayé ẹnì kan, ó nílò àwọn tí Bíbélì sọ nípa wọn pé, “ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.”—Òwe 18:24.

Gbígbìyànjú Láti Kọ́fẹ Padà

Ìyá kan sọ lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínlógún tó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ pé: “Mo ṣì máa ń nímọ̀lára ìdáwà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan—kódà tí mo bá wà láàárín àwọn ènìyàn pàápàá.” Báwo ló ṣe kojú ipò náà? Ó rántí pé: “Mo ń dènà ìmọ̀lára náà nípa mímú kí ọwọ́ mi dí níbi iṣẹ́, bíbójútó ọmọkùnrin mi, àti títọ́jú ilé. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo ń bá àwọn aládùúgbò mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí mo gbà gbọ́, mo sì ń ṣe àwọn nǹkan fún àwọn ẹlòmíràn. Ìyẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an.”

Àwọn déètì àti àkókò kan nínú ọdún lè múni rántí àwọn ohun tí ń dunni àti ìmọ̀lára kíkorò: ọjọ́ tí àṣírí ìwà àìṣòótọ́ náà tú, ìgbà tó jáde nílé, déètì tí a ṣe ẹjọ́ náà ní ilé ẹjọ́. Àwọn àkókò aláyọ̀ tí tọkọtaya náà máa ń gbádùn pọ̀ nígbà kan rí—bí àkókò ìsinmi àti àwọn ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ ìgbéyàwó—lè jẹ́ ohun tí ń rùmọ̀lára ẹni sókè tó ṣòro láti kápá. Pat sọ pé: “Mo máa ń kápá ẹ̀dùn ọkàn lọ́jọ́ wọ̀nyẹn nípa ṣíṣètò láti lọ bá ìdílé mi tàbí àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ tí wọ́n mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí mi ṣeré. A máa ń ṣe àwọn ohun tí yóò jẹ́ kí n gbà gbé àwọn ohun tó ti kọjá tí a ó sì sọ àwọn nǹkan tuntun. Ṣùgbọ́n ohun tó ràn mí lọ́wọ́ jù lọ ni ipò ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà—mímọ̀ pé ó lóye ìmọ̀lára mi.”

Má Ṣe Sọ̀rètí Nù

Àwọn tí wọ́n ṣe olóòótọ́ nínú ìgbéyàwó, tí wọ́n ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tí wọ́n sì yàn láti lo ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run fún wọn láti kọ ẹnì kejì wọn tó ṣe panṣágà sílẹ̀ kò ní láti máa rò pé àwọn jẹ̀bi tàbí kí wọ́n bẹ̀rù pé Jèhófà ti kọ àwọn sílẹ̀. Ipa ọ̀nà aládàkàdekè tí ẹnì kejì rẹ̀ tó ṣe panṣágà tọ̀—tó fa “ẹkún sísun àti ìmí ẹ̀dùn”—ni Ọlọ́run kórìíra. (Málákì 2:13-16) Kódà Jèhófà, tí í ṣe Ọlọ́run “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́,” mọ bó ṣe rí lára bí olólùfẹ́ kan bá kọni. (Lúùkù 1:78; Jeremáyà 3:1; 31:31, 32) Nítorí náà, jẹ́ kí ó yé ọ pé, “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.”—Sáàmù 37:28.

Ní ti gidi, yóò sàn jù bí a bá lè yẹra fún àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó àti àwọn aburú tó ń gbẹ̀yìn rẹ̀. Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé,b ìwé tí ń tọ́ ìdílé sọ́nà, tó sì gbéṣẹ́, ń ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ jákèjádò ayé láti gbé ìdílé tó láyọ̀ ró kí wọ́n sì yẹra fún àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó. Ó ní àwọn àkòrí tó ń sọ nípa níní ìgbéyàwó tó láyọ̀, títọ́ àwọn ọmọ, àti kíkojú àwọn ìṣòro tí ń yọjú nínú ìgbéyàwó. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí yóò láyọ̀ láti pèsè ìsọfúnni síwájú sí i fún ọ lórí kókó ọ̀rọ̀ yìí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A lè rí ìsọfúnni sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àbójútó Ọmọ—Kí Ni Èrò Oníwọ̀ntúnwọ̀nsì?” àti nínú àpilẹ̀kọ “Ríran Àwọn Ọmọ Òbí Akọrasílẹ̀ Lọ́wọ́,” nínú Jí!, December 8, 1997, àti April 22, 1991.

b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]

KÒ YẸ KÍ ÀWỌN ỌMỌ FOJÚ WINÁ ÌKỌ̀SÍLẸ̀ ÀWỌN ÒBÍ

Ní 1988, olóògbé Diana, Ìyàwó Ọmọba ilẹ̀ Wales, sọ pé ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nìkan, nǹkan bí okòólénírínwó [420] ọmọdé ni àwọn òbí wọn ń kọra sílẹ̀ lójoojúmọ́. Ìdá mẹ́ta àwọn ọmọdé náà ni kò tí ì pé ọmọ ọdún márùn-ún. Ó bani nínú jẹ́ pé nǹkan bí ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé ni kì í rí ọ̀kan lára àwọn òbí wọn mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá kọra wọn sílẹ̀.

Yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń rò, òǹkọ̀wé nípa ìlera àti ìṣègùn tí a bọ̀wọ̀ fún kan sọ pé, “ìwọ̀nba kéréje lára àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọ́n kọra sílẹ̀ ni inú wọn dùn sí ìkọ̀sílẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ yóò yàn láti rí i kí àwọn òbí wọn máa gbé pọ̀ kódà bí ìṣòro tilẹ̀ wà nínú ilé.” Bí ó bá tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé tọkọtaya kan máa ń jiyàn gan-an nígbà tí a hùwà àìṣòótọ́ náà, kò yẹ kí wọ́n kù gììrì pinnu pé fífòpin sí ìgbéyàwó yóò dára fún àwọn ọmọ. Yíyí ìṣesí àti ìwà wọn padà lè mú kí wọ́n lè gbé pọ̀ fún ire ìdílé lápapọ̀.

Òǹkọ̀wé Pamela Winfield sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ tí ń ṣèṣekúṣe ro ti àwọn ọmọ wọn tó fajú ro nígbà tí ilé bá fẹ́ pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ lẹ́yìn tí wọ́n hùwà burúkú wọn.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

ǸJẸ́ GBOGBO ÌKỌ̀SÍLẸ̀ NI ỌLỌ́RUN KÓRÌÍRA?

Pat sọ pé: “Ohun tó ń dà mí láàmú gan-an ni èrò pé ‘Jèhófà kórìíra ìkọ̀sílẹ̀.’ Gbogbo ìgbà ni ìbéèrè náà máa ń wá sọ́kàn mi pé, ‘Ǹjẹ́ ohun tí inú Jèhófà dùn sí ni mo ń ṣe?’”

Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ kí a wo àyíká ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Málákì 2:16 yẹn. Ní ìgbà ayé Málákì, ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ló ń kọ ìyàwó wọn sílẹ̀, bóyá nítorí àtifẹ́ àwọn obìnrin kèfèrí tò jẹ́ omidan. Ọlọ́run dẹ́bi fún ìwà ẹ̀tàn, aládàkàdekè yìí. (Málákì 2:13-16) Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run kórìíra ni lílé ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó dà nù láìnídìí nítorí àtifẹ́ òmíràn. Ẹni tó bá fẹ̀tàn ṣe panṣágà, tó wá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tàbí tó dà á láàmú láti kọ òun sílẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ àdàkàdekè, tí ó jẹ́ ìkórìíra.

Bí ó ti wù kí ó rí, ẹsẹ Bíbélì yìí kò dẹ́bi fún gbogbo ìkọ̀sílẹ̀. A lè fìdí èyí múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹni yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 19:9) Jésù fìdí ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ níhìn-ín pé ṣíṣe àgbèrè ni ìdí gidi tí a lè torí rẹ̀ jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ látàrí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí—ní gidi, òun nìkan ni ìdí gidi tí ó gbani láyè láti fẹ́ ẹlòmíràn. Ẹni tó ṣe olóòótọ́ náà lè pinnu láti dárí ji ẹnì kejì rẹ̀ tó dẹ́ṣẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹni tó bá yàn láti lo ọ̀rọ̀ Jésù gẹ́gẹ́ bí ìdí fún kíkọ ẹnì kejì rẹ̀ tó ṣe panṣágà sílẹ̀ kò ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra. Ìwà ẹ̀tàn tí aláìṣòótọ́ náà hù ni Ọlọ́run kórìíra.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ẹnì kejì tó ṣe olóòótọ́ náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ ń jàǹfààní ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́