ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/08 ojú ìwé 18-20
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò?
  • Jí!—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ìdẹwò?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Bí O Ṣe Lè Borí Ìdẹwò
    Jí!—2014
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ Ìdẹwò?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Bíborí Àìpé Ẹ̀dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 10/08 ojú ìwé 18-20

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dènà Ìdẹwò?

◼ Kò tíì ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá lọ tí Karen débi àríyá kan tó fi rí àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n gbé àpò ńlá ńlá wọlé. Ohun tó wà nínú àwọn àpò yẹn ò ṣàjèjì rárá, torí ó ti gbọ́ táwọn ọmọkùnrin yẹn ń sọ pé “ọtí máa ṣàn bí omi” níbí lónìí. Karen ò sọ èyí mọ́rọ̀ fáwọn òbí ẹ, ìyẹn kì í sì í ṣe nǹkan tuntun. Lójú tiẹ̀, eré làwọn ọmọkùnrin yẹn ń ṣe. Ó ṣe tán, ó yẹ káwọn àgbàlagbà kan wà nílé tàbí nítòsí.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn tí Karen gbọ́ tẹ́nì kan tó mọ̀ sọ látẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Kí ló dé tó o wara ro síbẹ̀ yẹn, àbí sùẹ̀gbẹ̀ ni ẹ́ ni?” Nígbà tí Karen máa bojú wẹ̀yìn, Jessica ọ̀rẹ́ ẹ̀ ló rí pẹ̀lú ìgò ọtí méjì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí. Jessica na ọ̀kan sí Karen, ó wá ní, “Máà jẹ́ n gbọ́ pó o kéré láti jayé orí ẹ o!”

Karen ò fẹ́ mu ún. Àmọ́, wàhálà yìí ti pọ̀ ju ohun tó retí lọ. Ọ̀rọ̀ àtimu ọtí kọ́ ló ń ṣe é. Àmọ́, ọ̀rẹ́ lòun àti Jessica, kò sì fẹ́ dà bíi sùẹ̀gbẹ̀ lójú ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn ọmọ rere làwọn èèyàn mọ Jessica sí. Bí irú ẹ̀ bá wá ń mutí, a jẹ́ pé kò sí nǹkan tó burú níbẹ̀ nìyẹn. Karen wá bẹ̀rẹ̀ sí bára ẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní, ‘Ṣebí ìgò ọtí kan lásán ni. Kì í kúkú ṣe pé mo fẹ́ mugbó tàbí pé mo fẹ́ ní ìbálòpọ̀.’

NÍGBÀ tó o ṣì kéré, oríṣiríṣi ọ̀nà ni ìdẹwò máa ń gbà wá. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ló sábà máa ń jẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó ń jẹ́ Ramon sọ pé: “Wàhálà àwọn ọmọbìnrin tó wà níléèwé tí máa ń pọ̀ jù.a Wọ́n á máa mọ̀ọ́mọ̀ fọwọ́ kàn ẹ́, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá o ṣì máa gbà fún wọn. Tó o bá sọ pó ò ṣe, tiwọn kọ́ lò ń sọ yẹn!” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Deanna ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] náà nìyẹn, ó ní: “Ọmọkùnrin kan wá bá mi, ó sì fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn. Mo gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lọ́wọ́, mo wá ní, ‘Ṣé nǹkan rọ lù ẹ́ ni? Ọjọ́ wo lèmi àti ẹ mọra tó o fi ń fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn?’”

Ìwọ náà lè dojú kọ ìdẹwò, ó tiẹ̀ lè dà bíi pé wàhálà náà fẹ́ pọ̀ jù. Bí Kristẹni kan ṣe sọ, “ńṣe ni ìdẹwò dà bí ìgbà tẹ́nì kan ń gbá ilẹ̀kùn mọ́ ẹ lórí bó ò tiẹ̀ fẹ́ ṣílẹ̀kùn fún un.” Ṣé ohun kan wà tó máa ń dà ẹ́ láàmú bí ìgbà tẹ́nì kan ń gbá ilẹ̀kùn mọ́ ẹ lórí? Bí àpẹẹrẹ, ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi kó o lọ́wọ́ sí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tá a tò sísàlẹ̀ yìí?

□ Sìgá mímu

□ Otí mímu

□ Lílo oògùn olóró

□ Wíwo àwòrán oníhòòhò

□ Ṣíṣe ìṣekúṣe

□ Nǹkan míì ․․․․․

Tó o bá fàmì sí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tá a tò sókè yìí, má kàn sáré parí èrò sí pé o ò yẹ lẹ́ni tá a lè pè ní Kristẹni. O lè kọ́ bó o ṣe lè kápá ìfẹ́ ọkàn rẹ kó o sì dènà ìdẹwò. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Ó yẹ kó o mọ ohun tó fa ìdẹwò tó bá ẹ torí ìyẹn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú ẹ̀. Kà nípa àwọn nǹkan mẹ́ta tó lè fa ìdẹwò.

1. Àìpé ẹ̀dá. Gbogbo èèyàn aláìpé ló máa ń fẹ́ láti ṣe ohun tí kò tọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ pàápàá gbà láìjanpata pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” (Róòmù 7:21) Ó ti wá ṣe kedere pé ẹni tó ṣọmọlúwàbí jù lọ pàápàá máa ń rí i pé “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” máa ń nípa lórí òun lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (1 Jòhánù 2:16) Àmọ́ ríronú nípa ìdẹwò láti ṣe ohun tí kò tọ́ wulẹ̀ máa mú nǹkan burú sí i ni, torí Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.”—Jákọ́bù 1:15.

2. Àwọn nǹkan tó ń mọ́kàn èèyàn fà sí i. Kò síbi tí ìdẹwò ò sí. Trudy sọ pé: “Kò sígbà táwọn èèyàn kì í sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ níléèwé àti níbi iṣẹ́. Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí tí wọ́n fi ń ṣeré nínú fíìmù, ńṣe ni wọ́n máa ṣe é bíi pé kò sóhun tó dùn tó o. Wọn kì í sábà jẹ́ káwọn èèyàn rí ohun tó burú nípa ẹ̀!” Ìgbà tó yá ni Trudy náà kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí ara ẹ̀ pé àwọn nǹkan tó ń mọ́kàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe máa ń lágbára gan-an. Ó ní: “Mo rò pé mo ti yófẹ̀ẹ́ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16]. Mọ́mì pè mí jókòó, wọ́n sì sọ fún mi pé tí mi ò bá jáwọ́ nínú ìwàkiwà tí mò ń hù, mo máa lóyún gbẹ̀yìn ni. Ẹ̀rù bà mí gan-an pé mọ́mì mi lè sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ jáde lẹ́nu! Àmọ́, oṣù méjì péré lẹ́yìn yẹn ni mo gboyún.”

3. “Ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” (2 Tímótì 2:22) Gbólóhùn yìí lè túmọ̀ sí ohun tó sábà máa ń gba àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn, irú bíi kí wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn gba tiwọn tàbí kí wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú àgbàlagbà wò wọ́n. Àwọn ìfẹ́ ọkàn wọ̀nyẹn ò burú láyè ara wọn, àmọ́ téèyàn ò bá fi wọ́n sáyè wọn, wọ́n lè jẹ́ kó ṣòro láti dènà ìdẹwò. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ń fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú àgbàlagbà wò ẹ́, ìyẹn lè jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn ìlànà rere táwọn òbí ẹ fi tọ́ ẹ dàgbà sílẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Steve nìyẹn, ó ní: “Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni mo bẹ̀rẹ̀ sí kọtí ikún sáwọn òbí mi tí mo sì ń ṣe gbogbo ohun tó bá wù mí, kódà ohun tí wọ́n bá ní kí n má ṣe gan-an ni mo máa ń ṣe.”

Ká sòótọ́, àwọn nǹkan tá a sọ pó ń mọ́kan èèyàn fà sí nǹkan tí ò dáa máa ń lágbára gan-an. Àmọ́, o ṣì lè dènà ìdẹwò. Lọ́nà wo?

◼ Kọ́kọ́ mọ ìdẹwò tó máa ń ṣòro fún ẹ jù láti kojú. (O lè ti ṣèyẹn lókè.)

◼ Lẹ́yìn náà bi ara ẹ pé, ‘Ìgbà wo gan-an ni ìdẹwò yìí máa ń wáyé?’ Fàmì sí ọ̀kan lára àwọn ibi tá a tò sísàlẹ̀ yìí:

□ Níléèwé

□ Níbi iṣẹ́

□ Nígbà tí mo bá dá wà

□ Ibòmíì ․․․․․

Tó o bá ti mọ ìgbà tí ìdẹwò lè yọjú, wàá lè mọ ọgbọ́n tó o máa dá sí i. Bí àpẹẹrẹ, gbé àpèjúwe tá a fì bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí yẹ̀ wò. Kí ló jẹ́ kí Karen mọ̀ pé wàhálà máa wà níbi àríyá tó lọ? Kí ni kò bá ti ṣe láti dènà ìdẹwò yẹn?

◼ Ní báyìí tó o ti (1) mọ ohun tó sábà máa ń dẹ ẹ́ wò tó o sì ti (2) mọ̀gbà tó ṣeé ṣe kó wáyé, a jẹ́ pé o ti gbára dì láti dènà ẹ̀ nìyẹn. Ohun àkọ́kọ́ tó o máa fi ṣe àfojúsùn ẹ̀ ni pé kó o mọ bó o ṣe lè dín ohun tó ń fa ìdẹwò yẹn kù tàbí kó o máà jẹ́ kó wáyé rárá. Kọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe síbí.

․․․․․

․․․․․

(Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé nígbà tẹ́ ẹ bá jáde níléèwé lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọ iléèwé yín kan sábà máa ń wá fi sìgá mímu lọ̀ ẹ́, o lè máa gba ọ̀nà míì lọ sílé kó o má bàa máa pàdé wọn. Bó o bá sì sábà máa ń ráwọn nǹkan tó ń mọ́kàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láì béèrè fún un, á dáa kó o ṣètò kọ̀ǹpútà ẹ lọ́nà tí ò fi ni máa gba ìsọfúnni látorí irú ìkànnì bẹ́ẹ̀ àtàwọn míì tó bá ń dá irú ẹ̀ láṣà. Ó sì lè jẹ́ pé ìwọ fúnra ẹ lo máa ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tó o máa ń tẹ̀ sí kọ̀ǹpútà láti fi wá ìsọfúnni.)

Òótọ́ ni pé o ò lè dènà gbogbo ìdẹwò. Bó pẹ́ bó yá, ó lè jẹ́ pé ìdẹwò tó lágbára gan-an ló máa dojú kọ ẹ́ nígbà tó ò tiẹ̀ rò ó sí. Kí lo lè ṣe nípa ẹ̀?

Gbára dì. Nígbà tí Sátánì “ń dẹ [Jésù] wò,” kò rò ó lẹ́ẹ̀mejì kó tó kọ̀ jálẹ̀. (Máàkù 1:13) Kí nìdí? Torí ó mọ ìpinnu tó ti ṣe lórí àwọn nǹkan tí Èṣù fẹ́ fi dẹ ẹ́ wò. Ronú lórí ìyẹn. Jésù kì í ṣe rọ́bọ́ọ̀tì. Ì bá ti juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò. Àmọ́ ó ti pinnu lọ́kàn ara ẹ̀ pé tí Bàbá òun lòún á máa ṣe. (Jòhánù 8:28, 29) Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an ni Jésù sọ, ó ní: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 6:38.

Kọ ìdí méjì tó o fi gbọ́dọ̀ dènà ìdẹwò tó sábà máa ń kò ẹ́ lójú, kó o sì kọ ohun méjì tó o ti pinnu láti ṣe kó o lè dènà rẹ̀.

1. ․․․․․

2. ․․․․․

Rántí pé tó o bá gba ìdẹwò láyè, o ti di ẹrú fáwọn ìfẹ́ ọkàn ẹ nìyẹn. (Títù 3:3) Kí ló wá dé tí wàá fi gba ìfẹ́ ọkàn láyè láti máa darí rẹ? Yáa fi hàn pé o dàgbà nípa dídarí ìfẹ́ ọkàn ẹ, kó o má sì jẹ́ kí wọ́n máa darí ẹ.—Kólósè 3:5.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Ṣé àwọn ẹ̀dá pípé lè dojú kọ ìdẹwò?—Jẹ́nẹ́sísì 6:1-3; Jòhánù 8:44.

◼ Tó o bá dènà ìdẹwò, ipa wo ni ìgbàgbọ́ ẹ máa ní lórí àwọn ẹlòmíì? —Òwe 27:11; 1 Tímótì 4:12.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ

Mú kọ́ńpáàsì kan tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa sórí tábìlì, kó o wá fi irin tútù, ìyẹn mágínẹ́ẹ̀tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kí ló ṣẹlẹ̀? Kọ́ńpáàsì yẹn ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́.

Bíi kọ́ńpáàsì yẹn gan-an ni ẹ̀rí ọkàn ẹ ṣe rí. Tó o bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn ẹ dáadáa, á máa ṣiṣẹ́ dáadáa, wàá sì máa ṣàwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ bí mágínẹ́ẹ̀tì yẹn ò ṣe jẹ́ kí kọ́ńpáàsì ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹgbẹ́ búburú ṣe lè jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí ṣìwà hù, kó o sì máa ṣèpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti yẹra fáwọn ohun tó máa jẹ́ kó o fọwọ́ ara ẹ sọ àwọn ìwà rere tó o ní nù!—Òwe 13:20.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

ÀBÁ

Ní ohun tó o máa fi dá ẹni tó bá fẹ́ sún ẹ hùwà tí ò tọ́ lóhùn. Má janpata. Kò dìgbà tó o bá sọ ara ẹ di olódodo àṣelékè. Lọ́pọ̀ ìgbà gbogbo ohun tó o máa ṣe ò ju kó o sọ pé o ò ṣe lọ. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọléèwé ẹ bá fi sìgá mímu lọ̀ ẹ́, ìwọ ṣáà sọ fún un pé: “Má fi sìgá ẹ ṣòfò. Mi ò ní mu ún!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Tó o bá juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò, ńṣe lo máa sọ ara ẹ di ẹrú fún ìfẹ́ ọkàn ẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́