KÍ LÈRÒ RẸ?
- Tí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́, kí nìdí tó fi jẹ́ kí ìwà ibi àti ìyà máa bá a lọ? 
- Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé là ń gbé yìí? 
- Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run máa ṣẹ? 
- Ṣé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu lóde òní? 
Torí pé Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa, ó pèsè ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì. Lọ sí ìkànnì wa, www.pr2711.com/yo, tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o ba lè rí àwọn ìdáhùn náà.
Tó o bá lọ sórí ìkànnì wa, wàá rí eré ìkẹ́kọ̀ọ́, àwọn àpilẹ̀kọ, ohùn tá a gbà sílẹ̀ àti fídíò, àwọn ìfòrọ̀wánilẹ́nuwò, àti ọ̀pọ̀ àwọn ìwé lóríṣiríṣi, títí kan Bíbélì. Ọ̀fẹ́ sì ni gbogbo wọn.