ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 10/8 ojú ìwé 29-30
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Ẹ̀jẹ́ Máàgbéyàwó Nítorí Ìsìn?
  • Fífi Àwọ̀n Pa Àwọn Ẹ̀dá Òkun Nípakúpa
  • Kẹ́míkà Nínú Ohun Ìṣeré Ọmọdé
  • Àwọn Ìjọ Tí Kò Lálùfáà
  • Èèyàn Púpọ̀ Sí I Ń Wọko Gbèsè
  • Ṣé Aṣọ Kan Wà Tí Kò Lè Rùn?
  • Wàhálà Omi Ń Pọ̀ Sí I
  • Èèyàn Ń Pọ̀ Sí I ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà
  • Gbígba Bẹ́ẹ̀tì Lé Amágẹ́dọ́nì Lórí
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Àwọn Ohun Ìṣeré Tó Dáa Jù Lọ Fáwọn Ọmọdé
    Jí!—2004
  • Ṣé Ó Pọn Dandan Kí Kristẹni Òjíṣẹ́ Wà Láìgbéyàwó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 10/8 ojú ìwé 29-30

Wíwo Ayé

Kí Nìdí Ẹ̀jẹ́ Máàgbéyàwó Nítorí Ìsìn?

Ìwé ìròyìn Veja sọ pé: “Èdè-àìyedè tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ọ̀ràn máàgbéyàwó nítorí ìsìn nínú Ìjọ Àgùdà jẹ́ ọ̀kan lára ìpèníjà tó le jù lọ tó dojú kọ ipò àlùfáà. Ní ọdún 1970, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àlùfáà ni wọ́n gbé orúkọ wọn jáde pé wọ́n ti fi ipò wọn sílẹ̀ nítorí àtigbéyàwó. Ní báyìí, wọ́n ti pé ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000]—ìlọ́po méjìlá iye yẹn. Ní Brazil, iye àwọn àlùfáà tí wọ́n ti ṣèpinnu yìí ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po ogún láàárín sáà kan náà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlàyé àwọn aṣáájú ìsìn Ìjọ Àgùdà kò bá Ìwé Mímọ́ mu, wọ́n ń jiyàn gbe àṣà máàgbéyàwó nítorí ìsìn nípa sísọ pé ó ń jẹ́ kí àlùfáà lè “túbọ̀ darí ọkàn rẹ̀ sọ́dọ̀ Ọlọ́run” àti láti pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ rẹ̀. Ìwé ìròyìn Veja náà sọ pé: “Ṣùgbọ́n àlàyé náà gan-an tó mú kí àṣà máàgbéyàwó nítorí ìsìn máa wà nìṣó kò kájọ. Èrò náà wáyé ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú láti lè dáàbò bo dúkìá ṣọ́ọ̀ṣì, kí àwọn ọmọ má bàa gba ilẹ̀ àti àwọn ohun ìní mìíràn.”

Fífi Àwọ̀n Pa Àwọn Ẹ̀dá Òkun Nípakúpa

Ìwé ìròyìn The Globe and Mail sọ pé: “Lọ́dọọdún, ìwọ̀n ibi tó tóbi ju ilẹ̀ Kánádà lọ lábẹ́ àwọn òkun àgbáyé ni a ń fi àwọ̀n gbá. Tí àwọn èèyàn bá fẹ́ fa àwọ̀n ni wọ́n máa ń wọ́ àwọ̀n ńlá gba abẹ́ òkun kọjá, wọ́n á sì máa pa ẹja àti àwọn ẹ̀dá òkun tí ń gbé abẹ́ omi, tí àwọn ẹranmi ńláńlá ń rí jẹ, nípakúpa. Wọ́n tún máa ń fi àwọ̀n náà kó ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ẹ̀dá omi tí kì í ṣe òun ni àwọn apẹja ń wá, wọ́n á sì kú síbẹ̀.” Àwọn olùwádìí fojú díwọ̀n pé, “tí a bá rí i tí wọ́n pa edé kan, mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ẹja turbot tàbí ẹja cod kéékèèké ni àwọ̀n á ti kó tí wọ́n á sì kú.” Ìròyìn náà sọ pé ibikíbi tí wọ́n bá ti wọ́ abẹ́ òkun, àwọn ẹ̀dá tí kò léegun ẹ̀yìn, àwọn ẹran oníkarawun ni gbogbo wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán. Les Watling láti Yunifásítì Maine, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa òkun àti ẹ̀dá inú rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Kódà ẹni tí kì í ṣe onímọ̀ nípa ohun alààyè inú òkun á mọ̀ pé ọ̀nà ìpẹja wọ̀nyí ń ṣèpalára fún àwọn ẹ̀dá inú òkun. Kò sí ohun tó burú tó èyí lára ohun tí ẹ̀dá ń ṣe sí òkun.” Nígbà tí àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ń fi ìparun náà wé sísọ igbó daṣálẹ̀, wọ́n ní ó yẹ kí a ya àwọn àgbègbè kan sọ́tọ̀ bí òkun àìdẹ.

Kẹ́míkà Nínú Ohun Ìṣeré Ọmọdé

Ìwé ìròyìn The Independent, tí wọ́n ń ṣe nílùú London, sọ pé: “Ọ̀wọ́ àwọn kẹ́míkà kan tí wọ́n sábà máa ń lò láti mú kí àwọn ohun ìṣeré ọmọdé dẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe é fi nǹkan bí ìgbà ogún léwu ju bí a ṣe rò tẹ́lẹ̀ lọ.” Ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Netherlands fi hàn pé kẹ́míkà phthalate—tí wọ́n fi ń dẹ ike líle, bíi kẹ́míkà polyvinyl chloride—wà lára rọ́bà tí ọmọdé fi ń rin erìgì àti àwọn ohun ìṣeré mìíràn tí àwọn ọmọdé ń kì bọnu àti pé àwọn kẹ́míkà wọ̀nyí sì tètè máa ń dà pọ̀ mọ́ itọ́. Àwọn ìwádìí fi hàn pé bí oríṣi méjì kẹ́míkà phthalate bá pọ̀ nínú ara ó “lè fa àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín, kó sì mú kí kórópọ̀n wàkì.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, ó léwu fún àwọn ọmọdé ní pàtàkì nítorí pé “kíkéré tí wọ́n kéré níwọ̀n, ìdàgbàsókè ẹ̀yà ara wọn àti ṣíṣeéṣe tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa kó o jẹ fún ìgbà pípẹ́ yóò mú kí kẹ́míkà náà máa pa wọ́n lára dé ìwọ̀n kan.” Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n James Bridges, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń gbé ìṣòro náà yẹ̀ wò fún Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù, ó ní ominú ń kọ òun ní pàtàkì nípa “àwọn ọmọdé tí a ń gbé fún abánitọ́jú-ọmọ, fún àpẹẹrẹ ní àwọn ilé ìtọ́jú ọmọ lóòjọ́ tàbí ilé ìwòsàn tí kò bójú mu, níwọ̀n bí wọ́n ti sábà máa ń ki ohun tí wọ́n fi ń ṣeré sẹ́nu nígbà tí wọn ò ní nǹkan mìíràn láti ṣe ju ìyẹn lọ.” Orílẹ̀-èdè mẹ́fà ti fòfin de lílo àwọn kẹ́míkà wọ̀nyẹn nínú ṣíṣe ohun ìṣeré ọmọdé, àwọn mẹ́rin mìíràn sì ń múra àtiṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn Ìjọ Tí Kò Lálùfáà

Ìwádìí kan tí Ibùdó Ìdarí Iṣẹ́ Àlùfáà ti Ìjọ Àgùdà ṣe fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìjọ wọn ní Ítálì—ní pàtó iye wọ́n jẹ́ igbádínlẹ́gbàajì [3,800]—ni kò ní àlùfáà tó ń bójú tó ibẹ̀. Èyí kì í sì í ṣe àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní àwọn àgbègbè àrọko tàbí àdádó nìkan. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn La Repubblica ṣe sọ, “kì í sábà sí ‘àlùfáà kan tó ń bójú tó ṣọ́ọ̀ṣì’ kódà ní àwọn ìlú tó tóbi díẹ̀ (tí iye àwọn tó ń gbé ibẹ̀ wà láàárín ẹgbẹ̀rún kan sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta).” Láti bo àṣírí yìí, ńṣe ni wọ́n sábà máa ń fa àbójútó ọ̀wọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mélòó kan lé àlùfáà kan ṣoṣo lọ́wọ́ tàbí ọ̀wọ́ àwọn àlùfáà mélòó kan. Ìwé ìròyìn náà ṣàlàyé pé: “Ṣùgbọ́n, lọ́nà yìí, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì náà kì í lè fojú kan àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀, kì í sì í lè rí wọn lójoojúmọ́, àti pé . . . èyí ń sọ ọ́ di dandan fún àwọn àlùfáà láti máa sá láti ibì kan lọ sí ibòmíràn.” Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ń gbà rí sí ọ̀ràn àìtó náà. Àwọn ìlú ńlá bíi Róòmù ti gba àwọn àlùfáà láti ilẹ̀ òkèèrè. Ó kéré tán, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì méjì ní ilẹ̀ Ítálì ni wọ́n ti fà lé ọ̀gbẹ̀rì méjì lọ́wọ́, tí wọn kò gbọ́dọ̀ darí ìsìn Máàsì, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fi ìgbòkègbodò wọn mọ sórí fífúnni ní Ara Olúwa tàbí ṣíṣe ààtò ìrìbọmi àti ìsọmọlórúkọ tó bá di pàjáwìrì.

Èèyàn Púpọ̀ Sí I Ń Wọko Gbèsè

Sẹ́nétọ̀ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó ń jẹ́ Charles Grassley sọ pé: “Ọ̀ràn gbèsè ti di wàhálà ní Amẹ́ríkà.” Láti ìgbà tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti ṣe òfin lórí ọ̀ràn ìwọko gbèsè ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ [20,000,000] àwọn ọmọ Amẹ́ríkà ló ti kọ̀wé pé àwọn wọko gbèsè, ó sì lé ní ìdajì àwọn tó ti kọ irú ìwé bẹ́ẹ̀ láti ọdún 1985. Nígbà tó máa fi di àárín ọdún 1998, àwọn tó ti kọ̀wé pé àwọn wọko gbèsè ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ àtààbọ̀ láàárín oṣù méjìlá ṣáájú ìyẹn. Kí ló wá fa pípọ̀ tí iye náà ń pọ̀ sí i? Alan Greenspan tó jẹ́ alága Owó Àfipamọ́ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé lápá kan, pípọ̀ tí iye àwọn tó ń sọ pé àwọn wọko gbèsè ń pọ̀ sí i lè jẹ́ nítorí àwọn ìyípadà “nínú ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn nípa àbààwọ́n tí ọ̀ràn ìwọko gbèsè ń kó báni.” Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé ohun mìíràn tó ń fà á ni “lílò tí ọ̀pọ̀ èèyàn níbi gbogbo ń lo káàdì ìrajà àwìn tó ń jẹ́ kó mọ́ àwọn èèyàn lára láti máa jẹ gbèsè lọ ràì.”

Ṣé Aṣọ Kan Wà Tí Kò Lè Rùn?

Ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Le Monde, sọ pé: “Ó ti pé ọdún méjì báyìí tí àwọn tó mọṣẹ́ aṣọ ṣíṣe dunjú ti rí ìjẹ́pàtàkì àwọn aṣọ tí kì í rùn, tí a ń kọ oríṣiríṣi àkọlé sí pé wọ́n jẹ́ agbógunti bakitéríà . . . tàbí tí kì í rùn.” Àwọn aṣọ tí ń gbógun ti bakitéríà ti wá ń tà lọ́jà gan-an báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tí a ń tẹ́ sórí bẹ́ẹ̀dì ni wọ́n sábà máa ń fi aṣọ yìí ṣe, wọ́n tún ti ń fi ṣe ìbọ̀sẹ̀ àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ ara. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń yá lára láti wọ aṣọ tó ní èròjà phenol àti àwọn mẹ́táàlì tí ń yí ọ̀nà tí bakitéríà ń gbà ṣiṣẹ́ padà, níwọ̀n bí àwọn bakitéríà púpọ̀ ti máa ń ṣe èèyàn láǹfààní. Ìwé ìròyìn Le Monde sọ pé: “Kí awọ ara wa baà lè ṣiṣẹ́ dáadáa, ó nílò gbogbo àwọn bakitéríà tó lè ṣe é láǹfààní. Àwọn tí ń ṣe àwọn aṣọ tí ń gbógun ti bakitéríà ní láti gbà pé àwọn ti há báyìí, kí wọ́n sì wá nǹkan ṣe sí ìṣòro pàtàkì kan”—bí wọ́n ṣe lè ṣe é tí wọ́n á rẹ́yìn àwọn bakitéríà tí ń ṣèpalára láìjẹ́ pé wọ́n pa àwọn bakitéríà tó wúlò fún gbígbógun ti kòkòrò.

Wàhálà Omi Ń Pọ̀ Sí I

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Kì í ṣe pé oògùn apakòkòrò kún inú omi tí a ń mu nìkan ni, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ó jọ pé àwọn oògùn líle ti kún inú rẹ̀ pẹ̀lú.” Àwọn ibi mélòó kan ni àwọn oògùn líle náà gbà dé inú rẹ̀. Nígbà mìíràn, a máa ń da àwọn oògùn tí a kò nílò sínú ṣáláńgá. Ní àfikún sí i, a máa ń tọ oògùn dà nù. Bent Halling-Sorensen, láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìpoògùn Ìjọba ti Denmark, sọ pé: “Láàárín ìpín ọgbọ̀n sí ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún lára èyí tó pọ̀ jù lọ nínú oògùn apakòkòrò táwọn èèyàn àtẹranko ń lò ni wọ́n ń tọ̀ dà nù.” Ó jẹ́ àṣà àwọn àgbẹ̀ láti máa lo ìtọ̀ ẹran àti ajílẹ̀ nínú oko wọn. Tí oògùn bá dé àyíká náà, wọ́n lè wà bí a ṣe ṣe wọ́n gẹ́lẹ́, tàbí tí ara èèyàn bá ti yí wọn padà, wọ́n lè wá di èyí tó tètè máa ń ṣiṣẹ́ tàbí tí èròjà onímájèlé inú rẹ̀ pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ àti èyí tó sábà tètè máa ń yọ́ nínú omi. Steve Killeen, láti Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àyíká ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé: “Oògùn líle jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀wọ́ àwọn kẹ́míkà díẹ̀ tó wà nínú omi tí a kì í yẹ̀ wò.”

Èèyàn Ń Pọ̀ Sí I ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “Bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣẹ̀wọ̀n ní Amẹ́ríkà kò láfiwé ní orílẹ̀-èdè èyíkéyìí tí wọ́n ti ní ìjọba tiwa-n-tiwa, ó sì tilẹ̀ pọ̀ ju èyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìjọba apàṣẹ-wàá tíì ṣe lọ. Lọ́dún tó kọjá, ẹnì kan lára àádọ́jọ èèyàn tó ń gbé [Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà] (títí kan àwọn ọmọdé) ló ṣẹ̀wọ̀n.” Ìwọ̀n ìfinisẹ́wọ̀n náà jẹ́ ìlọ́po ogún ti Japan, ìlọ́po mẹ́fà ti Kánádà, àti láti nǹkan bí ìlọ́po márùn-ún sí mẹ́wàá ti àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù. Iye àwọn tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti di ìlọ́po mẹ́rin láti ọdún 1980. Ó lé ní ogún ọ̀kẹ́ [400,000] àwọn tó ń ṣẹ̀wọ̀n nísinsìnyí tó jẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìjoògùnyó ni wọ́n ṣe ń ṣẹ̀wọ̀n, síbẹ̀ iye èèyàn tó ń joògùn yó kò tíì yí padà láti ọdún 1988. Ìwé ìròyìn The Economist béèrè pé: “Yálà ọgbà ẹ̀wọ̀n ń ṣiṣẹ́ bí ohun èlò tí a fi ń bá ìwà ọ̀daràn jà tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀, báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó tí Amẹ́ríkà yóò fi lágbára láti máa bá a lọ láti fi àwọn èèyàn sẹ́wọ̀n léraléra?”

Gbígba Bẹ́ẹ̀tì Lé Amágẹ́dọ́nì Lórí

Ìwé ìròyìn The Guardian sọ pé, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló “ń gba bẹ́ẹ̀tì lé Amágẹ́dọ́nì lórí.” Ìwádìí kan tí a ṣe lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé kan fi hàn pé ìpín mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lérò pé ogun àgbáyé kan ni yóò fa òpin ayé, nígbà tí ìpín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lérò pé ìmóoru ilẹ̀ ayé ni yóò fa òpin ayé. Àwọn mìíràn méfò pé sísọlu asteroid ni yóò fà á. Ká sọ tòótọ́, ìwé ìròyìn The Guardian sọ pé ìpín mọ́kàndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a wádìí lẹ́nu wọn “lérò pé yóò ṣeé ṣe fún àwọn láti rí òpin ayé ju kí àwọn jẹ Tẹ́tẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ lọ.” Kí ló wá fa gbogbo ìméfò yìí nípa Amágẹ́dọ́nì? Ìwé ìròyìn náà sọ pé àwọn èèyàn “lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí Ẹgbẹ̀rúndún tó ń bọ̀ àti ìmọ̀lára àjálù tó so mọ́ ọn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́