ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/08 ojú ìwé 26-29
  • Ibi Tí Mo Ti Kọ́kọ́ Gbọ́ Tí Wọ́n Pe Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibi Tí Mo Ti Kọ́kọ́ Gbọ́ Tí Wọ́n Pe Jèhófà
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Látojú Ogun Ni Mo Ti Dèrò Ẹ̀wọ̀n
  • Bí Mo Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run Tòótọ́
  • Iṣẹ́ Ìsìn Àkànṣe
  • Bá A Ṣe Ń Tẹ̀wé Nígbà Tí Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa
  • Àwọn Ọlọ́pàá Ń Dọdẹ Wa
  • Jèhófà, Ilé Ìṣọ́ Agbára
  • Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́
    Jí!—2002
  • Àdánwò Ìgbàgbọ́ ní Slovakia
    Jí!—2003
  • Jehofa Pa Iwalaaye Ai Mọ́ Ninu Ọgbà-ẹ̀wọ̀n Aṣálẹ̀ Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Mo Kọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 7/08 ojú ìwé 26-29

Ibi Tí Mo Ti Kọ́kọ́ Gbọ́ Tí Wọ́n Pe Jèhófà

Gẹ́gẹ́ bí Pavol Kovár ṣe sọ ọ́

Òjò bọ́ǹbù tó ń rọ̀ ò jẹ́ ká lè débi tá a fẹ́ forí pa mọ́ sí. Bí bọ́ǹbù yẹn ṣe túbọ̀ ń bú gbàù, tí ibi tá a wà sì ń mì tìtì, ọ̀kan lára àwọn tá a jọ wà lẹ́wọ̀n gbàdúrà sókè pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́ gbà wá o! Wo torúkọ mímọ́ rẹ mọ́ wa lára o!”

ỌJỌ́ kẹjọ oṣù January, ọdún 1945 ní ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ́ ẹ kà tán yìí wáyé, látojú ogun ni mo ti dèrò ẹ̀wọ̀n nílùú Linz lórílẹ̀-èdè Austria. Àwa èèyàn tá a tó àádọ́ta lé rúgba [250] la wà nínú ilé yẹn, kò sì sẹ́ni tó kú nínú wa nígbà táwọn bọ́ǹbù wọ̀nyẹn bú. Nígbà tá a jáde nínú ilé yẹn, a rí ọ̀pọ̀ nǹkan tí bọ́ǹbù yẹn ti bà jẹ́. Àdúrà àtọkànwá tí mo gbọ́ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ẹni tó gbà á. Kí n tó ṣàlàyé bí mo ṣe wá mọ ẹni tó ń jẹ́ Jèhófà nígbà tó yá, ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe jẹ́ fún yín.

Ọjọ́ kejìdínlógún oṣù September, ọdún 1921 ni wọ́n bí mi, nínú ilé kan nítòsí abúlé tí wọ́n ń pè ní Krajné, lápá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Slovakia tó jẹ́ apá kan ìlú Czechoslovakia nígbà kan rí. Pùròtẹ́sítáǹtì làwọn òbí mi, wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn wọn. Àràárọ̀ ọjọ́ Sunday ni bàbá mi máa ń ka Bíbélì tó jẹ́ ti ìdílé wa, gbogbo àwa ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, tó fi mọ́ màmá mi, sì máa ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́. Àmọ́, bàbá mi ò dárúkọ Jèhófà lójú mi rí. Àwọn èèyàn ò wayé máyà lápá ibi tá à ń gbé, àwa náà sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tá a ní.

Àyà àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí já nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939. Ọ̀pọ̀ wọn ló rántí palaba ìyà tí wọ́n jẹ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní jà tán ní ogún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Lọ́dún 1942, wọ́n ní kí n wá dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Slovakia. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè Jámánì ni Slovakia wà, wọ́n gbìyànjú láti dá ìjọba tiwa-n-tiwa padà sórílẹ̀-èdè náà lóṣù August, ọdún 1944. Nígbà tọ́wọ́ pálábá wọn ségi, mo wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn sójà orílẹ̀-èdè Slovakia tí wọ́n kó lọ sáwọn ilẹ̀ táwọn ará Jámánì ń ṣàkóso. Mo bára mi ni àhámọ́ tó wà Gusen, lẹ́bàá àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Mauthausen, nítòsí ìlú Linz.

Látojú Ogun Ni Mo Ti Dèrò Ẹ̀wọ̀n

Wọ́n ní ká máa lọ ṣiṣẹ́ níléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe ọkọ̀ òfuurufú nítòsí abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Sankt Georgen an der Gusen. Ibi tí wọ́n ti ń la pákó ni wọ́n ní kí n ti máa ṣiṣẹ́. Oúnjẹ tí wọ́n ń fún wa jẹ ò tó nǹkan, nígbà tó tún wá di January ọdún 1945, ńṣe ni wọ́n dín ìwọ̀nba oúnjẹ tí wọ́n ń fún wa kù torí pé àwọn ọmọ ogun Násì ń fìdí rẹmi lójú ogun. Oúnjẹ kan ṣoṣo tó lọ́wọ́ọ́wọ́ tí wọ́n ń fún wa jẹ ò ju ọbẹ̀ kékeré kan báyìí lọ. Àràárọ̀ làwọn òṣìṣẹ́ máa ń wá látinú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Mauthausen. Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà sábà máa ń lu àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí kò bá lè ṣiṣẹ́ mọ́ títí tí wọ́n á fi kú. Wọ́n á wá ní káwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ wọn kó wọn sínú ọkọ̀ akẹ́rù, kí wọ́n sì gbé wọn lọ síbi tí wọ́n ti máa sun wọn.

Láìfi gbogbo ìyà àjẹkúdórógbó yìí pè, a nírètí pé ogun yẹn máa tó dópin. Lọ́jọ́ karùn-ún oṣù May, ọdún 1945, oṣù mẹ́rin lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, mo jí láàárọ̀, àmọ́ ṣìbáṣìbo bá mi. Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ti sá lọ, wọ́n to àwọn ìbọn wọn jọ pelemọ, gbogbo ilẹ̀kùn sì wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu. Kedere là ń rí báwọn ẹlẹ́wọ̀n ṣe ń rọ́ jáde tìrítìrí látinú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kejì tó wà lọ́ọ̀ọ́kán wa. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí fìkanra gbẹ̀san. Bí wọ́n ṣe pa àwọn èèyàn nípakúpa lọ́jọ́ náà ò tíì kúrò lọ́kàn mi dòní olónìí.

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn kan tí wọ́n máa ń pè ní kapo pa, ìyẹn àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ìwà ìkà táwọn kapo yìí gan-an máa ń hù nígbà míì ju tàwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Násì gbà síṣẹ́ lọ. Kòrókòró ni mo rí i tí ẹlẹ́wọ̀n kan lu kapo kan pa bó ti ń kígbe lóhùn rara pé: “Òun ló pa bàbá mi. A jọ wà ńbí látọjọ́ yìí ni o, kó tó lù ú pa níjẹta!” Nígbà tó fi máa dìrọ̀lẹ́, ọgọ́rọ̀ọ̀rún òkú ti sùn lọ, ìyẹn òkú àwọn kapo, àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n míì. Ká tó kúrò níbẹ̀, a rìn yíká gbogbo àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ yẹn, a fara balẹ̀ wo oríṣiríṣi àwọn nǹkan tí wọ́n fi máa ń pa àwọn èèyàn, ní pàtàkì, iyàrá tí wọ́n ti máa ń fi afẹ́fẹ́ olóró gbẹ̀mí àwọn èèyàn àti ibi tí wọ́n ti máa ń finá sun wọ́n.

Bí Mo Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run Tòótọ́

Ìparí oṣù May ọdún 1945 ni mo padà sílé. Ní gbogbo ìgbà tí mò ń wí yìí, kì í wulẹ̀ ṣe pé àwọn òbí mi ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run nìkan ni, ìyẹn orúkọ tí mo gbọ́ nígbà tí mo wà nínú àhámọ́ yẹn, àmọ́ wọ́n ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí mo padà dé lèmi àti Oľga pàdé. Ọmọbìnrin yìí kì í fàwọn nǹkan tẹ̀mí ṣeré, ọdún kan lẹ́yìn ìgbà náà la ṣègbéyàwó. Ìtara tí Oľga ní fún òtítọ́ Bíbélì ló ran èmi pàápàá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Èmi, Oľga àtàwọn èèyàn tó tó àádọ́ta [50] la ṣèrìbọmi, nínú odò Váh nílùú Piešťany ní ọ̀kan lára àwọn àpéjọ tá a ṣe gbẹ̀yìn kí ìjọba Kọ́múníìsì tó fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́dún 1949. Kò pẹ́ púpọ̀ tá a fi bí àwọn ọmọbìnrin wa méjì, ìyẹn Oľga àti Vlasta.

Ilé wa ni Ján Sebín, arákùnrin kan tó wà lára àwọn tó tún ètò ṣe fún iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, sábà máa ń dé sí, a sì jọ máa ń jáde òde ẹ̀rí dáadáa. Láìfi gbogbo àtakò táwọn ìjọba Kọ́múníìsì ń ṣe pè, a ò dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. A máa ń fọgbọ́n báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì, kò sì pẹ́ tá a fi ní ọ̀pọ̀ èèyàn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èmi àtìyàwó mi là ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀nyí lẹ́yìn tí Ján kó kúrò ládùúgbò wa. A sábà máa ń ráwọn ẹni ọ̀wọ́n wọ̀nyí àtàwọn ọmọ àti ọmọ ọmọ wọn láwọn àpéjọ wa. Ìdùnnú sì máa ń ṣubú layọ̀ fún wa nígbà tá a bá rí wọn!

Iṣẹ́ Ìsìn Àkànṣe

Nígbà tó fi máa di ọdún 1953, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ òléwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ni wọ́n ti jù sẹ́wọ̀n. Torí náà, wọ́n ní kí n wá máa lọ wàásù níbi tó tó àádọ́jọ [150] kìlómítà sílé wa. Lẹ́yìn tí n bá ti ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí mò ń ṣe láwọn ọ̀sán Sátidé, ọ̀sẹ̀ méjì méjì ni mo máa ń wọkọ̀ ojú irin láti Nové Mesto nad Váhom lọ sílùú Martin tó wà lápá àríwá orílẹ̀-èdè Slovakia. Gbogbo alẹ́ Saturday àtọjọ́ Sunday, tí mo bá fi wà níbẹ̀ ni mo fi máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó bá wá dìrọ̀lẹ́ Sunday, mo máa ń wọkọ̀ ojú irin padà lọ sí Nové Mesto. Ọ̀gànjọ́ òru ni mo máa ń débẹ̀, mo sì máa ń dé sọ́dọ̀ tọkọtaya kan tí wọ́n ti dàgbà, ara wọn yọ̀ mọ́ọ̀yàn gan-an ni, ọ̀dọ̀ wọn ni mo sì máa ń sùn mọ́jú. Ibẹ̀ ni mo máa ń gbà lọ síbi iṣẹ́ láàárọ̀ Monday, kí n tó wá padà sílé wa ní Krajné. Láwọn òpin ọ̀sẹ̀ tí mi ò bá sí nílé, Oľga ló máa ń bójú tó àwọn ọmọ wa.

Nígbà tó di ọdún 1956, wọ́n ní kí n wá wọṣẹ́ alábòójútó àyíká, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn tó máa ń bẹ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò láti máa fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká rí níbẹ̀ ló ti wà lẹ́wọ̀n báyìí, mo rí i lóòótọ́ pé ó yẹ kí n gba iṣẹ́ náà. Ó dá èmi àti ìyàwó mi lójú pé Jèhófà máa ran ìdílé wá lọ́wọ́.

Òfin ìjọba Kọ́múníìsì ni pe gbogbo èèyàn ló gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ oṣù. Ìjọba kì í fojúure wo àwọn tí ò bá níṣẹ́ lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Torí náà, mi ò fiṣẹ́ oṣù tí mò ń ṣe sílẹ̀. Mo máa ń lo òpin ọ̀sẹ̀ méjì pẹ̀lú ìdílé mi lóṣù, a sì jọ máa ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan pa pọ̀, tó fi mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí; àmọ́ mo máa ń fi òpin ọ̀sẹ̀ méjì yòókù nínú oṣù ṣèbẹ̀wò sí ọ̀kan lára àwọn ìjọ mẹ́fà tó wà ní àyíká wa.

Bá A Ṣe Ń Tẹ̀wé Nígbà Tí Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa

Ojúṣe àwọn alábòójútó àyíká ni láti rí i dájú pé gbogbo ìjọ tó bá wà láyìíká wọn ló ní àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì. Ọwọ́ la kọ́kọ́ máa fi ń da àwọn ìwé ìròyìn wa kọ tàbí ká fi ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé tẹ̀ ẹ́. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n ṣe sórí fíìmù ìtẹ̀wé gbà, a sì ń fi ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Látorí fíìmù ìtẹ̀wé yìí làwọn ìjọ ti máa ń ṣe ẹ̀dà tiwọn sórí bébà. Àwọn tó máa ń lọ ra àwọn bébà wọ̀nyẹn gbọ́dọ̀ já fáfá kí wọ́n sì nígboyà, torí pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n fura sẹ́ni tó bá wá ra irú bébà yẹn jọ rẹpẹtẹ.

Štefan Hučko já fáfá nídìí iṣẹ́ yìí gan-an ni, ó sì tún nítara pẹ̀lú. Àpẹẹrẹ kan rèé: Ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan pé, Štefan padà lọ sí ṣọ́ọ̀bù kan tí wọ́n ti máa ń ta bébà nílùú kan tó jìnnà síbi tó ń gbé, bó ṣe fẹ́ máa lọ torí bébà yẹn ti tán níbẹ̀ ló rí ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ṣọ́ọ̀bù yẹn tó ti ṣèlérí fún un pé òun máa bá a ra bébà yẹn wá. Bí Štefan ṣe fẹ́ lọ bá ọmọbìnrin yẹn ló bá tajú kán rí ọlọ́pàá kan tó wọnú ṣọ́ọ̀bù náà. Ìgbà yẹn gan-an lọmọbìnrin yẹn rí Štefan, ló bá sọ tayọ̀tayọ̀ pé: “Ọ̀gá, ẹ mọ̀-ọ́n rìn o, a ti ní àwọn bébà tẹ́ ẹ máa ń bá wa rà yẹn!”

Štefan yara ro ohun tó máa sọ, ó ní: “Ẹ máà bínú o, ó ní láti jẹ́ pé ẹlòmíì lẹ fi mí pè. Fíìmù ìtẹ̀wé kan ṣoṣo péré lèmí fẹ́ rà.”

Nígbà tí Štefan padà dénú mọ́tò, kò wù ú kó fi bébà tó torí ẹ̀ wá yẹn sílẹ̀. Torí náà, ó ṣí fìlà, ó sì tún bọ́ kóòtù tó wọ̀ kí wọ́n má bàa dá a mọ̀, ó padà wọnú ṣọ́ọ̀bù yẹn lọ, ó sì lọ bá ọmọbìnrin yẹn. Ó wá sọ fún un pé: “Èmi ni mo wá síbí lọ́sẹ̀ tó kọjá, o sì sọ fún mi pé wàá bá mi ra àwọn bébà ìtẹ̀wé kan. Ṣó ti wà nílẹ̀?”

Ọmọbìnrin yẹn fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, a ti ni wọ́n lọ́wọ́ báyìí. Ṣẹ́ ẹ rí i, kò tíì pẹ́ tọ́kùnrin kan wá síbí, ọkùnrin náà mà jọ yín gan-an o, ńṣe lẹ dà bí ìbejì!” Štefan yáa ra àwọn bébà rẹpẹtẹ tó fẹ́ rà, ó sì tètè kúrò níbẹ̀, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kóun rí i rà.

Láwọn ọdún 1980, inú àjà ilẹ̀ àtàwọn ibi kọ́lọ́fín míì la ti máa ń fi àwọn ẹ̀rọ kékeré tó máa ń ṣe àdàkọ ìwé tẹ àwọn ìtẹ̀jáde wa. Kò pẹ́ púpọ̀ tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí tẹ iye ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn ìwé ńlá, tó máa kárí àwọn ará wa tó sì tún máa ṣẹ́ kù pàápàá.

Àwọn Ọlọ́pàá Ń Dọdẹ Wa

Láàárín ọdún 1960 sí 1969, ó ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ní kí n lọ fara mi hàn lọ́dọ̀ àwọn ológun tó wà níléeṣẹ́ tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan tí ò wọṣọ ológun ló fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, wọ́n bi mí pé: “Látìgbà wo lo ti máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Àwọn wo lẹ jọ máa ń pàdé?” Nígbà tí mo kọ̀ láti sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́, wọ́n ní àwọn á máa kàn sí mi nígbà míì. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn témi àtàwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ fojú kojú.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n wá mú mi, láti ibi iṣẹ́, lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Wọ́n fún mi níwèé kan pé kí n kọ orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí mo bá mọ̀ sí i. Nígbà tẹ́ni tó fún mi níwèé yẹn máa padà ní nǹkan bíi wákàtí kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, mi ò kọ nǹkan kan sínú ìwé yẹn, mo sì ṣàlàyé fún un pé mi ò lè kọ orúkọ ẹnì kankan. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n tún wá gbé mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá pé kí n wá lọ kọ orúkọ àwọn ará tí mo bá mọ̀, mo sì tún kọ̀ jálẹ̀. Àmọ́, lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n lù mí, nígbà tí mo sì fẹ́ máa lọ, wọ́n ń fìpá taari mi títí tí mo fi jáde nínú ilé náà.

Lẹ́yìn ìgbà náà, odindi ọdún kan gbáko làwọn ọlọ́pàá wọ̀nyẹn ò fi dà mí láàmú mọ́. Wọ́n wá rán ọkùnrin kan tá a ti jọ wà lẹ́wọ̀n nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Násì sí mi. Ọkùnrin yẹn sọ fún mi pé: “Àfi ká tún wá ọgbọ́n míì tọ́wọ́ wa fi máa tẹ ẹ̀yin aráabí yìí. Bá a bá fi Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sẹ́wọ̀n, wọ́n á ti di márùn-ún nígbà tó bá fi máa jáde.” Ohun tí ìjọba fẹ́ ṣe nígbà yẹn ni pé kí wọ́n máa fàṣẹ wọn darí iṣẹ́ wa dé ìwọ̀n àyè kan. Àmọ́ mo ti pinnu pé mi ò ní sọ ohunkóhun tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi wà lára àwọn táwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ máa ń fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò torí iṣẹ́ ìwàásù wa. Ìgbà míì wà tí wọ́n á ṣe bí ọ̀rẹ́ sí wa, ìgbà míì sì rèé, wọ́n á fi ẹnì kan nínú wa sẹ́wọ̀n. Mo dúpẹ́ pé wọn ò fi mí sẹ́wọ̀n ní gbogbo àkókò tá à ń wí yìí. Àmọ́, àwọn ọlọ́pàá wọ̀nyẹn ò yé dọdẹ wa títí di ọdún 1989, nígbà tí ètò ìjọba Kọ́múníìsì forí ṣánpọ́n lórílẹ̀-èdè Czechoslovakia.

Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá àgbà fáwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó wà ní Bratislava wá mi wálé. Ó wá bẹ̀ mí pé kí n máà bínú, ó ní: “Bí wọ́n bá fi dá mi, a ò kúkú ní dà yín láàmú.” Ó wá fún mi ní àpò méjì tó kún fún èso tí wọ́n ṣe sínú agolo.

Jèhófà, Ilé Ìṣọ́ Agbára

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa fún odindi ogójì ọdún àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí mo di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú mi dùn pé ìgbésí ayé mi nítumọ̀ gan-an. Àwọn ohun tójú wa rí láwọn ọdún wọ̀nyẹn ti jẹ́ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà tá a jólóòótọ́ túbọ̀ mọwọ́ ara wa. A di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ a sì fọkàn tán ara wa.

Ó dùn mí gan-an nígbà tí Oľga, ìyàwó mi ọ̀wọ́n, kú lóṣù March ọdún 2003. Aya mi àtàtà tó ti dúró tì mí gbágbáágbá látìgbà tá a ti ṣègbéyàwó. Àwa méjèèjì ò kẹ̀rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù látọdún tá a ti jọ ń bá a bọ̀. Mò ń bá a nìṣó láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ wa báyìí, mi ò sì yé wá àwọn ẹni yíyẹ tó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì. Inú àhámọ́ tí mo wà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ni mo ti kọ́kọ́ gbọ́ tí wọ́n pe Jèhófà. Orúkọ yẹn sì ń bá a nìṣó láti jẹ́ ilé ìṣọ́ agbára fún mi.a—Òwe 18:10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Arákùnrin Pavol Kovár kú lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù July, ọdún 2007 nígbà tá à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́. Ọmọ ọdún márùnlélọ́gọ́rin [85] ni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Nígbà tí mo wà lára àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Slovakia lọ́dún 1942

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Nígbà tó yá wọ́n fi mí sẹ́wọ̀n ní Gusen (tí wọ́n fi tẹ́lẹ̀ àwòrán yìí)

[Credit Line]

© ČTK

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Bàbá mi máa ń ka Bíbélì fún wa láràárọ̀ ọjọ́ Sunday

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìgbà ìgbéyàwó wa lọ́dún 1946

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti Oľga kó tó kú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́