Ó Ṣeyebíye Ju Owó Lọ
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KÁNÁDÀ
Ọ̀rọ̀ kan tí olóòtú ìwé ìròyìn The Monitor ti Bridgetown, Nova Scotia, kọ kà pé: “[Obìnrin] náà fún ọmọ rẹ̀ obìnrin ní ẹ̀bùn kan tó ṣeyebíye ju iyekíye lọ.” Ẹ̀bùn wo ló fún un? “Àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ àrà ọ̀tọ̀” rẹ̀ ni.
Anna àti Tanya ọmọ rẹ̀ yà ní ilé kan tí wọ́n ti ń lu àwọn nǹkan tí wọn ò lò mọ́ ní gbàǹjo, wọ́n sì ra àpò funfun kan tí Tanya á máa gbé Bíbélì rẹ̀ sí. Nígbà tí wọ́n délé, Tanya ṣí ibì kan nínú àpò náà ṣùgbọ́n ẹnu yà á láti rí ẹgbẹ̀rún dọ́là nínú rẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ padà lọ sí ilé tí wọ́n ti ra àpò náà, wọ́n sì kó owó náà fún obìnrin tó tà á fún wọn. Ó ṣe kedere pé ìyá obìnrin náà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, tó ní Àrùn Ọpọlọ Abọ́jọ́-ogbó-rìn, ló ni àpò tí wọn kì í fìgbà gbogbo lò náà, wọn ò sì yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa kí wọ́n tó tà á. Inú obìnrin náà dùn gan-an, ó sì wí pé: “Èyí á jẹ́ kí n tún bẹ̀rẹ̀ sí fọkàn tán àwọn èèyàn . . . Inú mi dùn láti mọ̀ pé àwọn olóòótọ́ èèyàn ṣì kù láyé.”
Àpilẹ̀kọ kan ní abala iwájú ìwé ìròyìn àdúgbò náà fa ọ̀rọ̀ Anna yọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a ò jẹ́ ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí a ṣe yẹn. A ní [ẹ̀rí-ọkàn] tí a fi Bíbélì kọ́. Bákan náà la fẹ́ fi ohun tó dáa kọ́ Tanya.” Ní ti Tanya, àpò funfun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rà náà á jẹ́ ohun ìránnilétí pàtàkì tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ìṣòtítọ́.