Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Da Ìwà Àìdáa?
“Àwọn olówó nìkan làwọn èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń ṣe àwa tí a kò rí oúnjẹ jẹ tí a kò sì ríbi sùn bí ẹran. Bí ohunkóhun bá wà tí mo ń retí kó ṣẹlẹ̀ sí mi lọ́jọ́ iwájú, ikú ni, tí ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀.”—Arnulfo, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí kò nílé.
HÍHÙWÀ àìdáa sí èèyàn pọ̀ láyé yìí. Ìròyìn tó wá láti ọ̀dọ̀ Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) sọ pé: “Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ó lé ní mílíọ̀nù méjì ọmọdé tógun pa, ó sì lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin tí a sọ di aláàbọ̀ ara, bákan náà ni ogun ti sọ àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan di aláìlóbìí tàbí kí wọ́n máà rí àwọn ìdílé wọn mọ́.” Ebi àti ipò òṣì ń bá èyí tó pọ̀ jù lára àwọn olùgbé ayé fínra bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan lọ́rọ̀, tí wọ́n sì ní àníṣẹ́kù. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ bí Arnulfo ni a ń fi àǹfààní àtikàwé dù.
Ó sábà máa ń dunni gan-an, àgàgà tó bá jẹ́ àwọn tó yẹ kí wọ́n fìfẹ́ hàn síni tàbí kí wọ́n dáàbò boni ló ń hùwà àìdáa síni. Gbé ọ̀ràn ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó ń jẹ́ Susana yẹ̀ wò. Ìyá rẹ̀ já òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin méjì sílẹ̀. Susana sọ tẹ̀dùntẹ̀dùn pé: “Ọdún ti gorí ọdún, màmá mi ò sì sọ rí pé kí n wá máa gbé ọ̀dọ́ òun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ìlú kan náà la ń gbé. Kò tilẹ̀ tíì sọ fún mi rí pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ,’ nǹkan tó sì máa ń mú kí orí mi gbóná nígbà gbogbo nìyẹn títí di ìsinsìnyí pàápàá.” Bí a bá hùwà àìdáa sí ọ, ó lè ṣòro fún ọ láti pa ìbínú mọ́ra. Ẹnì kan tí wọ́n fìbálòpọ̀ fìtínà rẹ̀ nígbà ọmọdé sọ pé: “Ó tilẹ̀ ti mú kí inú bí mi sí Ọlọ́run.”
Ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti ní ìrora ọkàn kí a sì bínú tí ẹnì kan bá hùwà àìdáa síni. Bíbélì sọ pé: “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníwàásù 7:7) Fífarada ìwà àìdáa lójoojúmọ́ ayé rẹ tún lè mú kí o sorí kọ́. (Fi wé Sáàmù 43:2.) Nítorí náà, o lè máa yán hànhàn pé kí àṣà híhùwà àìdáa síni dópin. Ọmọdébìnrin kan láti ìhà Àárín Amẹ́ríkà rántí pé: “Mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tí ń jà fún ire àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Góńgó mi ni láti sapá láti mú kí nǹkan yí padà, kí ebi má baà máa pa àwọn ọmọdé. . . . Nígbà tó yá, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn ajìjàgbara.” Ṣùgbọ́n dípò kí wọ́n hùwà tó dáa sí i, ńṣe làwọn sójà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń hùwà àìdáa tí ò ṣeé fẹnu sọ sí i.
Iru ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ń rán wa létí pé àwọn èèyàn ò lè tún ọ̀ràn ara wọn ṣe. Nígbà náà, báwo ni àwọn tí a hùwà àìdáa sí ṣe lè fara dà á?a Báwo lo ṣe lè fara da ìbànújẹ́ àti ìbínú tó ṣeé ṣe kí o ní?
Mímú Ìwà Kíkorò àti Ìbínú Kúrò
Láti ìgbà dé ìgbà, o lè ní láti rán ara rẹ létí pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí là ń gbé. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn òde òní yóò jẹ́ “aṣeniléṣe, . . . aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdárí-jini, abanijẹ́, aláìníkòóra-ẹni-níjàánu, òkú òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, aládàkàdekè.” (2 Tímótì 3:1-4, New International Version) Ọ̀pọ̀ èèyàn ti “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.” (Éfésù 4:19) Nítorí náà, a ò lè fẹ́ àṣà híhùwà àìdáa sí èèyàn kù láyé. Nígbà náà, “bí ìwọ bá rí ìnilára èyíkéyìí tí a ṣe sí ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ àti fífi ipá mú ìdájọ́ àti òdodo kúrò ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ, má ṣe jẹ́ kí kàyéfì ṣe ọ́ lórí àlámọ̀rí náà.”—Oníwàásù 5:8.
Ìdí pàtàkì wà tí Bíbélì fi kìlọ̀ pé kí o máà jẹ́ kí inú àbíjù rí ẹ gbé ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú . . . kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfésù 4:31) Èé ṣe? Nítorí tí a kò bá yé bínú àbíjù, tó bá yá ó lè pani lára, ó sì lè pààyàn. (Fi wé Òwe 14:30; Éfésù 4:26, 27.) Èyí rí bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì bí o bá rí i tí o ń “kún fún ìhónú sí Jèhófà.” (Òwe 19:3) Bíbínú sí Ọlọ́run ń ba ipò ìbátan rẹ jẹ́ pẹ̀lú Ẹni náà gan-an tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ jù lọ. Bíbélì sọ pé “ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíróníkà 16:9.
Bíbélì tún sọ nípa Jèhófà pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Ìwà ọ̀tẹ̀ tí Ádámù àti Éfà hù ló mú kí ìwà àìdáa máa ṣẹlẹ̀. (Oníwàásù 7:29) Ènìyàn ló ń “jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀” kì í ṣe Ọlọ́run. (Oníwàásù 8:9) Tún rántí pẹ̀lú pé, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù. (1 Jòhánù 5:19) Sátánì ló ń fa ìwà àìdáa tó ń ṣẹlẹ̀ láyé kì í ṣe Jèhófà.
Òpin Ìwà Àìdáa
Ó dùn mọ́ni pé ìwà àìdáa kò ní máa bá a lọ títí láé. Fífi ìyẹn sọ́kàn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa fara dà á. Gbé ìrírí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ásáfù yẹ̀ wò, tó gbé ayé ní ìgbà tí a ń kọ Bíbélì. Ìwà àìdáa ń ṣẹlẹ̀ láyìíká rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn èèyàn tó ń sọ pé àwọn ń sin Jèhófà ló ń gbé. Dípò kí a fìyà jẹ àwọn òǹrorò èèyàn nítorí ìwà àìdáa tí wọ́n ń hù sí àwọn ẹlòmíràn, ńṣe ló jọ pé wọn ò níṣòro láyé wọn, wọ́n sì ń jayé fàlàlà! Ásáfù jẹ́wọ́ pé: “Èmi ṣe ìlara . . . nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.” Díẹ̀ ló kù kí ẹsẹ̀ Ásáfù yẹ̀ tán kúrò lọ́nà òdodo nígbà tó jẹ́ kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ gba òun lọ́kàn.—Sáàmù 73:1-12.
Bí àkókò ti ń lọ, Ásáfù wá rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an. Ó wá sọ nípa àwọn èèyàn burúkú pé: “Dájúdájú, orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni ibi tí ìwọ [Ọlọ́run] gbé wọn kà. Ìwọ ti mú kí wọ́n ṣubú ní rírún wómúwómú.” (Sáàmù 73:16-19) Lóòótọ́, Ásáfù wá lóye pé bópẹ́bóyá, àwọn èèyàn kì í mú ìwà burúkú tí wọ́n ń hù jẹ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyà ìwà àìtọ́ tí wọ́n ń hù máa ń jẹ wọ́n, wọ́n sì máa ń ṣẹ̀wọ̀n, wọ́n a dí tálákà, iṣẹ́ á bọ́ lọ́wọ́ wọn, tàbí kí a yọ wọ́n kúrò nípò agbára tí wọ́n wà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, èèyàn burúkú yóò wá “ṣubú ní rírún wómúwómú” nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ ṣẹ lórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí.—Sáàmù 10:15, 17, 18; 37:9-11.
Mímọ̀ pé Ọlọ́run yóò tún nǹkan ṣe láìpẹ́ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìbínú àti ìdààmú tóo ní. Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn. Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’”—Róòmù 12:17-19; fi wé 1 Pétérù 2:23.
Rírí Ìrànlọ́wọ́ àti Ìtìlẹ́yìn
Bó ti wù kó rí, ó lè jẹ́ pé nǹkan kan wà tó ń bà ọ́ nínú jẹ́, bíi rírántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí àjọ UNICEF gbé jáde ti sọ, “ìgbàgbọ́ àti ìṣesí àwọn ọmọ tí wọ́n ti fojú winá ìwà ipá sábà máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ yàtọ̀ lọ́nà pàtàkì àti pé wọn ò wá ní gba ẹnikẹ́ni gbọ́ mọ́. Èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀ gan-an nínú ọ̀ràn àwọn ọmọ tó jẹ́ àwọn èèyàn tí wọ́n kà sí aládùúgbò tàbí ọ̀rẹ́ wọn ló hàn wọ́n léèmọ̀ tàbí tó hùwà àìdáa sí wọn.”
Irú àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn kì í tètè yanjú. Ṣùgbọ́n bí ìmọ̀lára òdì tàbí rírántí àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ bá ń gbà ọ́ lọ́kàn nígbà gbogbo, ó lè jẹ́ pé o nílò ìrànlọ́wọ́ ni. (Fi wé Sáàmù 119:133.) Lákọ̀ọ́kọ́, o lè ka àwọn ìwé tó ń sọ ní pàtàkì nípa àwọn ìṣòro tí o ti ní. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Jí! ti tẹ àwọn àpilẹ̀kọ mélòó kan jáde tó pèsè àmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ fún àwọn tí èèyàn ti fipá bá lò pọ̀, tí wọ́n digun jà lólè, àti àwọn ọmọdé tí wọ́n hùwà àìdáa sí. Sísọ ẹ̀dùn ọkàn àti ìmọ̀lára rẹ fún ẹnì kan tó dàgbà dénú, tí yóò sì fara balẹ̀ gbọ́ ẹ lágbọ̀ọ́yé lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ púpọ̀. (Òwe 12:25) Bóyá o tilẹ̀ lè finú han àwọn òbí rẹ.
Ṣùgbọ́n bí àwọn òbí ẹ kò bá ràn ẹ́ lọ́wọ́ ńkọ́? Nígbà náà, wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ ìjọ Kristẹni. Láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn alàgbà ìjọ dà bí ibi ìsádi fáwọn tí ìpọ́njú dé bá. (Aísáyà 32:1, 2) Kì í ṣe pé wọ́n á tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹ nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n tún lè ní àwọn àmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ láti gbà ẹ́. Má ṣe gbàgbé pẹ̀lú pé àwọn Kristẹni mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú lè ṣe bí “àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá” fún ẹ. (Máàkù 10:29, 30) Ǹjẹ́ o rántí Susana, tí ìyá rẹ̀ já sílẹ̀? Òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ rí ìrànlọ́wọ́ gbà nínú ìjọ Kristẹni. Òjíṣẹ́ Kristẹni kan nífẹ̀ẹ́ ìdílé Susana gan-an débi pé ńṣe ló ń pe arákùnrin náà ní bàbá tó gba Susana ṣọmọ. Susana sọ pé, irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ “ti ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà di géńdé kí a sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.”
Àwọn ògbógi sọ pé lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tó ṣe pàtàkì lójoojúmọ́ tún lè ṣèrànwọ́. Wíwulẹ̀ lọ sí ilé ìwé àti ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an láti gbé ọkàn kúrò nínú àwọn èrò òdì. Bó ti wù kó rí, ní pàtàkì, wàá tilẹ̀ jàǹfààní pàápàá nínú pípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò tẹ̀mí mọ́—lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti wíwàásù ìhìn rere náà.—Fi wé Fílípì 3:16.
Ó dìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, tó sì mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ jákèjádò ayé kí ìwà àìdáa tó lè kásẹ̀ nílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Kó tó dìgbà yẹn, sapá láti máa fara dà á. Máa jèrè okun nípasẹ̀ ìlérí náà pé Jésù Kristi tí yóò jẹ́ Olùṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run yóò “dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.”—Sáàmù 72:12, 13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpilẹ̀kọ yìí darí àfiyèsí sí ìwà àìdáa tí a lè hù sí àwọn èwe ní orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀, àwọn ìlànà tí a jíròrò nínú rẹ̀ kan irú ìwà àìdáa èyíkéyìí tó ṣeé ṣe ká hù síni.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
“Ó tilẹ̀ ti mú kí inú bí mi sí Ọlọ́run”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa fara da ìwà àìdáa