Láti Inú Òógùn Àwọn Ọmọdé
“Ńṣe ni a ń ṣe àwọn ọmọdé, tí a ń kó ṣiṣẹ́ nísinsìnyí, bí ẹrù tí ń mówó wá dípò àwọn tí yóò wá di irú di igba láwùjọ wa lọ́jọ́ ọ̀la.”—Chira Hongladarom, olùdarí Àjọ Tí Ń Rí sí Ipa Ẹ̀dá Láwùjọ, Thailand.
NÍGBÀ tí o bá tún ra ohun ìṣeré fún ọmọbìnrin rẹ, rántí pé ó lè jẹ́ àwọn ọmọdé ní Ìlà oòrùn gúúsù Éṣíà ni wọ́n ṣe é. Nígbà tí ọmọkùnrin rẹ bá tún gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá kan, ronú wò pé ó lè jẹ́ ọmọdébìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta kan ló rán an, tí òun àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin mẹ́rin ń gba sẹ́ńtì márùndínlọ́gọ́rin lóòjọ́. Nígbà mìíràn tí o bá tún ra kápẹ́ẹ̀tì kan, ronú pé ó lè jẹ́ àwọn ọmọdékùnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà tí ọwọ́ wọ́n yá gan-an ni wọ́n ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí hun ún lójoojúmọ́ lábẹ́ ipò tí a ti ń fìyà jẹ wọ́n.
Báwo ni àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ ṣe gbalẹ̀ tó? Kí ló ń fi ojú àwọn ọmọdé rí? Kí ni a lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà?
Bí Ìṣòro Náà Ṣe Pọ̀ Tó
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé (ILO) ṣe sọ, a fojú díwọ̀n iye àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùn-ún sí mẹ́rìnlá tí a ń kó ṣiṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà sí àádọ́talénígba mílíọ̀nù.a A gbà gbọ́ pé ìpín mọ́kànlélọ́gọ́ta nínú ìpín ọgọ́rùn-ún wọn ló wà ní Éṣíà, ìpín méjìlélọ́gbọ̀n nínú ìpín ọgọ́rùn-ún ní Áfíríkà, àti ìpín méje nínú ìpín ọgọ́rùn-ún ní Látìn Amẹ́ríkà. Àwọn orílẹ̀-èdè onílé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá pẹ̀lú ń kó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́.
Ní ìhà gúúsù Yúróòpù, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ni a ń rí níbi iṣẹ́ àṣegbowó, ní pàtàkì àwọn iṣẹ́ tó ní sáà tí a ń ṣe wọ́n, bí iṣẹ́ àgbẹ̀, àti iṣẹ́ ọwọ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Láìpẹ́ yìí, àṣà kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ ti pọ̀ sí i ní Àárín Gbùngbùn àti Ìlà Oòrùn Yúróòpù lẹ́yìn tí wọ́n dẹ̀yìn lẹ́yìn ètò ìjọba Kọ́múníìsì tí wọ́n nawọ́ mú ètò ìjọba olówò bòńbàtà. Iye àwọn ọmọdé tí a ṣàkọsílẹ̀ wọn, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà jẹ́ mílíọ̀nù márùn-ún ààbọ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé tí wọn kò tí ì pé ọmọ ọdún méjìlá tí a gbà síṣẹ́ láìbófinmu ní àwọn ilé iṣẹ́ àṣelàágùn tí kò lówó lórí àti àwọn tí a gbà síṣẹ́ tó ní sáà tí a ń ṣe é tàbí bí òṣìṣẹ́ aṣíkiri nínú àwọn oko ńláńlá kò sí lára wọn. Báwo ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé wọ̀nyí ṣe wọ agbo àwọn òṣìṣẹ́?
Ohun Tó Fa Kíkó Àwọn Ọmọdé Ṣiṣẹ́
Fífi ipò òṣì ẹni yanni jẹ. Ìwé The State of the World’s Children 1997 sọ pé: “Fífi ipò òṣì ẹni yanni jẹ ni ohun tó lágbára jù lọ tó ń ti àwọn ọmọdé sínú iṣẹ́ eléwu, tí ń sọni di ahẹrẹpẹ. Ní ti àwọn ìdílé tó ṣe aláìní, ìwọ̀nba àǹfààní àtiṣiṣẹ́ tí owó tí ọmọ kan ń pa tàbí tó fi ń ṣètìlẹyìn nínú ilé ń pèsè fún àwọn òbí lè mú kí nǹkan túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí fún wọn.” Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn òbí tí àwọn ọmọ wọn kékeré ń ṣiṣẹ́ kò níṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí kí iṣẹ́ tí wọ́n ní máà pójú owó. Wọ́n máa ń wá owó tó pọ̀ tó lọ́nàkọnà. Nígbà náà, kí ló dé tó jẹ́ àwọn ọmọ wọn ni a wá fún ní àwọn iṣẹ́ náà dípò wọn? Nítorí pé a lè sanwó tí kò tó nǹkan fún àwọn ọmọdé. Nítorí pé àwọn ọmọdé kì í janpata, ó sì rọrùn láti darí wọn—ohunkóhun tí a bá ní kí púpọ̀ lára wọ́n ṣe ni wọ́n máa ṣe, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ pe aláṣẹ níjà. Nítorí pé kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe fún àwọn ọmọdé láti gbógun dìde nítorí ìnilára. Àti nítorí pé wọn kì í ṣíwọ́ sókè luni padà tí a bá lù wọ́n.
Àìkàwé. Ọmọdékùnrin Sudhir, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá láti Íńdíà, jẹ́ ọ̀kan lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé tó ti fi ilé ìwé sílẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Kí ló fà á? Ó fèsì pé: “Àwọn olùkọ́ kì í kọ́ wa dáadáa ní ilé ìwé. Bí a bá ní kí wọ́n kọ́ wa ní á-bí-dí, ńṣe ni wọ́n máa ń lù wá. Oorun ni wọ́n máa ń sùn ní kíláàsì. . . . Bí a kò bá mọ nǹkan kan, wọn ò ní kọ́ wa.” Ó bani nínú jẹ́ pé bí ilé ìwé ṣe rí gẹ́lẹ́ ni Sudhir sọ yẹn. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, dídín iye tí ìjọba ń ná lórí ètò ìfẹ́dàáfẹ́re kù ti ṣèpalára fún ètò ẹ̀kọ́ gidigidi. Ìwádìí kan tí àjọ UN ṣe ní 1994 ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlá lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà níwọ̀nba gbé àwọn kókó tó gbàfiyèsí jáde. Fún àpẹẹrẹ, ní ìdajì lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin péré nínú mẹ́wàá ni a pèsè àga ìjókòó fún ní àwọn iyàrá ìkàwé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ onípele kìíní wà. Ìdajì lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni kò ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìdajì lára àwọn iyàrá ìkàwé náà ni kò sì ní pátákó ìkọ̀wé. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé púpọ̀ lára àwọn ọmọ tí ń lọ sí irú àwọn ilé ìwé bẹ́ẹ̀ ló ń yí sí iṣẹ́ ṣíṣe.
Àwọn ohun tí àṣà ìbílẹ̀ ń fẹ́. Bí iṣẹ́ bá ṣe léwu tó tí ó sì le tó ni yóò fi ṣeé ṣe tó láti fi í sílẹ̀ fún àwọn ìran tí ó kéré, àwùjọ àwọn gbáàtúù, àwọn tí nǹkan ò ṣẹnuure fún, àti àwọn aláìní. Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé sọ nípa orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà pé, “èrò wọn ni pé a bí àwọn ènìyàn kan láti máa ṣàkóso kí wọ́n sì máa lo ọpọlọ wọn nígbà tí a bí àwọn mìíràn, àwọn tí wọ́n pọ̀ jù lọ, láti máa fi ara wọn ṣiṣẹ́.” Ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Ayé, ìṣarasíhùwà wọn kò fi bẹ́ẹ̀ sàn ju ìyẹn lọ. Àwùjọ àwọn tí ń ṣàkóso kì í fẹ́ kí àwọn ọmọ tiwọn ṣe iṣẹ́ tó léwu, ṣùgbọ́n kò ṣe wọ́n ní nǹkan kan bí àwọn èwe tó wá láti inú àwọn ẹ̀yà àti ìran tí ó kéré, tàbí àwọn tí kò lọ́rọ̀ bá ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Turkey tàbí Áfíríkà ni àwọn ọmọdé tí a ń kó ṣiṣẹ́ ní ìhà àríwá Yúróòpù; kí àwọn tí a ń kó ṣiṣẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Éṣíà tàbí Látìn Amẹ́ríkà. Àwùjọ ìgbàlódé kan tí èrò ríra nǹkan púpọ̀ sí i ṣáá ti gbà lọ́kàn ló mú kí àṣà kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ burú sí i. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń fẹ́ ohun tí kò wọ́n. Ó jọ pé àwọn díẹ̀ ló ń ṣàníyàn nípa pé ó lè jẹ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ tí a kò mọ̀, tí a ń fọmọdé yàn jẹ ló ṣe wọ́n.
Àwọn Oríṣi Iṣẹ́ Tí Ọmọdé Ń Ṣe
Irú iṣẹ́ wo ni a ń kó àwọn ọmọdé ṣe? Ní gbogbo gbòò, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé tí a ń kó ṣiṣẹ́ ló jẹ́ iṣẹ́ ilé ni wọ́n ń ṣe. A máa ń pe àwọn tí ń ṣe irú iṣẹ́ wọ̀nyẹn ní “àwọn ọmọ tí a gbàgbé jù lọ lágbàáyé.” Kò yẹ kí àwọn iṣẹ́ ilé léwu nínú, àmọ́ ó sábà máa ń léwu. Ó jọ pé a kì í sanwó dáadáa fún àwọn ọmọdé tí ń ṣe iṣẹ́ ilé—tàbí kí a tilẹ̀ máà máa sanwó fún wọn rárá. Àwọn ọ̀gá wọn nìkan ló ń pinnu ipò àti irú iṣẹ́ tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe. A ń fi ìfẹ́ni, lílọ sílé ìwé, eré, àti kíkópa nínú ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà dù wọ́n. Wọ́n tún rọrùn láti fìyà jẹ àti láti bá ṣèṣekúṣe.
Àwọn ọmọdé mìíràn bá ara wọn ní ipò òṣìṣẹ́ tí a fi dúró fún gbèsè, tí a sì ń fipá mú ṣiṣẹ́. Ní Gúúsù Éṣíà, àti ní àwọn àgbègbè mìíràn, àwọn òbí sábà máa ń fi àwọn ọmọ wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án péré ṣe pàṣípààrọ̀ fún gbèsè owó díẹ̀ tí wọ́n jẹ àwọn onílé-iṣẹ́ ẹ̀rọ tàbí àwọn aṣojú wọn. Iṣẹ́ ìsìnrú tí àwọn ọmọdé náà yóò fi gbogbo ayé wọn ṣe kì í tilẹ̀ dín gbèsè náà kù rárá.
Ọ̀ràn ti sísọ ìṣekúṣe di òwò ìyànnijẹ fún ọmọdé ńkọ́? A fojú díwọ̀n pé ó kéré tán, mílíọ̀nù kan àwọn ọmọdébìnrin ni a ń tàn wọnú òwò iṣẹ́ aṣẹ́wó lọ́dọọdún níbi gbogbo lágbàáyé. Bákan náà ni a sábà máa ń yan àwọn ọmọdékùnrin jẹ nípa bíbá wọn ṣèṣekúṣe. Ìpalára nípa ti ara àti ìmọ̀lára tí irú ìwà àìda yìí ń fà—kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ti kíkó àrùn fáírọ́ọ̀sì HIV—mú kí ó jẹ́ ọ̀kan lára oríṣi àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ tó léwu jù lọ. Aṣẹ́wó kan láti Senegal, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Ojú tí àwọn ènìyàn fi ń wo àwọn aṣẹ́wó ni wọ́n fi ń wo àwa náà láwùjọ. Kò sí ẹni tó fẹ́ mọ̀ wá tàbí tó fẹ́ kí wọ́n rí wa pẹ̀lú òun.”b
Púpọ̀ lára àwọn ọmọdé tí ń ṣiṣẹ́ ni a ń kó ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ẹ̀rọ àti lóko ọ̀gbìn. Irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó níbi iṣẹ́ ìwakùsà tí a lè kà sí èyí tó léwu gan-an fún àwọn àgbàlagbà. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni ikọ́ ẹ̀gbẹ, àrùn gbọ̀fungbọ̀fun, àti ikọ́ fée ti ń hàn léèmọ̀. Àwọn ọmọdé tí ń ṣiṣẹ́ lóko ọ̀gbìn ni ejò ń bù wọ́n jẹ, ni kòkòrò ń ta, tí oògùn apakòkòrò sì ń yọ wọ́n lẹ́nu. Àwọn kan ti ṣèèṣì fi àdá tí wọ́n fi ń gé ìrèké ba ẹsẹ̀ ara wọn jẹ́. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé mìíràn ti sọ ojú pópó di ibi iṣẹ́ wọn. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Shireen, ọmọ ọdún mẹ́wàá, tó mọ̀ dáadáa nípa iṣẹ́ ṣíṣa ohun tó wúlò lórí àkìtàn yẹ̀ wò. Kò fẹsẹ̀ tẹ ilé ìwé rí, ṣùgbọ́n ọ mọ̀ nípa ọ̀ràn káràkátà dáadáa. Bí ó bá pa tó ọgbọ̀n sẹ́ńtì sí ìdajì dọ́là Amẹ́ríkà láti inú bébà àti láílọ̀nù tó ń tà, á jẹun ọ̀sán. Bí kò bá pa tó iye yẹn, kò ní jẹun. A tún máa ń hùwà àìda sí àwọn ọmọ asùnta tí wọ́n sábà ń sá kúrò nílé nítorí ìwà àìda tí a ń hù sí wọn tàbí nítorí pé a ń pa wọ́n tì, a sì máa ń yàn wọ́n jẹ. Josie, ọmọ ọdún mẹ́wàá kan tó ń ta mindin-mín-ìndìn ní àwọn títì ìlú ńlá kan ní Éṣíà, sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà lójoojúmọ́ pé kí n máà kó sọ́wọ́ àwọn ẹni ibi.”
A Ba Ìgbà Ọmọdé Wọn Jẹ́
Nítorí àbájáde irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tí a ń kó àwọn ọmọdé ṣe, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé ló ń kojú àwọn ewu lílekoko. Èyí lè wá láti inú irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tàbí kí ó jẹ́ inú ipò tí kò dára tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ náà. Ó jọ pé jàǹbá tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tí a ń kó ṣiṣẹ́ máa ń le ju èyí tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn àgbàlagbà lọ. Èyí jẹ́ nítorí pé ìgbékalẹ̀ ara ọmọdé kan yàtọ̀ sí ti àgbàlagbà. Iṣẹ́ líle lè tètè ba eegun ẹ̀yìn tàbí ti ìgbáròkó rẹ̀ jẹ́. Bákan náà, àwọn ọmọdé máa ń jìyà ju àwọn àgbàlagbà lọ tí wọ́n bá wà níbi tí kẹ́míkà tàbí ìtànṣán olóró ti lè pa wọ́n lára. Ní àfikún sí i, iṣẹ́ àṣekúdórógbó fún ọ̀pọ̀ wákàtí, tí a sábà máa ń kó àwọn ọmọdé ṣe, kò bá wọn lára mu. Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn ewu tó so mọ́ ọn, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣọ́ra.
Ipa burúkú tí iṣẹ́ tí a ń kó àwọn ọmọdé wọ̀nyí ṣe ń ní lórí agbára ìrònú òun ìhùwà, ìmọ̀lára, àti làákàyè wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà kò kéré pẹ̀lú. A ń fi ìfẹ́ni du irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀. Lílù wọ́n, sísọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, fífi ebi pa wọ́n, àti bíbá wọn ṣèṣekúṣe wọ́pọ̀ gan-an. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti sọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára nǹkan bí àádọ́talénígba mílíọ̀nù ọmọdé tí ń ṣiṣẹ́ tó jẹ́ pé sísá ni wọ́n sá kúrò ní ilé ìwé. Ní àfikún sí i, a ti ṣàkíyèsí pé agbára àtikẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọdé tí ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí kò gbéṣẹ́ tó.
Kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé tí a ń kó ṣiṣẹ́ ni a ti sọ di òtòṣì, ni a ń ni lára, ni a ti sọ di aláìsàn, aláìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, àti aláìbẹ́gbẹ́mu ní gbogbo ìgbésí ayé wọn. Tàbí, gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn Robin Wright ṣe sọ ọ́, “lójú gbogbo ìtẹ̀síwájú tí ayé ti ní nínú ìmọ̀ sáyẹ́ńsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, ó ṣì ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé tó jẹ́ agbára káká ni wọ́n fi ní ìrètí àtilo ìgbésí ayé wọn bó ṣe yẹ, ní òpin ọ̀rúndún ogún yìí, ká má tí ì máa sọ ti mímú ayé wọnú ọ̀rúndún kọkànlélógún.” Èrò amúniṣe-wọ̀ọ̀ wọ̀nyí fa ìbéèrè náà pé: Ìwà wo ló yẹ ká máa hù sí àwọn ọmọdé? Ǹjẹ́ a lè rí ojútùú èyíkéyìí sí ìṣòro àṣà kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ lọ́nà àìda?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní gbogbo gbòò, àjọ ILO fi lélẹ̀ pé, kí a tó lè gba àwọn ọmọdé láyè láti ṣiṣẹ́, ó kéré tán wọ́n gbọ́dọ̀ pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún—ìyẹn bí wọ́n bá lè parí ìwọ̀n ẹ̀kọ́ tó pọndandan kí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yẹn tó pé. Ìlànà yìí ni a ń lò jù lọ níbi púpọ̀ tí a bá fẹ́ mọ iye àwọn ọmọdé tí ń ṣiṣẹ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ jákèjádò ayé.
b Láti rí ìsọfúnni sí nípa àwọn ọmọdé tí a ń bá ṣèṣekúṣe, wo ojú ìwé 11 sí 15 Jí!, ìtẹ̀jáde ti April 8, 1997.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Kí Ni Àṣà Kíkó Ọmọdé Ṣiṣẹ́?
ÈYÍ tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọdé ló ń ṣiṣẹ́ lọ́nà kan tàbí òmíràn ní gbogbo àwùjọ ẹ̀dá. Irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yàtọ̀ láwùjọ kan sí òmíràn láàárín àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Iṣẹ́ lè kó ipa pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé, kí ó sì jẹ́ ọ̀nà tí àwọn òbí ń gbà tàtaré àwọn òye pàtàkì sí wọn. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọmọdé sábà máa ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi iṣẹ́ ọwọ́ àti àwọn iṣẹ́ òwò pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọn á wá di ẹni tó mọṣẹ́ dunjú lọ́jọ́ iwájú. Ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, àwọn ọ̀dọ́langba máa ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí díẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kí wọ́n lè ní owó lọ́wọ́. Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé sọ pé irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ “ń ṣàǹfààní, ó ń mú kí ọmọ kan lè dàgbà di ọ̀jáfáfá ní ìrísí, èrò inú, ipò tẹ̀mí, ìwà rere tàbí láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà láìsí pé ó dí ilé ẹ̀kọ́, eré ìtura àti ìsinmi rẹ̀ lọ́wọ́.”
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ jẹ́ ọ̀ràn nípa àwọn ọmọdé tí ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́, tí a ó wá san owó ọ̀yà tí kò tó nǹkan fún, èyí sì máa ń jẹ́ lábẹ́ ipò tó lè ṣèjàǹbá fún ìlera wọn. Ìwé The State of the World’s Children 1997, sọ pé ó “ṣe kedere” pé irú iṣẹ́ yìí “ń ṣèpalára tàbí kí ó jẹ́ èyí tí a fi yàn wọ́n jẹ. Kò sí ẹni tó lè jiyàn ní gbangba pé yíyan àwọn ọmọdé jẹ nípa fífi wọ́n ṣe aṣẹ́wó bójú mu nínú ipò èyíkéyìí. A lè sọ ohun kan náà nípa ‘fífi ọmọ dí gbèsè’, ọ̀rọ̀ tí a máa ń sábà lò fún àṣà fífi ọmọ ṣe ẹrú lọ́nà kan ṣáá, láti san gbèsè tí àwọn òbí tàbí àwọn òbí àgbà ọmọ náà jẹ. Èyí tún kan àwọn ilé iṣẹ́ tí a mọ̀ dáadáa pé wọ́n máa ń wu ìlera àti ààbò léwu . . . Iṣẹ́ eléwu kò wulẹ̀ dára fún gbogbo ọmọdé.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
“A Ṣì Ní Ohun Púpọ̀ sí I Láti Gbé Ṣe”
ÀJỌ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé (ILO) ń mú ipò iwájú nínú ìsapá láti mú oríṣi àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ tí ó burú jù lọ kúrò. Àjọ ILO ń rọ àwọn ìjọba láti ṣe òfin tí ń fagi lé àṣà kíkó àwọn ọmọdé tí kò tí ì pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣiṣẹ́. Ó tún ń ṣagbátẹrù mímú kí àwọn ìjọba ṣe àwọn àdéhùn tuntun láti fòfin de àṣà kíkó àwọn ọmọdé tí kò tí ì pé ọmọ ọdún méjìlá ṣiṣẹ́ àti láti fòfin de oríṣiríṣi ọ̀nà líléwu jù lọ tí a ń gbà yan àwọn ọmọdé jẹ. Láti mọ̀ sí i nípa bí àwọn ìsapá wọ̀nyí ṣe kẹ́sẹ járí tó, Jí! fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú Sonia Rosen, olùdarí Ètò Tí Ń Rí Sí Àṣà Kíkó Ọmọdé Ṣiṣẹ́ Jákèjádò Ayé, ní Ẹ̀ka Àbójútó Ọ̀ràn Òṣìṣẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó ti ń ṣiṣẹ́ ní ifẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú onírúurú ètò tí àjọ ILO ṣe. Díẹ̀ lára ìjíròrò náà nìyí.
Ìbéèrè: Ọ̀nà wo ló gbéṣẹ́ jù lọ láti ṣẹ́pá àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́?
Ìdáhùn: A ò ní ìdáhùn pàtó kan sí ìbéèrè yẹn. Àmọ́, tí a bá wò ó jákèjádò ayé, àwọn kókó tí a ti jíròrò ṣe pàtàkì, ìyẹn ni, ṣíṣe òfin tó kájú ìwọ̀n papọ̀ pẹ̀lú pípèsè ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ fún gbogbo gbòò, tí yóò dára jù tí a bá fi dandan lé e kí ó sì jẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́. Dájúdájú, ó tún ṣe pàtàkì kí àwọn òbí ní iṣẹ́ tó kájú ìwọ̀n.
Ìbéèrè: Ǹjẹ́ àṣeyọrí tí ẹ ti ṣe láti ṣẹ́pá àṣà kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ ní báyìí ti tẹ́ yín lọ́rùn?
Ìdáhùn: Kò tí ì tẹ́ mi lọ́rùn rárá. A ní a kò fẹ́ kí ọmọdé kankan máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ ipò tí a ti ń fìyà jẹ ẹ́. Ìtẹ̀síwájú púpọ̀ ti wà láti inú àwọn ètò tí àjọ ILO ṣe. Àmọ́, a ṣì ní ohun púpọ̀ sí i láti gbé ṣe.
Ìbéèrè: Kí ni èrò àwùjọ àgbáyé nípa ìsapá láti mú àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ kúrò?
Ìdáhùn: Mi ò mọ bí mo ṣe lè dáhùn ìbéèrè yẹn mọ́. Ní báyìí, a ti fohùn ṣọ̀kan dé àyè kan jákèjádò ayé pé a ní láti gbéjà ko àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́. Mo rò pé ohun tó yẹ ká máa béèrè báyìí ni pé: Báwo lá ó ṣe ṣe é, àti báwo ni yóò ṣe yá tó? Àwọn ohun wo ló dára jù láti fi gbéjà ko àwọn oríṣi àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ kan? Mo rò pé ìpèníjà gan-an tí a ní nìyẹn.
Ìbéèrè: Kí ni àwọn ọmọdé tí a ń kó ṣiṣẹ́ lè máa wọ̀nà fún láìpẹ́?
Ìdáhùn: Gbogbo orílẹ̀-èdè àgbáyé kò ní pẹ́ padà lọ sí Geneva lọ́dún yìí láti lọ fìdí àdéhùn tuntun kan múlẹ̀ lórí ọ̀ràn oríṣi àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ tó burú jù lọ. A ń fojú sọ́nà gan-an pé yóò ṣẹnuure—gbogbo orílẹ̀-èdè, àti àjọ àwọn òṣìṣẹ́ àti àjọ àwọn agbanisíṣẹ́. A retí pé kí ìyẹn dá ètò tuntun sílẹ̀ tí a gbé kalẹ̀ nítorí àtifòpin sí àwọn oríṣi àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ tó burú jù lọ.
Gbogbo èèyàn kọ́ ló ní èrò rere bíi ti Sonia Rosen. Charles MacCormack, ààrẹ Àjọ Aṣèrànwọ́ Fọ́mọdé, ní èrò tó yàtọ̀. Ó sọ pé: “Ètò tí ìjọba ń fẹ́ ṣe nípa ìṣòro náà àti pé gbogbo ìlú mọ̀ nípa rẹ̀ kọ́ ló máa yanjú rẹ̀.” Èé ṣe? Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé sọ pé: “Ọ̀ràn dídíjú ni ọ̀ràn nípa àṣà kíkó ọmọdé ṣiṣẹ́ sábà máa ń jẹ́. Àwọn lóókọlóókọ ló wà nídìí rẹ̀, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn agbanisíṣẹ́, àwọn ẹgbẹ́ tí ń jàǹfààní àrà ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀ àti àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé tí ń dámọ̀ràn pé gbogbo ènìyàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti wà lágbo ìṣòwò lọ́nàkọnà, àti àwọn olófin àtọwọ́dọ́wọ́ tí wọ́n gbà gbọ́ pé àwùjọ àwọn ọmọdé kan ń fi ẹ̀tọ́ du àwọn.”
[Àwòrán]
Sonia Rosen
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ṣíṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó ní àwọn ibi ìwakùsà àti ilé iṣẹ́ ìhunṣọ wà lára ìtàn bíbaninínújẹ́ tí àṣà kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ ní
[Credit Line]
Àwọn fọ́tò U.S. National Archives
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ṣíṣa nǹkan lórí àkìtàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ṣíṣiṣẹ́kára láti ṣa igi ìdáná
[Credit Line]
FỌ́TÒ ÀJỌ UN 148046/ J. P. Laffont - SYGMA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
A gbà wọ́n síṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìrànwú
[Credit Line]
CORBIS/Dean Conger
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn ọmọdé tí ń kiri ọjà ní òpópó ń gba sẹ́ǹtì mẹ́fà péré lóòjọ́
[Credit Line]
FỌ́TÒ ÀJỌ UN 148027/Jean Pierre Laffont
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ṣíṣiṣẹ́kára ní ibi iṣẹ́ káfíńtà kan
[Credit Line]
FỌ́TÒ ÀJỌ UN 148079/ J. P. Laffont - SYGMA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ṣíṣiṣẹ́kára láti rí nǹkan gbọ́ bùkátà
[Credit Line]
FỌ́TÒ ÀJỌ UN 148048/J. P. Laffont - SYGMA