Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Àwọn Ọba Mẹ́ta Bẹ Jésù Wò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?
LẸ́YÌN ìbí Jésù, àwọn ènìyàn olókìkí láti Ìlà Oòrùn ayé wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti wá júbà fún un bí ọba àwọn Júù. Títí dòní, ọ̀pọ̀ èèyàn jákèjádò ayé tó ń ṣọdún Kérésìmesì ló ń ṣèrántí àbẹ̀wò yẹn.
Ní àwọn ibì kan, àwọn èèyàn máa ń ya Àwòrán Ìbí Jésù tó ń fi àwọn olùbẹ̀wò ará Ìlà Oòrùn ayé hàn bí ọba mẹ́ta tó kó ẹ̀bùn wá fún ọmọ tuntun náà, Jésù. Láwọn ilẹ̀ míì, àwọn ọmọdé a máa rìn kiri àdúgbò nínú aṣọ “Àwọn Ọba Mímọ́.” Àní lẹ́yìn ogún ọ̀rúndún, àwọn èèyàn níbi gbogbo ṣì ń ṣèrántí àwọn olùbẹ̀wò tó ṣàjèjì wọ̀nyẹn. Ta tiẹ̀ ni wọ́n?
Ṣé Ọba Ni Wọ́n?
Ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wà nínú Bíbélì, nínú ìwé Mátíù. Ó kà níbẹ̀ pé: “Lẹ́yìn ìbí Jésù . . . àwọn awòràwọ̀ láti ìlà oòrùn dé lọ́jọ́ kan láti Jerúsálẹ́mù, wọ́n ń béèrè pé, ‘Ọba àwọn Júù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí dà? A rí ìràwọ̀ rẹ̀ nígbà tó yọ, ìyẹn la fi ní ká wá júbà rẹ̀.’” (Mátíù 2:1, 2, New American Bible) Èé ṣe tí ìtumọ̀ Bíbélì yìí fi pe àwọn olùbẹ̀wò náà láti ìlà oòrùn ayé ní awòràwọ̀, tí kò pè wọ́n ní ọba?
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí lo ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà maʹgos. Oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì tú ọ̀rọ̀ yìí sí “àwọn amòye,” “àwọn awòràwọ̀,” tàbí kí wọ́n má tilẹ̀ tú u, kí wọ́n kàn pè é ní “àwọn Magí.” Ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ń lò fáwọn agbaninímọ̀ràn àti alásọtẹ́lẹ̀, tí wọ́n ń lo ipò ìràwọ̀ àti pílánẹ́ẹ̀tì láti sàsọtẹ́lẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi ka àwọn olùbẹ̀wò wọ̀nyí tó wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sí woṣẹ́woṣẹ́, tí ń lo agbára òkùnkùn tí Ọlọ́run kórìíra.—Diutarónómì 18:10-12.
Wọ́n ha tún í ṣe ọba bí? Bó bá ṣe pé ọba ni wọ́n, kò sóhun tó burú nínú ká retí pé kí Bíbélì pè wọ́n bẹ́ẹ̀. Mátíù 2:1-12 lo ọ̀rọ̀ náà “ọba” lẹ́ẹ̀mẹrin, ó lò ó fún Jésù lẹ́ẹ̀kan, ó sì lò ó fún Hẹ́rọ́dù lẹ́ẹ̀mẹ́ta. Àmọ́ kò pe àwọn awòràwọ̀ náà ní ọba rárá. Lórí kókó yìí, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia sọ pé: “Kò sí ìkankan lára àwọn Bàbá Ìjọ tó sọ pé ọba làwọn awòràwọ̀ náà.” Bíbélì pẹ̀lú kò pè wọ́n bẹ́ẹ̀.
Ṣé Mẹ́ta Ni Wọ́n?
Bíbélì kò sọ iye àwọn awòràwọ̀ náà. Síbẹ̀, àwọn Àwòrán Ìbí Jésù àti àwọn orin Kérésì máa ń ṣètìlẹ́yìn fún àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ náà pé mẹ́ta ni wọ́n. Ó jọ pé ohun tó fa èyí ni pé oríṣi ẹ̀bùn mẹ́ta ni wọ́n mú wá. Nípa èyí, Bíbélì sọ pé: “Wọ́n ṣí àwọn ìṣúra wọn pẹ̀lú, wọ́n sì fún [Jésù] ní àwọn ẹ̀bùn, wúrà àti oje igi tùràrí àti òjíá.”—Mátíù 2:11.
Ǹjẹ́ ó mọ́gbọ́n dání láti parí èrò sí pé mẹ́ta làwọn awòràwọ̀ náà gbọ́dọ̀ jẹ́ nítorí pé wọ́n fún un ní oríṣi ẹ̀bùn mẹ́ta? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ nípa gbajúmọ̀ míì tó wá bẹ Ísírẹ́lì wò. Nígbà kan rí, ọbabìnrin Ṣébà wá kí Sólómọ́nì Ọba, ó sì fún un ní “òróró básámù àti wúrà púpọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye.” (1 Àwọn Ọba 10:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣi ẹ̀bùn mẹ́ta la sọ̀rọ̀ rẹ̀, ọbabìnrin Ṣébà nìkan la sọ pé ó fún un lẹ́bùn. Iye ẹ̀bùn tó mú wá kò fi hàn pé èèyàn mẹ́ta ló wá kí Sólómọ́nì nígbà yẹn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀bùn mẹ́ta tí wọ́n fún Jésù kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan í ṣe pẹ̀lú iye èèyàn tó mú wọn wá.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia sọ pé: “Àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere kò sọ̀rọ̀ nípa iye àwọn awòràwọ̀ náà, kò sì sí ìsọfúnni pàtó nípa rẹ̀. Àwọn kan lára Bàbá Ìjọ sọ pé mẹ́ta làwọn awòràwọ̀ náà; ó jọ pé iye ẹ̀bùn náà ló mú kí wọ́n rò bẹ́ẹ̀.” Ó tún sọ síwájú sí i pé onírúurú àwòrán ya èèyàn méjì, mẹ́ta, mẹ́rin tó wá kí Jésù, ọ̀kan tilẹ̀ ya mẹ́jọ pàápàá. Àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kan sọ pé wọ́n tó méjìlá. Ohun tó kàn ṣẹlẹ̀ ni pé kò sí báa ṣe lè mọ iye àwọn awòràwọ̀ náà.
Ìtàn Tó Lókìkí, Ṣùgbọ́n Tí Kò Jóòótọ́
Ní ìlòdì sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́, kì í ṣe Bẹ́tílẹ́hẹ́mù làwọn awòràwọ̀ náà kọ́kọ́ dé lẹ́yìn ìbí Jésù, bí kò ṣe Jerúsálẹ́mù. Wọn ò sí níbẹ̀ nígbà ìbí Jésù. Lẹ́yìn náà, tí wọ́n lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Bíbélì sọ pé “nígbà tí wọ́n sì wọ ilé náà, wọ́n rí ọmọ kékeré náà.” (Mátíù 2:1, 11) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé nígbà táwọn awòràwọ̀ náà wá kí Jésù, inú ilé gidi ni òun àti ìdílé rẹ̀ ń gbé. Inú ibùjẹ ẹran kọ́ ni wọ́n ti bá a.
Báa bá fẹ́ tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ìtàn olókìkí tó sọ pé ọba mẹ́ta wá bọlá fún Jésù nígbà ìbí rẹ̀ kì í ṣòótọ́. Gẹ́gẹ́ bí a ti wí lókè, Bíbélì kọ́ni pé àwọn awòràwọ̀ tó wá kí Jésù kì í ṣe ọba, bí kò ṣe àwọn awòràwọ̀ oníṣẹ́ òkùnkùn. Ìwé Mímọ́ kò sọ iye wọn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọn kò wá bẹ Jésù wò nígbà ìbí rẹ̀, nígbà tó wà ní ibùjẹ ẹran, àmọ́, ẹ̀yìn ìgbà náà, nígbà tí ìdílé rẹ̀ ń gbé inú ilé kan, ni wọ́n tó wá.
Lójú àwọn èèyàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn yìí kì í ṣòótọ́ nítorí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ìtàn ìgbà ọdún tó dùn-ún gbọ́ ni wọ́n ń pe ìtàn olókìkí nípa àwọn ọba mẹ́ta wọ̀nyí àtàwọn ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ Kérésìmesì míì. Àmọ́ o, àwọn Kristẹni kò fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ọ̀nà ìjọsìn tòótọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lára Jésù. Nígbà kan tó ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Ó sọ pé “àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.”—Jòhánù 4:23.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
“Fífi Ìbà fún Àwọn Awòràwọ̀”