Ọlọ́run Ló Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
BÍ FRANCISCO COANA ṢE SỌ Ọ́
Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin kìlọ̀ fún mi pé: “Bóò bá gbọ́ràn sí àwọn aláṣẹ lẹ́nu, wọ́n á pa ẹ́!”
Mo dá họ̀ọ́-ọ̀ rẹ̀ pé: “Ìyẹn á tiẹ̀ dáa ju wàhálà téèyàn wà nínú ẹ̀ yìí lọ.”
Ọ̀RỌ̀ tí èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin sọ ní September 1975 nìyẹn. Oúnjẹ ló gbé wá fún mi nígbà tí mo ń ṣẹ̀wọ̀n ní Màpútò (tí a ń pè ní Lourenço Marques nígbà yẹn), ní gúúsù Mòsáńbíìkì. A lé ní ọgọ́sàn-án, tí àwọn tó pọ̀ jù lára wá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n rọ́ lù sínú iyàrá ẹ̀wọ̀n kan ṣoṣo. Inú bí ẹ̀gbọ́n mi sí mi gan-an tí kò fi gbé oúnjẹ tó gbé wá fún mi sílẹ̀!
Kí ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìpàdé tó ru ìgbónára sókè yìí lè yé yín, ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó sọ mí dèrò ẹ̀wọ̀n fún yín.
Fífi Ìsìn Kọ́ Wa
Wọ́n bí mi ní ọdún 1955 sínú ìdílé onísìn Presbyterian ní abúlé Calanga ní Àgbègbè Manica. Ibẹ̀ ò jìnnà sí ìlú ńlá Màpútò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bàbá mi kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, Ìyá mi máa ń lọ, ó sì máa ń kó àwa ọmọ rẹ̀ márààrún lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní gbogbo ọjọ́ Ọ̀sẹ̀. Nígbà tí a ṣì kéré, ó kọ́ wa ní Àdúrà Olúwa, mo sì máa ń kà á lórí lọ́pọ̀ ìgbà. (Mátíù 6:9-12) Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọdé, mo máa ń béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ màmá mi, àwọn ìbéèrè bíi “Kí ló dé tí a fi ń kú?” àti, “Ṣé àwọn èèyàn ò ní yé kú ni?”
Màmá mi sọ pé ikú jẹ́ ọ̀kan lára ète Ọlọ́run—pé àwọn tí ń ṣe búburú yóò lọ sí ọ̀run àpáàdì, àwọn tí ń ṣe rere yóò sì lọ sí ọ̀run rere. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò fèsì, ìdáhùn rẹ̀ bà mí nínú jẹ́. Ìbànújẹ́ tí ikú ń fà dààmú mi, ní pàtàkì nígbà tí bàbá wa ọ̀wọ́n kú nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá péré. Lẹ́yìn náà, ó máa ń wù mí gan-an láti mọ̀ nípa ipò tí àwọn òkú wà àti bóyá wọ́n ní ìrètí kankan.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ àti Fífi Í Sílò
Gbàrà lẹ́yìn tí Bàbá mi kú, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa lo ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada láti kọ́ wa ní kíláàsì. Èdè Zulu, tó jẹ́ èdè Gúúsù Áfíríkà ni Watch Tower Bible and Tract Society fi kọ ìwé náà. Olùkọ́ náà yá mi ní ìwé náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò gbọ́ èdè Zulu dáadáa, inú mi dùn sí ohun tí mo kọ́ láti inú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí nínú rẹ̀.
Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, wọ́n ránṣẹ́ wá mú ẹ̀gbọ́n mi tó ń gbọ́ bùkátà ìdílé wa láti wọ iṣẹ́ ológun. Ìgbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe lọ́fínńdà ní Màpútò, mo sì ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ kan lálaalẹ́. Lákòókò ìsinmi ọ̀sán, mo máa ń ṣàkíyèsí Teófilo Chiulele, tó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—ó sábà máa ń ka Bíbélì. Nígbà tí Teófilo ṣàkíyèsí pé mo ń fìfẹ́ hàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá mi sọ̀rọ̀.
Nígbà tó yá, Ẹlẹ́rìí mìíràn, Luis Bila, bẹ̀rẹ̀ sí bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ara tù mí láti mọ̀ pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan àti pé wọ́n ní ìrètí pé a óò mú wọn padà wá sí ìyè nígbà àjíǹde. (Oníwàásù 9:5, 10; Jòhánù 5:28, 29) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo kọ̀wé sí màmá mi, tí mo sì fi Bíbélì dáhùn àwọn ohun tí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Inú rẹ̀ dùn láti mọ̀ pé mo ti rí ìdáhùn tó ṣeé gbíyè lé níkẹyìn.
Bí ohun tí mo ń kọ́ ti ń jẹ mí lọ́kàn, mo múra láti ṣàjọpín àwọn ohun wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n gbà mí láyè láti máa sọ ọ̀rọ̀ lórí Bíbélì ní ilé ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n wọn kò gbà mí láyé ní ṣọ́ọ̀ṣì. Láìpẹ́, wọn kò jẹ́ kí n wọ ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Kódà, àwọn mẹ́ńbà ìdílé tèmi alára bẹ̀rẹ̀ sí ṣenúnibíni sí mi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú màmá mi dùn sí ìsìn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin lù mí lálùbami. Nígbà tí àwọn àtakò wọ̀nyẹn kò yọrí sí bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé mi ṣe fẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, pàápàá nígbà tí wọ́n ń rí i tí mo ń gbàdúrà nígbà tí a bá fẹ́ jẹun. Nítorí náà, ńṣe ni mo máa ń gbàdúrà nínú iyàrá ìtura kí n tó jáde wá jẹun. Mo nímọ̀lára pé “Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi.”—Sáàmù 54:4.
Nígbà tó wá yá, wọn kì í jẹ́ kí Luis wọlé wá máa bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ nílé wa. Nígbà tó ti dà bẹ́ẹ̀, ilé rẹ̀ la ti wá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ tí mo sì ń lọ sóde ìwàásù, wọ́n máa ń tì mí mọ́ta kí n tó dé. Èyí sì mú kí n máa sun ilé àwọn Ẹlẹ́rìí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mọ́jú.
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi ní May 13, 1973. Ilẹ̀ Potogí, tó ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Potogí àti gbogbo àwọn àgbègbè tó ń tòkèèrè ṣàkóso, ló ń darí Mòsáńbíìkì nígbà náà. Ní October 1, 1974, mo di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń pe àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ góńgó mi láti di míṣọ́nnárì, mo bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì kí n lè tóótun láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ míṣọ́nnárì.
Fífọgbọ́n Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù
Láàárín àwọn ọdún tí wọ́n fi fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Potogí tí ń tòkèèrè ṣàkóso, ìyẹn PIDE, da ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí sẹ́wọ̀n nítorí wíwàásù. Nítorí náà, kí wọ́n má bàa tì wá mọ́lé, ńṣe la ń dá ọgbọ́n sí i. Fún àpẹẹrẹ, a óò sọ̀rọ̀ ní ilé kan, lẹ́yìn náà, a óò wá lọ sí ilé mìíràn ní àgbègbè ibòmíràn. Bákan náà, àwa méjì yóò lọ sí ọgbà ìtura ìlú lákòókò ìsinmi oúnjẹ ọ̀sán wa tàbí ní ìrọ̀lẹ́. Ọ̀kan lára wa yóò jókòó ti ẹnì kan, yóò sì máa ka ìwé ìròyìn ayé. Tó bá ṣe díẹ̀, ẹnì kejì á jókòó tì wọ́n, á wo ìwé ìròyìn ayé náà, á sì sọ ọ̀rọ̀ bíi: “Ó ga o, ẹ wo bí àwọn tó kú ṣe pọ̀ tó! Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé irú èyí kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́ nínú ìjọba Ọlọ́run?”
Níbẹ̀ ni a ó ti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nígbà tí ẹnì kejì tó ń ka ìwé ìròyìn ayé náà bá béèrè pé kí ẹni tó sọ̀rọ̀ náà fi Bíbélì ti ohun tó sọ lẹ́yìn. Lẹ́yìn náà, a óò ṣètò láti pàdé lọ́jọ́ kejì láti máa bá ìjíròrò náà lọ. Lọ́nà yìí, ó ń ṣeé ṣe fún wa lọ́pọ̀ ìgbà láti mú kí ẹni tó jókòó tì wá lóhùn sí ìjíròrò wa tó dá lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, a sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀. A máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ríràn wá lọ́wọ́.
Àkókò Ìdánwò Lílekoko
Ní April 25, 1974, ìjọba àwọn abàṣẹ-wàá tí ń ṣàkóso ní ilẹ̀ Potogí dópin, ọ̀pọ̀ ìyípadà sì ṣẹlẹ̀ nínú ètò ìṣèlú ní àwọn ibi tí ilẹ̀ Potogí ń gbókèèrè ṣàkóso. Ní Mòsáńbíìkì, ìjọba dárí ji àwọn tó kó sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn ìṣèlú, àti àwa Ẹlẹ́rìí tó kó sẹ́wọ̀n nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì wa. Ṣùgbọ́n ní June 25, 1975, oṣù mẹ́rìnlá péré lẹ́yìn náà, Mòsáńbíìkì polongo òmìnira rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìṣàkóso ilẹ̀ Potogí. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, wọ́n tún gbé oríṣi inúnibíni mìíràn dìde sí àwa Ẹlẹ́rìí. Wọ́n ń rán àwọn ẹgbẹ́ kan ládùúgbò láti máa kó gbogbo Ẹlẹ́rìí tí wọ́n bá ti rí. Wọ́n ṣàpèjúwe wa bí “aṣojú Ètò Ìgbókèèrè-ṣàkóso tí àwọn ará Potogí fi sílẹ̀.”
Ní September, wọ́n fipá mú mi láti lọ sí ìpàdé ẹgbẹ́ kan ládùúgbò. Nígbà tí mo débẹ̀, mo rí i pé gbogbo àwọn tí a jọ ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló wà níbẹ̀. Wọ́n pàṣẹ fún wa láti kígbe àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú olóṣèlú tí ń gbé ẹgbẹ́ tí ń ṣàkóso lárugẹ. Nígbà tí a fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kọ̀, wọ́n kó wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì tì wá mọ́ iyàrá ẹ̀wọ̀n tó kún fọ́fọ́ tí mo sọ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀.
Ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kún débi pé agbára káká la fi ń lè kúrò lójú kan. Kí àwọn díẹ̀ lára wa lè ríbi sùn sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀, àwọn yòókù ní láti jókòó tàbí kí wọ́n wà lórí ìdúró. Ilé ìyàgbẹ́ kan ṣoṣo ló wà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń dí, tí á sì kún àkúndànù, òórùn burúkú á wá bolẹ̀. Spaghetti olóòóró tí eegun ẹja kún inú ẹ̀ tí eṣinṣin ọdẹ ńláńlá ti kú sínú ẹ̀ ni wọ́n ń fún wa jẹ, a kò sì ní fọ ọwọ́ kí a tó jẹ ẹ́. Ọjọ́ mọ́kàndínlógún ni àwa tí a lé ní ọgọ́sàn-án náà fi wà ninú ipò bíburú jáì yìí. Lẹ́yìn náà, wọ́n kó wa lọ síbì kan tó jẹ́ èkìdá àwa Ẹlẹ́rìí ni wọ́n tì mọ́ ibẹ̀, àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé. Láàárín oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ló kú nítorí ipò bíburú jáì tí a wà nínú ẹ̀wọ̀n náà.
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìjọba pinnu láti lé àwa Ẹlẹ́rìí kúrò nílùú, kó sì kó wa lọ sí Carico, àgbègbè kan tó jìnnà ní ìhà àríwá. Ète tí wọ́n fi ṣe èyí jẹ́ láti fi wá síbi àdádó. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje Ẹlẹ́rìí ló wà ní Mòsáńbíìkì nígbà náà, èyí tó pọ̀ jù lára wọ́n ló sì ṣèrìbọmi ní 1974 àti 1975. Nígbà tí mo ronú pé a óò nílò àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láàárín ìgbà tí a ó fi wà ní àdádó, mo tọrọ àyè láti lọ sílé láti lọ kó oúnjẹ díẹ̀ àti àwọn ohun èlò fún ìrìn àjò náà. Nígbà tí òṣìṣẹ́ ọba tó tẹ̀ lé mi lọ kò wo ọ̀dọ̀ mi, mo kó àwọn kéèkì kúrò nínú àwọn páálí wọn, mo sì kó àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì tẹ́lẹ̀ páálí náà. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù kì í bà wá. A gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé yóò ràn wá lọ́wọ́.—Hébérù 13:6.
Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Àwọn Àgọ́
A dé Carico ní January 1976, a sì rí ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá láti ilẹ̀ Màláwì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa, tí wọ́n ń gbé inú àwọn àgọ́ tí wọ́n pa. Láti 1972 sí 1975, ó lé ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ènìyàn [30,000], títí kan àwọn ọmọdé, tí wọ́n sá kúrò ní Màláwì nítorí inúnibíni onísìn bíburú jáì tí a ń ṣe sí wọn níbẹ̀. Wọ́n jẹ́ kí wọ́n wọ ìhà àríwá Mòsáńbíìkì gẹ́gẹ́ bí olùwá-ibi-ìsádi, nígbà tí àwá sì dé, wọ́n gbà wá sílé, wọ́n sì fún wa lára ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní.
Níwọ̀n bí èyí tó pọ̀ jù lọ lára wa kò ti mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé, àwọn arákùnrin wa láti Màláwì fi bí a ó ṣe kọ́ ilé wa hàn wá nípa mímọ bíríkì àti lílo koríko pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n tún kọ́ wa bí a ṣe ń gbin ọ̀gbìn oúnjẹ àti bí a ṣe ń ṣe àwọn ohun mìíràn láti gbọ́ bùkátà ara wa. Mo tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ iṣẹ́ káfíńtà, iṣẹ́ àgbẹ̀, àti aṣọ rírán. Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ tí a kọ́ wọ̀nyí wá wúlò fún ọ̀pọ̀ lára wa nígbà tí a padà sí ìlú wa.
Ohun tó jẹ wá lógún jù ni láti di ipò tẹ̀mí wa mú, mo sì gbọ́dọ̀ sọ pé a kò lálàṣí oúnjẹ tẹ̀mí rárá. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Ó dára, bí mo ṣe sọ níṣàájú, nígbà tí wọ́n lé wa lọ sí ìgbèkùn, ọ̀pọ̀ lára wa lo ọgbọ́n láti kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ohun èlò mìíràn dání. Bákan náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Gúúsù Áfíríkà tẹ àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tín-tìn-tín fún wa. Èyí mú kí ó rọrùn láti kó wọn wọ inú àwọn àgọ́.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìwé ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tí a ti kọ, nígbà tó di December 1, 1978, wọ́n gbà wá láyè láti ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó àkọ́kọ́ nínú àwọn àgọ́ náà. Ọjọ́ yẹn ni mo gbé Alita Chilaule, tí bàbá rẹ̀ wà lára àwọn tí a kọ́kọ́ ṣèrìbọmi fún ní Màpútò lọ́dún 1958, níyàwó. Nígbà tí a bí àwọn ọmọ wa, Dorcas àti Samuel, a kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì máa ń mú wọn lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Nígbà tó ṣe díẹ̀, a bí ọmọ mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jaimito.
Bí A Ṣe Ń Wàásù
Wọ́n ń fún àwa Ẹlẹ́rìí láyè láti máa jáde kúrò ní àwọn àgọ́ láti lọ ta nǹkan, títí kan irè tí ó ti oko wa wá. Ọ̀pọ̀ lára wa ń lo àǹfààní yìí láti wàásù. Ní gidi, mo mọ̀ọ́mọ̀ dá owó púpọ̀ lé iyọ̀ kí ẹnikẹ́ni má bàa lè rà á. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn díẹ̀ tí mo bá pàdé gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan.
Ọ̀kan lára àwọn tí mo ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan tó nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì sọ̀rọ̀ ní ìlú Milange tí kò jìnnà sí wa. Nígbà tí mo gbọ́ nípa rẹ̀, mo kọ̀wé sí ọ̀gá náà. Ó fèsì nípa kíké sí mi láti wá bẹ òun wò. Nítorí náà, mo tọ́jú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sábẹ́ aṣọ mi, mo sì gbéra pẹ̀lú ìrísí bíi pé mo fẹ́ lọ ta àwọn àga tí mo ṣe fún un.
Nígbà tí mo débẹ̀, gádígádí ni àwọn sójà ń ṣọ́ ilé náà; ẹ̀rù sì ń bà mí. Àmọ́, ọkùnrin náà jáde wá, ó sì sọ fún àwọn sójà náà pé òun kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí òun lọ́wọ́. La bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ní agogo márùn-ún ìrọ̀lẹ́, ó sì fi ìfẹ́ hàn gan-an débi tí a kò fi ṣe tán títí di agogo márùn-ún òwúrọ̀ ọjọ́ kejì! Nígbà tó yá, ó ní òun fẹ́ láti máa gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa láti ilẹ̀ Potogí, níwọ̀n bí a kò ti fòfin de àwọn lẹ́tà tí ń wọlé fún un. Lẹ́yìn náà, á mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà wá fún mi, èmi náà á sì mú un wọnú àgọ́.
Lóòótọ́, wọ́n mú àwọn kan nínú wa, wọ́n sì tì wá mọ́lé lọ́pọ̀ ìgbà nítorí iṣẹ́ ìwàásù tí a ń ṣe. Síbẹ̀, nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run ń tì wá lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bó ṣe ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lẹ́yìn.—Ìṣe, orí kẹta sí ìkarùn-ún.
Wọ́n Dá Wa Sílẹ̀, A Sì Padà sí Màpútò
Ní September 1985, lẹ́yìn tí a gbé àwọn ohun tó so mọ́ ọn yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, a pinnu pé a óò ṣètò láti kóra pọ̀ jáde kúrò ní àwọn àgọ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan kò jáde kúrò ní àwọn àgọ́ Carico náà tí wọn kò sì fojú kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòókù fún ọdún méje lẹ́yìn náà, àwọn mìíràn sá lọ sí Màláwì àti Zambia. Èmi àti ìyàwó mi pinnu láti kó àwọn ọmọ wa lọ sí ìlú Milange tó wà nítòsí wa. Mo ríṣẹ́ àti ibùgbé níbẹ̀, a sì ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, a padà sí Màpútò pátápátá.
Ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí wa la kọ́kọ́ ń gbé. Iṣẹ́ ṣòro láti rí, ṣùgbọ́n bí àkókò ti ń lọ mo rí iṣẹ́. Ẹ̀pà ni Alita ń yan tà kí owó tí ń wọlé fún wa lè gbé pẹ́ẹ́lí díẹ̀ sí i. Níwọ̀n bí èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ń mọ́ mi lẹ́nu báyìí, mo kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ ní Ilé Iṣẹ́ Tí A Ti Ń Gbàwé Àṣẹ Àtiwọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Mo yege nínú ìdánwò wọn, wọ́n sì gbà mí síṣẹ́ tí n óò ti máa gba owó oṣù tó fi ìgbà ogún pọ̀ ju iye tí ń wọlé fún mi tẹ́lẹ̀ lọ! Ní gidi, mo nímọ̀lára pé Jèhófà ló ràn mí lọ́wọ́, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nínú àdúrà.
N Kò Jẹ́ Kí Àwọn Ojúṣe Mi Para Wọn Lára
Níkẹyìn, ní February 11, 1991, ìjọba ilẹ̀ Mòsáńbíìkì fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láṣẹ láti máa ṣe ẹ̀sìn wa lọ láìsí ìkálọ́wọ́kò lábẹ́ òfin. Ọjọ́ ńlá mà lọjọ́ náà jẹ́ fún wa o! Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n pè mí láti wá sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ tí ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mòsáńbíìkì. Ní ìgbà yẹn, àkọ́bí wa jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá, èkejì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, ẹ̀kẹta sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà. Gbogbo òru ni mo fi gbàdúrà, mo ń béèrè pé kí Jèhófà fún mi lọ́gbọ́n tí n óò fi máa ṣèpinnu nínú bíbójútó ojúṣe mi nínú ilé àti nínú ètò lọ́nà tí ọ̀kan kò fi ní pa èkejì lára.
A ra ọkọ̀ kékeré kan tó ní ilé lẹ́yìn, tí a fi ń ṣòwò. A gba àwọn aṣáájú ọ̀nà bíi mélòó kan síṣẹ́ láti máa ṣe búrẹ́dì eléròjà nínú kí wọ́n sì máa tà á, òwò náà sì ń mérè wá. Lọ́nà yẹn, mo ní àkókò láti bójú tó àwọn àǹfààní iṣẹ́ tuntun tí mo ní nínú ètò. Bákan náà ni a nílò ilé, níwọ̀n bí a ò ti rí owó ilé san mọ́. Nítorí náà, mo kọ ìwé béèrè fún ibùgbé lọ́dọ̀ ìjọba, mo sì ṣàlàyé ipò tí ìdílé mi wà. Láìpẹ́, wọ́n fọwọ́ sí i pé a lè ra ilé. Wọ́n kéde rẹ̀ níbi gbogbo, nítorí pé èmi ni ará Mòsáńbíìkì tó kọ́kọ́ ra ilé lọ́wọ́ ìjọba.
Ọlọ́run fi àwọn ọmọ, tí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtọ́ni tẹ̀mí tí a ń fún wọn, ta èmi àti Alita lọ́rẹ. (Diutarónómì 6:6-9) Ó jẹ́ àṣà wa láti máa jíròrò ẹsẹ Bíbélì kan lọ́jọ́ kan ní agogo mẹ́fà ku ogún ìṣẹ́jú lówùúrọ̀, lẹ́yìn náà, a óò sì jùmọ̀ ka Bíbélì. Níwọ̀n bí àwọn ọmọ wa ti ní láti tètè dé ilé ẹ̀kọ́, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdájí yìí ti mọ́ wọn lára. Ọjọ́ Friday ní agogo mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ni a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa, àwọn ọmọ yóò jíròrò àwọn àkòrí Bíbélì kan tí wọ́n ti ṣèwádìí nípa rẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀. Àkókò yìí kan náà ni a máa ń fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a fẹ́ lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ dánra wò.
Gbogbo àwọn ọmọ wa ló ti ṣèrìbọmi. Kódà, Dorcas àti Samuel ti ń sìn bí aṣáájú ọ̀nà láti ọdún 1994, láti ìgbà tí Jaimito sì ti ṣèrìbọmi ló ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bọ̀. Àwọn ọmọ wa ṣì ń lọ sí ilé ìwé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì ní in lọ́kàn láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i tó bá yá. Alita ń ṣètò àkókò rẹ̀ ní ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àti bíbójútó ilé wa. Mo ti ń sìn bí aṣáájú ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún, títí kan àwọn ọdún tí a lò ní àgọ́ tí wọ́n há wa mọ́. Ṣùgbọ́n láti 1993 ni mo ti ń ti ilé lọ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Àwọn Ìbùkún Ọlọ́run Ń Pọ̀ Sí I
Ní 1997, mo rí ìbùkún kíkọyọyọ ti lílọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ olóṣù-méjì tí a fún àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ti wáyé ní Watchtower Educational Center ní Patterson, New York. Lọ́nà yìí, lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún jèrè láti inú ìsapá mi láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tí mo ń padà lọ sílé, mo ní àǹfààní láti bẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ilẹ̀ mìíràn wò, èyí sì mú kí ọkàn mi kún fún ìmọrírì púpọ̀ fún ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé!
Ìfẹ́ yìí gan-an tó wà láàárín àwa Kristẹni tòótọ́ ló ń mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn aláìlábòsí ọkàn púpọ̀ sí i dara pọ̀ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mòsáńbíìkì. (Jòhánù 13:35) Láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje ènìyàn tó ń wàásù nígbà tí wọ́n lé wa kúrò nílùú lọ sí àwọn àgọ́ àhámọ́, ní báyìí, àwọn tí ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò Mòsáńbíìkì ti lé ní ẹgbàá mẹ́rìnlá ààbọ̀ [29,000]. Àwọn wọ̀nyí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ju márùndínláàádọ́rin ó lé lẹ́gbẹ̀ta [665] lọ; mẹ́rin péré ló wà ní ọdún 1958.
Ní ọdún 1993 wọ́n fún wa láṣẹ ìkọ́lé láti kọ́ ọ́fíìsì ẹ̀ka kan sí Màpútò, èyí tí yóò gba àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka tó lé ní márùndínlọ́gọ́rin àti láti bójú tó ìtẹ̀síwájú àgbàyanu tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọsìn mímọ́ gaara ní Mòsáńbíìkì. Lẹ́yìn tí a lo nǹkan bí ọdún mẹ́rin lẹ́nu iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà, a parí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní December 19, 1998, ayọ̀ wa kò láàlà nígbà tí ẹni méjìdínlẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,098] ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ìyàsímímọ́ ilé tó jojúnígbèsè yìí. Nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, mo ní àǹfààní fífọ̀rọ̀ wá àwọn tí wọ́n lo ọ̀pọ̀ ọdún ní ìgbèkùn ní Carico lẹ́nu wò. Mo ní kí àwọn tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn níbẹ̀ nawọ́ sókè, ìmọ̀lára àwọn tó wà nínú àwùjọ náà ru sókè gan-an nígbà tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọwọ́ lọ sókè.
Lọ́jọ́ kejì, èrò tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbàárin lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [8,525] ló wá sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Matola fún àgbéyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà, àwọn ìròyìn tí ń fúnni níṣìírí láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, àti àwọn àsọyé tí a gbé karí Bíbélì látẹnu àwọn àlejò láti orílé iṣẹ́ àgbáyé ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó wà ní Brooklyn, New York.
Ní tòótọ́, láti ìgbà tí mo ti gba ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba, mo ti rí àtakò ìdílé, ewu ìṣekúpani, àti inúnibíni bíburú jáì tó ń mú kí n máa ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé ó sàn láti kú ju kí n wà láàyè lọ. Síbẹ̀, inú mi dùn nítorí àwọn ìrírí wọ̀nyí ti mú kí ìdè ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i. Láìṣe àní-àní, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti sọ nínú Bíbélì pé, “Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi; Jèhófà wà lára àwọn tí ń ti ọkàn mi lẹ́yìn.” (Sáàmù 54:4) Ó jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ fún èmi àti ìdílé mi láti máa sin Jèhófà papọ̀ pẹ̀lú ìdílé àgbáyé ti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn Ẹlẹ́rìí níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n kọ́ nígbà tí wọ́n wà ní àdádó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
A ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn ní àwọn àgọ́ Carico nawọ́ sókè