ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 11/8 ojú ìwé 4-7
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Kí Ló Dé Tí Ò Kásẹ̀ Ńlẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Kí Ló Dé Tí Ò Kásẹ̀ Ńlẹ̀?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsapá Láti Mú Un Kúrò ní China
  • Jíjẹ́ Ẹlẹ́nu Méjì
  • Ìdí Tí Kò Fi Kásẹ̀ Ńlẹ̀
  • Ǹjẹ́ Gbígba Ohun Asán Gbọ́ Bá Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Mu?
    Jí!—2008
  • Ṣé Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Báwo Ló Ṣe Gbilẹ̀ Tó Lónìí?
    Jí!—1999
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Èé Ṣe Tó Fi Léwu Gan-an?
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 11/8 ojú ìwé 4-7

Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán—Kí Ló Dé Tí Ò Kásẹ̀ Ńlẹ̀?

BÓYÁ ìwọ náà ti gbọ́ ọ rí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì ń ka kí ológbò dúdú gba iwájú wọn kọjá sí àmì pé nǹkan burúkú á ṣẹlẹ̀ sí àwọn tàbí kí wọ́n máa bẹ̀rù àtigba abẹ́ àkàsọ̀ kọjá. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tún gbà gbọ́ pé ọjọ́ burúkú ni ọjọ́ Friday tó bá bọ́ sí ọjọ́ kẹtàlá oṣù àti pé ó léwu láti wà ní àjà kẹtàlá nínú ilé. Irú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán báwọ̀nyí kò kásẹ̀ ńlẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò bọ́gbọ́n mu.

Rò ó wò ná. Kí ló fà á tí àwọn èèyàn kan fi máa ń mú ẹsẹ̀ ehoro lọ́wọ́ kiri bí ohun ààbò tàbí kí wọ́n máa fọwọ́ lu pátákó ko-ko-ko tí wọ́n bá fẹ́ sọ àwọn ohun kan tí a ń retí pé kó ṣẹ? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí pé wọ́n gbà gbọ́ pé ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí yóò mú oríire wá ni? Ìwé tó ń jẹ́ A Dictionary of Superstitions sọ pé: “Ẹnì kan tó gba ohun asán gbọ́ ní in lọ́kàn pé àwọn ohun kan, àwọn ibì kan, àwọn ẹran kan, tàbí àwọn ìṣe kan jẹ́ àmì oríire (àwọn àmì tàbí oògùn oríire) àti pé àwọn mìíràn kì í mú oríire wá (àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tàbí àjálù).”—Wo Gálátíà 5:19, 20.

Ìsapá Láti Mú Un Kúrò ní China

Ó hàn kedere pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti la ọ̀pọ̀ ìsapá láti mú un kúrò lóde òní já. Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún 1995, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ti Shanghai ṣe òfin ológun kan tó fòfin de ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, wọ́n ní nǹkan àtijọ́ ni, kò bóde mu mọ́, orílẹ̀-èdè àwọn sì ti lajú jùyẹn lọ. Ète rẹ̀ jẹ́ láti “fòpin sí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti ètò ìjọba oníṣàákọ́lẹ̀, láti ṣàtúnṣe àwọn àṣà ìsìnkú àti láti gbé àtúntò olú ìlú tó túbọ̀ lajú lárugẹ.” Àmọ́, kí ni àbájáde rẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ti sọ, àwọn ará Shanghai ṣì ń gba ohun asán wọn gbọ́. Ní ṣíṣàtakò sí òfin tí wọ́n fi de àṣà àwọn ará China tí wọ́n máa ń sun ayédèrú owó bébà lójú oórì àwọn baba ńlá, ẹnì kan tó lọ sójú oórì kan sọ pé: “A sun bílíọ̀nù mọ́kàndínlógún owó yuan [nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́ta dọ́là ti Amẹ́ríkà].” Ó fi kún un pé: “Ó jẹ́ àṣà wa láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa ń mú kí inú àwọn òrìṣà dùn.”

Ìwé ìròyìn Guangming Daily tí àwọn èèyàn máa ń ka ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ sí gan-an, ṣàlàyé nípa bí ìfòfindè náà kò ṣe gbéṣẹ́, ó sọ pé, “àwọn tó ń fi iṣẹ́ ìwòràwọ̀ jẹun ní China” lè tó “mílíọ̀nù márùn-ún, nígbà tó jẹ́ pé àròpọ̀ iye àwọn tó ń fi iṣẹ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ jẹun jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́wàá péré.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ó jọ pé àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìwòràwọ̀ ló pọ̀ jù.”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana, Ẹ̀dà Tó Jáde Kárí Ayé, sọ nípa ìdí tí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ò fi kásẹ̀ ńlẹ̀, ó sọ pé: “Nínú gbogbo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, ó máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn kì í jọ̀wọ́ àwọn àṣà àtijọ́ kan, ṣùgbọ́n wọ́n á gbé wọn jáde lákọ̀tun, wọ́n á sì tún túmọ̀ wọn sí àwọn nǹkan tuntun.” Ẹ̀dà ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica tó jáde láìpẹ́ yìí sọ pé: “Kódà ní ìgbà tí a sọ pé ojú ti là, ní sáà tí a ti ń fojú ribiribi wo ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro, bí a bá tẹ àwọn èèyàn kan nínú dáadáa, wọ́n á jẹ́wọ́ pé àwọn gba ohun kan tàbí méjì gbọ́ tí kò bọ́gbọ́n mu tàbí tó jẹ́ ohun asán.”

Jíjẹ́ Ẹlẹ́nu Méjì

Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ ẹlẹ́nu méjì nínú ọ̀ràn yìí, nítorí pé wọn kò lè sọ ohun tí wọ́n ń ṣe níkọ̀kọ̀ ní gbangba. Òǹṣèwé kan sọ pé ìdí tí wọ́n fi ń lọ́ra láti sọ̀rọ̀ síta jẹ́ nítorí kí wọ́n má bàa dà bí òmùgọ̀ lójú àwọn ẹlòmíràn. Nítorí náà, irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lè yàn láti máa pe àwọn ohun asán tí wọ́n gbà gbọ́ ní àṣà tó ti mọ́ àwọn lára. Fún àpẹẹrẹ, àwọn eléré ìdárayá lè sọ pé ohun tí àwọ́n ń ṣe wulẹ̀ jẹ́ ààtò ìmúrasílẹ̀ fún eré.

Láìpẹ́ yìí ni oníròyìn kan sọ̀rọ̀ tí ò dénú nípa lẹ́tà kan tí ń tọ̀dọ̀ ẹnì kan dọ́dọ̀ ẹlòmíràn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì ní láti fi ẹ̀dà púpọ̀ ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé ẹni tó bá fi lẹ́tà náà ṣọwọ́ sẹ́lòmíràn á ṣoríire, àmọ́ ẹni tí lẹ́tà yẹn bá gbẹ̀yìn sọ́wọ́ ẹ̀ á ṣorí burúkù. Lọ́nà kan ṣáá, lẹ́tà náà dọ́wọ́ oníròyìn náà, ó sì wí pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe nítorí pé mo gba ohun asán gbọ́ ni mo ṣe fi í ránṣẹ́ sí ẹlòmíràn. Kólúwarẹ̀ má kàn lọ ṣorí burúkú ni.”

Àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ògbógi nípa ìtàn ìṣẹ̀ǹbáyé lérò pé ọ̀rọ̀ náà “gbígba ohun asán gbọ́” pàápàá sinmi gan-an lórí èrò ẹni; wọn kì í fẹ́ ṣàpèjúwe àwọn ọ̀nà ìhùwà kan lọ́nà yẹn. Wọ́n fẹ́ràn láti lo ọ̀rọ̀ tó túbọ̀ “kó ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra” àmọ́ tí kò ní bí èèyàn nínú, ọ̀rọ̀ bí “àṣà àti ìgbàgbọ́ àbáláyé,” “ìtàn ìṣẹ̀ǹbáyé,” tàbí “àwọn ọ̀nà ìgbékalẹ̀ ìgbàgbọ́.” Dick Hyman sojú abẹ níkòó nínú ìwé rẹ̀, Lest Ill Luck Befall Thee—Superstitions of the Great and Small, ó sọ pé: “Bíi ti ọ̀ràn ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀fìnkìn, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló ń ṣalágbàwí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà á gbọ́.”

Àmọ́, orúkọ yòówù kí wọ́n pe ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, kò tíì kásẹ̀ ńlẹ̀. Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ní sànmánì yìí tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ti rìn jìnnà?

Ìdí Tí Kò Fi Kásẹ̀ Ńlẹ̀

Àwọn kan tilẹ̀ sọ pé gbígbàgbọ́ tí èèyàn ń gbà gbọ́ nínú ohun asán ò ba nǹkan kan jẹ́. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé wọ́n bí ìtẹ̀sí láti gbà gbọ́ nínú ohun asán mọ́ wa ni. Àmọ́, àwọn ìwádìí kan fi hàn pé kò rí bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé ohun tí wọ́n fi kọ́ àwọn èèyàn ló ń mú kí wọ́n gbà gbọ́ nínú ohun asán.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Stuart A. Vyse ṣàlàyé pé: “Àṣà gbígbàgbọ́ nínú ohun asán dà bí àwọn àṣà mìíràn tó jẹ́ pé bí èèyàn ṣe ń pẹ́ sí i láyé ló ń dara fún un. Wọn ò bí àṣà ká máa fọwọ́ lu pákó ko-ko-ko mọ́ wa; ńṣe la kọ́ ọ.” Wọ́n sọ pé nígbà tí àwọn èèyàn bá wà lọ́mọdé ni wọ́n máa ń gbà gbọ́ nínú idán pípa, wọ́n á wá di ẹni tó lè tètè gba ohun asán gbọ́ lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bá ti “dàgbàlagbà tó lọ́gbọ́n lórí.” Ibo ni wọ́n ti máa ń gbọ́ àwọn ohun asán tí wọ́n ń gbà gbọ́ yẹn?

Ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ló wé mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn táa yàn láàyò. Fún àpẹẹrẹ, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán jẹ́ apá kan ìsìn àwọn tó gbé ilẹ̀ Kénáánì kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó débẹ̀. Bíbélì sọ pé, iṣẹ́ wíwò, idán pípa, wíwá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ṣíṣiṣẹ́ oṣó, fífi èèdì di àwọn ẹlòmíràn, wíwádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò àti olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, àti ṣíṣèwádìí lọ́dọ̀ àwọn òkú jẹ́ àṣà àwọn ará Kénáánì.—Diutarónómì 18:9-12.

A mọ̀ pé àwọn ará Gíríìkì ìgbàanì pẹ̀lú da ìgbàgbọ́ nínú ohun asán pọ̀ mọ́ ìjọsìn wọn. Wọ́n gbà gbọ́ nínú òrìṣà, iṣẹ́ wíwò, àti idán pípa bíi ti àwọn ará Kénáánì. Àwọn ará Bábílónì máa ń wo inú ẹ̀dọ̀ ẹran, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé á tọ́ àwọn sọ́nà láti ṣe ohun tó yẹ. (Ìsíkíẹ́lì 21:21) A tún mọ̀ pé wọ́n máa ń ta tẹ́tẹ́, wọ́n sì máa ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ ohun tí Bíbélì pè ní “ọlọ́run Oríire.” (Aísáyà 65:11) Títí dòní olónìí ni a mọ̀ pé àwọn atatẹ́tẹ́ gbà gbọ́ nínú ohun asán.

A tilẹ̀ ti rí i pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mélòó kan ti rọ àwọn èèyàn láti fara jin tẹ́tẹ́ títa. Àpẹẹrẹ kan ni ti Ìjọ Kátólíìkì tó ń ṣètìlẹ́yìn fún títa tẹ́tẹ́ bingo. Lórí ọ̀ràn yìí, atatẹ́tẹ́ kan sọ pé: “Ó dá mi lójú pé Ìjọ Kátólíìkì mọ̀ pé [àwọn atatẹ́tẹ́ gba ohun asán gbọ́ gidigidi,] nítorí pé a sábà máa ń rí i tí àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ málọ̀ọ́kọ máa ń dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ pápá eré ìje pẹ̀lú àpótí ọrẹ lọ́wọ́ wọn. Báwo ni ọ̀pọ̀ lára wa táa jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì á ṣe kọjá lára ‘obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ málọ̀ọ́kọ’ láìṣètọrẹ, ká wá retí pé tẹ́tẹ́ wa á jẹ? Nítorí náà, àá yáa ṣètọrẹ. Bí a bá sì jẹ lọ́jọ́ yẹn, ńṣe làá yáa túbọ̀ ṣètọrẹ gan-an, pẹ̀lú ìrètí pé ńṣe làá túbọ̀ máa ṣoríire lọ.”

Àwọn àpẹẹrẹ kan tó wọ́pọ̀ nípa ìsopọ̀ tó wà láàárín ìsìn àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ni ti àwọn ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tó so pọ̀ mọ́ Kérésìmesì, àjọ̀dún tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ń gbé lárugẹ. Ara ẹ̀ ni ìrètí pé bí ẹni méjì bá fẹnu konu lábẹ́ igi àfòmọ́ oníṣàáná, wọ́n á fẹ́ ara wọn, ọ̀pọ̀ ohun asán mìíràn tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ nípa Bàbá Kérésìmesì pẹ̀lú wà lára ẹ̀.

Ìwé Lest Ill Luck Befall Thee sọ pé, ìgbìyànjú “láti rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú” ló tanná ran ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Nítorí náà, bó ṣe rí lónìí àti jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá, àwọn èèyàn gbáàtúù àti àwọn alákòóso ayé máa ń woṣẹ́ lọ́dọ̀ àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àti àwọn mìíràn tí wọ́n ní àwọ́n lágbára idán. Ìwé Don’t Sing Before Breakfast, Don’t Sleep in the Moonlight ṣàlàyé pé: “Àwọn èèyàn ní láti gbà gbọ́ pé oògùn wà, èèdì tí yóò gbógun ti bíbẹ̀rù àwọn ẹ̀mí tí a mọ̀ àti èyí tí a kò mọ̀ sì wà.”

Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ìgbòkègbodò tó kan gbígbàgbọ́ nínú ohun asán ti gbìyànjú láti mú kí ẹ̀dá èèyàn máa ronú pé àwọ́n lè kápá ìbẹ̀rù àwọn. Ìwé Cross Your Fingers, Spit in Your Hat sọ pé: “Ohun tí [gbogbo ayé] ń sọ pé ó fà á tí àwọn fi gbára lé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kò pé méjì. Tí [wọ́n] bá dojú kọ ìṣòro tí apá [wọn] ò ká—tó sinmi lé ‘oríire’ tàbí ‘àkọsẹ̀bá’—ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ló ń mú kí [wọ́n] túbọ̀ fọkàn balẹ̀.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i fún ẹ̀dá èèyàn, wọ́n ṣì ń nímọ̀lára pé ẹ̀mí àwọn kò dè. Ní gidi, àìláàbò ti pọ̀ sí i nítorí àwọn ìṣòro tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti dá sílẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Vyse sọ pé: “Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ìgbàgbọ́ nínú agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ ti kó wọ inú àṣà wa gan-an . . . nítorí ayé tí gbogbo wa ń gbé yìí ti ru ìmọ̀lára àìdájú sókè nínú wa.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia wá sọ pé: “Bí àwọn èèyàn bá ṣì ń ṣiyèméjì nípa ọjọ́ ọ̀la . . . bóyá ni ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lè kásẹ̀ ńlẹ̀ láé.”

Àmọ́, lákòópọ̀, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán kò tíì kásẹ̀ ńlẹ̀ nítorí pé àwọn ohun tó sábà máa ń ba aráyé lẹ́rù ni gbòǹgbò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ ìsìn táwọn èèyàn yàn láàyò ń tì í lẹ́yìn. Àmọ́, ṣé ó wá yẹ ká sọ pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ń ṣàǹfààní, nítorí pé ó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kápá àwọn àìdánilójú wọn? Ṣé kò lè pani lára? Àbí ohun tó léwu tó yẹ ká máa yẹra fún ni?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà ní China nìkan lè tó mílíọ̀nù márùn-ún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Nípa ṣíṣonígbọ̀wọ́ tẹ́tẹ́ “bingo” ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣètìlẹ́yìn fún ìgbàgbọ́ nínú ohun asán

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ló bí àwọn àṣà ṣíṣọdún Kérésìmesì bíi fífẹnukonu lábẹ́ igi àfòmọ́ oníṣàáná

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́