Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Wàhálà Níléèwé?
“Bó o tiẹ̀ dàgbà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ìyẹn ò ní kí wàhálà tó ń dojú kọ ẹ́ níléèwé dín kù, ohun tó ń fà á ló kàn máa yí pa dà.”—James, láti orílẹ̀-èdè New Zealand.a
“Wàhálà tó máa ń bá mi níléèwé máa ń pọ̀ débi pé ó máa ń ṣe mi bíi kí n máa sunkún kí n sì tún máa pariwo.”—Sharon, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
ṢÓ MÁA ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí ẹ ò mọ irú wàhálà tó o máa ń dojú kọ níléèwé? Wọ́n lè máa sọ fún ẹ pé o ò jẹ báńkì lówó, o ò tọ́mọ, o ò sì ní agbaniṣíṣẹ́ tó ń fẹ́ kó o ṣe tibí ṣe tọ̀hún. Lójú tìẹ sì rèé, o lè máa wò ó pé bí wàhálà ṣe ń bá àwọn òbí ẹ náà ló ń bá ìwọ náà níléèwé, o tiẹ̀ lè máa rò pé wàhálà tó bá ẹ ju tiwọn lọ pàápàá.
Lílọ síléèwé àti pípadà sílé tó wàhálà lọ́tọ̀. Tara tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àwọn ọmọ iléèwé wa sábà máa ń jà nínú mọ́tò tó máa ń gbé wa lọ síléèwé. Ẹni tó ń wakọ̀ á dúró, á lé gbogbo wa bọ́ sílẹ̀, ibẹ̀ la sì máa wà fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kó tó tún ní ká wọlé ká lè máa lọ.”
Ṣé tó o bá ti déléèwé, wàhálà tán nìyẹn? Kò dájú! Ka àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí, bóyá bó ṣe ń ṣèwọ náà nìyẹn.
◼ Wàhálà àwọn tíṣà.
“Àwọn tíṣà mi máa ń fẹ́ kí n mókè nínú àwọn iṣẹ́ kan, kí n sì kó wọn jẹ̀ ní kíláàsì mi, àmọ́ wàhálà tí mo máa ṣe kí n lè múnú wọn dùn ò kéré rárá.”—Sandra, láti erékùṣù Fíjì.
“Àwọn tíṣà máa ń fúngun mọ́ àwọn ọmọ iléèwé láti gba máàkì tó pọ̀ gan-an nínú àwọn iṣẹ́ kan, àgàgà táwọn ọmọ yẹn bá láwọn ẹ̀bùn kan. Wàhálà àwọn tíṣà yẹn ti pọ̀ jù torí ká ṣáà lè mókè níléèwé.”—April, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
“Bó o tiẹ̀ láwọn ohun tó o fẹ́ fayé ẹ ṣe, ńṣe làwọn tíṣà kan á máa wò ẹ́ bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan torí pé o ò fẹ́ ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ kó o ṣe tó bá dọ̀ràn ẹ̀kọ́ iléèwé.”—Naomi, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Báwo ni wàhálà àwọn tíṣà ṣe máa ń nípa lórí ẹ?
․․․․․
◼ Wàhálà àwọn ọmọ iléèwé.
“Níléèwé girama, àyè túbọ̀ máa ń gba àwọn ọmọ iléèwé, torí náà wọ́n sábà máa ń yàyàkuyà. Tó ò bá sì máa ṣe bíi tiwọn, wọ́n á rò pé ọ̀dẹ̀ ni ẹ́.”—Kevin, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
“Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń fi ọtí àti ìbálòpọ̀ lọ̀ mí. Nígbà míì, kì í rọrùn láti sọ pé mi ò ṣe.”—Aaron, láti orílẹ̀-èdè New Zealand.
“Nígbà tí mo ti wá pé ọmọ ọdún méjìlá [12] báyìí, wàhálà tó dé bá mi ni àdánwò láti lẹ́ni tí mò ń fẹ́. Gbogbo àwọn ọmọ iléèwé ló máa ń sọ pé, ‘Ìgbà wo nìwọ tiẹ̀ máa wá ẹnì kan fẹ́ ńtìẹ?’”—Alexandria, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
“Wọ́n fẹ́ fipá mú mi láti máa fẹ́ bọ̀bọ́ kan. Nígbà tí mo ní mi ò ṣe, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé obìnrin bíi tèmi ni mò ń bá lò pọ̀. Mi ò dẹ̀ tíì ju ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ nígbà yẹn o!”—Christa, láti ilẹ̀ Ọsirélíà.
Báwo ni wàhálà àwọn ọmọ iléèwé ṣe ń nípa lórí ẹ?
․․․․․
◼ Wàhálà nípa ohun táwọn ọmọ kíláàsì ẹ máa ṣe tí wọ́n bá mọ ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìsìn.
“Kò rọrùn láti sọ fáwọn ọmọ kíláàsì ẹ pé ohun báyìí lẹ gbà gbọ́ nínú ìjọ yín, torí o ò mọ ohun tí wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í pè ẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá mọ̀ tán. Wàá máa ronú pé wọ́n lè máa rò pé o ò dákan mọ̀.”—Carol, láti erékùṣù Hawaii.
“Níléèwé girama, àwọn ọmọ iléèwé máa ń lo oògùn olóró, wọ́n máa ń bára wọn sùn, wọ́n sì máa ń mutí. Wàhálà gbáà ni, torí o ò fẹ́ káwọn ọmọ kan máa wá fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ò ń fàwọn ìlànà Bíbélì sílò tó ò sì fara wé wọn.”—Susan, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Báwo làwọn wàhálà tó jẹ mọ́ ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìsìn ṣe máa ń nípa lórí ẹ?
․․․․․
◼ Àwọn wàhálà míì. Fàmì séyìí tó máa ń nípa lórí ẹ jù tàbí kó o kọ ọ́ sísàlẹ̀ tí kò bá sí lára èyí tá a kọ.
□ Àwọn wàhálà tó o fura pó ń bọ̀
□ Iṣẹ́ àṣetiléwá
□ Ohun táwọn òbí ẹ fẹ́ kó o ṣe ju agbára ẹ lọ
□ Bọ́wọ́ ẹ ṣe fẹ́ tẹ́ ohun ńlá tó ò ń lé
□ Àwọn tó ń fòòró ẹ àtàwọn tó ń fìṣekúṣe lọ̀ ẹ́
□ Àwọn nǹkan míì ․․․․․
Ohun Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Láti Dín Wàhálà Kù
Ká sòótọ́, kò sí bó o ṣe lè ṣe é tí wàá parí iléèwé láì dojú kọ wàhálà kan tàbí òmíràn. Òótọ́ sì ni pé tí wàhálà bá pọ̀ jù, ó lè ni èèyàn lára. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníwàásù 7:7) Àmọ́, kò yẹ kó o wá jẹ́ kí wàhálà tó dé bá ẹ sọ ẹ́ dìdàkudà. Ìwọ ṣáà kọ́ àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tó o lè gbà fara dà á.
Fífara da wàhálà dà bí ìgbà téèyàn bá ń gbé irin tó wúwo. Ẹni tó bá fẹ́ gbé irin tó wúwo gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ dáadáa. Ó ní láti gbé e bó ṣe yẹ, kó má bàa mọ̀ ọ́n lára ju bó ṣe yẹ lọ. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, iṣan ara ẹ̀ á máa le tantan láì ba ara ẹ̀ jẹ́. Àmọ́, tí ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè fa iṣan ara ẹ̀ ya, ó sì lè fọ́ ara ẹ̀ légungun.
Ìwọ náà lè fara da wàhálà tó o dojú kọ, kó o sì ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe láì bayé ara ẹ jẹ́. Lọ́nà wo? Ṣe àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí:
1. Mọ ohun tó fa wàhálà yẹn. Òwe ọlọ́gbọ́n kan sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Ṣùgbọ́n o ò lè para ẹ mọ́ lọ́wọ́ àwọn wàhálà tó ń nini lára tó ò bá kọ́kọ́ mọ ohun tó lè fa wàhálà ọ̀hún. Torí náà pa dà lọ wo ohun tó o kọ ṣáájú. Wàhálà wo ló máa ń nípa lórí ẹ jù lọ?
2. Wádìí ọ̀ràn náà wò. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé wàhálà iṣẹ́ àṣetiléwá tó pọ̀ jù ló bá ẹ, o lè ka àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ráyè Ṣe Iṣẹ́ Àṣetiléwá Mi?” tó wà nínú Jí! February 8, 2004. Tó bá sì jẹ́ pé ìfẹ́ láti ṣèṣekúṣe pẹ̀lú ọmọ kíláàsì ẹ kan ni wàhálà tó bá ẹ, ìmọ̀ràn tó wà nínú àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Bí Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Kan Bá Ní Kí N Jẹ́ Ká Jọ Gbéra Wa Sùn Ńkọ́?” tó wà nínú Jí! April–June 2007 máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an.
3. Ronú nípa bí wàá ṣe dáhùn. Bí nǹkan bá tojú sú ẹ torí pé o ò mọ báwọn ọmọ kíláàsì ẹ ṣe máa ṣe tí wọ́n bá gbọ́ nípa àwọn ohun tó o gbà gbọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, máà dúró dìgbà tẹ́nì kan bá ju ìbéèrè lù ẹ́ kó o tó ronú lórí ohun tó o máa sọ àtohun tó o máa ṣe. (Òwe 29:25) Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Kelsey sọ pé: “Ohun tó jẹ́ kí n lè fara dà á ni pé mo ti máa ń ronú lórí ohun tí mo máa ṣe bíṣòro bá dé. Mo ti máa ń pinnu bí mo ṣe máa ṣàlàyé àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ fún wọn.” Ohun tọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Aaron láti orílẹ̀-èdè Belgium ṣe náà nìyẹn, ó ní: “Mo ti máa ń ronú lórí àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè bi mí, mo sì máa ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè náà. Tó bá jẹ́ pé mi ò ṣe bẹ́ẹ̀ ni, mi ò jẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ fún wọn.”
4. Má fòní dónìí, fọ̀la dọ́la. Ṣàṣà làwọn ìṣòro tó máa wábi gbà tó o bá ṣe bíi pé o ò rí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n máa ń burú sí i, tí wàhálà á sì máa gorí wàhálà. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, jíjẹ́ káwọn ọmọléèwé ẹ tètè mọ̀ máa dáàbò bò ẹ́ gan-an. Marchet tó ti wá di ọmọ ogún [20] ọdún báyìí sọ pé: “Gbàrà tá a bá ti wọlé sáà ẹ̀kọ́ tuntun níléèwé ni mo ti máa ń dá àwọn ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ tí mo mọ̀ pó máa fún mi láǹfààní láti ṣàlàyé àwọn ìlànà Bíbélì tí mo gbà gbọ́. Mo wá rí i pé bí mo ṣe ń pẹ́ tó láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni mí ló ṣe ń nira fún mi tó láti fara dà á. Àmọ́, jíjẹ́ káwọn ọmọ kíláàsì mi mọ ohun tí mo gbà gbọ́ àti fífi wọ́n ṣèwà hù jálẹ̀ ọdún yẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni.”
5. Wá ìrànlọ́wọ́. Kódà ẹni tó lágbára jù lọ láti gbé irin tó wúwo níbi tó kù sí. Ìwọ náà sì níbi tó o kù sí. Àmọ́, kò yẹ kó o dá ìṣòro ẹ wà mọ́rùn. (Gálátíà 6:2) O ò ṣe sọ ọ́ fáwọn òbí ẹ tàbí àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn? Fi àwọn ìdáhùn tó o kọ sókè hàn wọ́n. Bá wọn sọ̀rọ̀ lórí ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àwọn wàhálà tó ò ń dojú kọ. Liz, láti orílẹ̀-èdè Ireland sọ fún dádì ẹ̀ pé ẹ̀rù ń ba òun pé àwọn ọmọléèwé òun máa fòun ṣe yẹ̀yẹ́ tóun bá sọ ohun tóun gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run fún wọn. Liz sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni dádì mi máa ń gbàdúrà pẹ̀lú mi kí wọ́n tó gbé mi lọ síléèwé. Ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ ní gbogbo ìgbà.”
Wàhálà Tó Dáa Kẹ̀?
Ó lè má rọrùn fún ẹ láti gbà gbọ́, àmọ́ ó dáa tó o mọ̀ pé wàhálà wà. Ìdí tó sì fi dáa ni pé ìyẹn ń fi ẹ́ hàn bí ọlọgbọ́n àti ẹni tí ẹ̀rí ọkàn ẹ ṣì ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Ìwọ náà wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí ò mọ̀ pé wàhálà wà, ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ, tí ìwọ yóò fi wà ní ìdùbúlẹ̀? Ìgbà wo ni ìwọ yóò dìde kúrò lójú oorun rẹ? Oorun díẹ̀ sí i, ìtòògbé díẹ̀ sí i, kíká ọwọ́ pọ̀ díẹ̀ sí i ní ìdùbúlẹ̀, ipò òṣì rẹ yóò sì dé dájúdájú gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri kan, àti àìní rẹ bí ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra.”—Òwe 6:9-11.
Bí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Heidi ṣe parí ọ̀rọ̀ ọ̀hún rèé, ó ní: “Iléèwé lè dà bí ibi tí wàhálà pọ̀ sí, àmọ́ wàhálà kan náà lo máa dojú kọ tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́.” Ká sòótọ́, kò rọrùn láti fara da wàhálà, àmọ́ téèyàn ò bá wa wàhálà máyà, wàhálà kì í pààyàn. Kódà, ńṣe ló máa ń sọni dalágbára.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí ló máa ń fi hàn pé wàhálà wà?
◼ Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ńṣe ni fífẹ́ láti ṣe ohun gbogbo láìsí àṣìṣe máa ń pa kún wàhálà?
◼ Ta lo lè sọ fún tó bá dà bíi pé wàhálà ti mu ẹ́ lómi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Fífara da wàhálà dà bí ìgbà téèyàn ń gbé irin tó wúwo, béèyàn bá gbé e bó ṣe yẹ, ńṣe ló máa ń sọni dalágbára