Nígbà Tí Òjò Bá Kọ̀ Tí Kò Rọ̀
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRAZIL
NÍ ÈṢÍ, ọ̀dá dá lápá ibi púpọ̀ ní ìlà oòrùn àríwá Brazil. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ìwé ìròyìn Veja gbé jáde ti wí, ẹgbàágbèje àwọn nordestino, ìyẹn àwọn olùgbé ìlà oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè náà, rí i pé “wàhálà gbáà lọ̀ràn òjò tó kọ̀ tí kò rọ̀ máa dá sílẹ̀ fáwọn.” Nítorí ọ̀dá òjò náà, ṣe ni oòrùn jó gbogbo oko ìrẹsì, oko ẹ̀wà, àti oko àgbàdo gbẹ, tó wá mú kí ìyàn mú jákèjádò àgbègbè yẹn—ó tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí irú ìyàn burúkú bẹ́ẹ̀ mú gbẹ̀yìn. Ní àwọn ibì kan, kò tiẹ̀ sí omi mímu.
Ọ̀dá kì í ṣe àjèjì àwọn ará Brazil. Lọ́dún 1877, nígbà ìyàn tó burú jù lọ lórílẹ̀-èdè náà, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] lebi lù pa. Ìgbà yẹn ni Dom Pedro Kejì, olú ọba Brazil, jẹ́jẹ̀ẹ́ pé bó jẹ́ kóun ta gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tó wà lára adé òun ni, òun gbọ́dọ̀ rẹ́yìn ọ̀dá òjò tó ń bá ilẹ̀ òun fínra! Ìyẹn ti lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún báyìí o; síbẹ̀, títí dòní, ìṣòro ọ̀hún kọ̀, ó lóun ò ní lọ. Nígbà ọ̀dá tèṣí, wọ́n sọ pé àwọn èèyàn tó máa kàn á tó mílíọ̀nù mẹ́wàá, lára àwọn tí ń gbé ní ìlú mẹ́sàn-án lé lẹ́gbẹ̀fà [1,209] tó wà ní ìlà oòrùn àríwá Brazil.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Láti Ibòmíràn Fìfẹ́ Gbégbèésẹ̀
Nígbà tí ìròyìn nípa ọ̀dá náà dé ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society ní Brazil, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n gbéṣẹ́ ṣe. Kíákíá ni wọ́n rán àwọn aṣojú arìnrìn-àjò sáwọn àgbègbè tọ́ràn náà kàn gbọ̀ngbọ̀n láwọn ìpínlẹ̀ Bahia, Ceará, Paraíba, Pernambuco, àti Piauí, kí wọ́n lọ wo bí ìṣòro ọ̀hún ti rinlẹ̀ tó. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò náà rí i pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] Ẹlẹ́rìí àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn tó ń gbé lágbègbè yẹn ni ọ̀dá náà ti sọ daláìní. Àwọn kan nínú wọn, ohunkóhun tí wọ́n bá sáà ti rí tó jọ iṣu ni wọ́n ń jẹ; ìrẹsì nìkan làwọn mìíràn ń rí jẹ. Ìdílé kan kò ní nǹkan kan láti jẹ, kìkì mílíìkì ni wọ́n ń mu láàárọ̀, lọ́sàn-án, àti lálẹ́. Ńṣe ni Kristẹni arábìnrin kan tó ní àrùn jẹjẹrẹ lu bẹ́ẹ̀dì rẹ̀ tà, tó fi owó rẹ̀ ra ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀. Ìdílé kan tó jẹ́ ẹlẹ́ni mẹ́fà ti gbà pé àjẹkẹ́yìn làwọn ti jẹ yẹn, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá rí nǹkan táwọn Kristẹni arákùnrin wọn fi ránṣẹ́.
Ojú ẹsẹ̀ ni a ṣètò àwọn ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ láti máa pín oúnjẹ àtàwọn ohun èlò. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń gbé nílùú Recife àtàwọn ìlú míì nítòsí dá nǹkan jọ tìrìgàngàn fáwọn aláìní. Ṣùgbọ́n nígbà tíyẹn ò tó, àwọn Kristẹni láti ìlú Rio de Janeiro tún pawọ́ pọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn arákùnrin wọn. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn Ẹlẹ́rìí ti dá tọ́ọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n oúnjẹ jọ, wọ́n sì ti sanwó tí wọ́n á fi kó nǹkan wọ̀nyí lọ sí Recife tó jẹ́ ìrìn ọ̀ọ́dúnrún lé lẹ́gbẹ̀rún méjì kìlómítà sí wọn.
Ní olú ìlú ìpínlẹ̀ Piauí àti Paraíba, tọ́ọ̀nù mẹ́fà oúnjẹ ni wọ́n sáré dá jọ. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan nílùú Fortaleza ni wọ́n kó oúnjẹ tí wọ́n dá jọ sí. Ṣùgbọ́n ìṣòro kan wà. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí yóò ṣe kó oúnjẹ wọ̀nyẹn débi tó ń lọ? Ọkùnrin kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi inú rere yọ̀ǹda pé kí wọ́n lo ọkọ̀ akẹ́rù òun. Àmọ́ o, wọ́n ń dá àwọn ọkọ̀ lọ́nà, wọ́n sì ń jí oúnjẹ àti ẹrù wọn kó lọ. Ṣé àwọn nǹkan táa dá jọ máa débi tí wọ́n ń lọ báyìí? Àwọn Ẹlẹ́rìí pinnu pé ohun tó bá gbà làwọn máa fún un. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún nínú Jèhófà, wọ́n di oúnjẹ náà gàgàgúgú, wọ́n tẹkọ̀ létí, ó di àgbègbè náà. Gbogbo ẹrù ọ̀hún ló gúnlẹ̀ láìyingin, àwọn ará náà sì fayọ̀ tẹ́wọ́ gbà wọ́n.
Ayọ̀ Tí Ń Bẹ Nínú Nínawọ́ Ìrànwọ́ Síni àti Rírí Ìrànwọ́ Gbà
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nídìí ṣíṣètò ìrànlọ́wọ́ náà dùn gan-an pé àwọn láǹfààní láti ran àwọn arákùnrin àwọn lọ́wọ́. Alàgbà ìjọ kan tí ń gbé ní São Paulo sọ pé: “Nígbà tí ìyàn mú gbẹ̀yìn, a ò sí lára àwọn tí wọ́n ní kó dá oúnjẹ. A mà mọrírì rẹ̀ o, pé wọ́n ké sí wa lọ́tẹ̀ yìí!” Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú Fortaleza kọ̀wé pé: “A láyọ̀ gan-an pé àwa náà ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́, pàápàá jù lọ nítorí pé ó dá wa lójú pé a ti mú ọkàn Jèhófà yọ̀. A ò jẹ́ gbàgbé ọ̀rọ̀ inú Jákọ́bù 2:15, 16.” Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn kà pé: “Bí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan bá wà ní ipò ìhòòhò, tí ó sì ṣaláìní oúnjẹ tí ó tó fún òòjọ́, síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa lọ ní àlàáfíà, kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa,’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò fún wọn ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí fún ara wọn, àǹfààní wo ni ó jẹ́?”
Nígbà míì, àwọn Ẹlẹ́rìí tó fi nǹkan wọ̀nyí ránṣẹ́ máa ń kọ ọ̀rọ̀ ìṣírí sára oúnjẹ tí wọ́n dì ránṣẹ́. Ọ̀kan kà pé: “Ẹ má gbàgbé ìlérí tó wà nínú Sáàmù 72:16 pé láìpẹ́, nínú ayé tuntun Ọlọ́run, oúnjẹ yóò wà rẹpẹtẹ.” Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, àwọn Ẹlẹ́rìí tí ìyàn mú mọrírì inú rere àwọn arákùnrin wọn gidigidi. Ẹlẹ́rìí kan tí ìdílé rẹ̀ rí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò gan-an gbà, fi ẹ̀mí ìmoore kọ̀wé pé: “Èmi àti ìdílé mi ka èyí sí ẹ̀rí tó ṣe kedere nípa ìfẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run àti Baba wa aláàánú, àti bíbìkítà tí ètò àjọ rẹ̀ bìkítà fún àwa mẹ́ńbà rẹ̀. Ó ti túbọ̀ fà wá sún mọ́ òun àtàwọn èèyàn rẹ̀.”
Àtúnṣe Tó Máa Yanjú Ìṣòro Náà Pátápátá
Kí ẹ sì máa wò ó o, kì í kúkú ṣe pé kò sómi ní ìlà oòrùn àríwá Brazil; omi tó ṣeé mu kún abẹ́ ilẹ̀ wọn dẹ́múdẹ́mú, bẹ́ẹ̀ náà ni omilẹgbẹ tún ń bẹ ní ìpamọ́. Ká sọ pé ó ṣeé ṣe láti mú kí omi wọ̀nyí ṣàn dé gbogbo ilẹ̀ wọn ni, ṣe ni ì bá máa méso jáde ní jìngbìnnì.
Láìpẹ́, a ó yanjú ìṣòro tó fòòró Olú Ọba Dom Pedro Kejì pátápátá. Ọjọ́ náà yóò dé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi yóò yanjú gbogbo ìṣòro ilẹ̀ ayé, títí kan ìyàn. Ìgbà yẹn ni ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà pé: “Omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀. Ilẹ̀ tí ooru ti mú gbẹ hán-ún hán-ún yóò sì ti wá rí bí odò adágún tí ó kún fún esùsú, ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò sì ti wá rí bí àwọn ìsun omi.”—Aísáyà 35:1, 2, 6, 7.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
“Ẹ Jẹ́ Kí A Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Ọ̀dá tó dá ní Brazil láìpẹ́ yìí fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ láǹfààní láti fi ìmọ̀ràn yẹn sílò lọ́nà yíyẹ. Wọ́n ṣaájò àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, àmọ́ wọn ò fi mọ síbẹ̀, wọ́n tún ṣaájò àwọn míì pẹ̀lú. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, àwọn kan tó máa ń ta ko iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí yí ojú ìwòye wọn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí padà.
Inú kọ́kọ́ ń bí ọkùnrin kan gan-an nígbà tí ìyàwó rẹ̀ pinnu pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àkókò ti ń lọ, ìyàwó rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí tan ìgbàgbọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì. Nígbà tí ìyàn náà wá mú dójú ẹ̀, táwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò náà dé sílé tọkọtaya náà tàwọn toúnjẹ, ó wú ọkùnrin náà lórí débi pé ó pinnu pé òun máa ṣe nǹkan tó ti sọ pé òun ò ní ṣe láé—pé òun máa lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọkùnrin tó ń ṣàtakò tẹ́lẹ̀ rí yìí gbà pé kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì gbà pátápátá pé lóòótọ́ ni Bíbélì ní ìmísí.
Ní àdúgbò míì, àwọn Ẹlẹ́rìí ròyìn pé: “Ó yà wá lẹ́nu pé àwọn ẹrù àfiṣèrànwọ́ lè tètè dé báyẹn. Oúnjẹ tí wọ́n kó wá pọ̀ ju ohun táa ń retí. Fún ìdí yìí, lẹ́yìn tí a gbọ́ tàwọn ará àti ìdílé wọn tán, a pín oúnjẹ fáwọn tí a ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹbí wọn, àti fáwọn tó ń gbé àdúgbò pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń gbé lábúlé kan kó oúnjẹ fáwọn kan ládùúgbò wọn. Onílé kan tó fìmọrírì hàn sọ pé: “Ẹ̀yin lẹ̀ ń ṣe ohun tí Kristi fi kọ́ni; ẹ ń fi fúnni láìretí àtirí nǹkan gbà padà.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ohun tí ọ̀dá náà fojú àwọn èèyàn rí
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Fọ́tò tí Evan Schneider yà lórúkọ àjọ UN/DPI