ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • T-13 ojú ìwé 2-6
  • Ìdí Tóo Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tóo Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì
  • Ìdí Tóo Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Tako Ara Rẹ̀?
  • Ìtàn àti Sáyẹ́ǹsì
  • Sísọtẹ́lẹ̀ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la
  • Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
  • Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ìdí Tóo Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì
T-13 ojú ìwé 2-6

Ìdí Tóo Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Bíbélì

Àwọn kan sọ pé Bíbélì ò ṣeé gbára lé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti gbà pẹ̀lú èrò àwọn èèyàn yìí. Ìyẹn lọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní fi ń fọwọ́ rọ́ ohun tí Bíbélì sọ tì, pé kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.

Àmọ́ o, ohun tí Jésù Kristi sọ nígbà tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run fúnni níṣìírí láti gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” Bíbélì fúnra rẹ̀ sì fi hàn pé Ọlọ́run ló mí sí òun.—Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16.

Kí lèrò tìrẹ nípa èyí? Ǹjẹ́ ìdí tó yè kooro wà láti gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì? Àbí ẹ̀rí wà lóòótọ́ pé Bíbélì ò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, pé ó tako ara rẹ̀, pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò sì ṣọ̀kan délẹ̀?

Ǹjẹ́ Bíbélì Tako Ara Rẹ̀?

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń sọ pé Bíbélì tako ara rẹ̀, ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì fi àpẹẹrẹ gidi kan hàn ọ́? A kò tíì rí ẹyọ kan ṣoṣo tó tíì fìdí múlẹ̀ lẹ́yìn àyẹ̀wò fínnífínní. Lóòótọ́, àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì kan lè dà bí èyí tí kò bára mu. Ṣùgbọ́n, àìmọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn àti àìmọ bí nǹkan ṣe rí lásìkò ìgbà yẹn ló sábà máa ń jẹ́ kó jọ bẹ́ẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń tọ́ka sí ohun tí wọ́n kà sí àìbáramu nínú Bíbélì, wọ́n á béèrè pé: ‘Ibo ni Kéènì ti rí aya tó fẹ́?’ Èrò wọn ni pé Kéènì àti Ébẹ́lì nìkan lọmọ tí Ádámù àti Éfà bí. Àmọ́, ṣíṣì tí wọ́n ṣi ọ̀rọ̀ Bíbélì lóye ló fà á. Bíbélì ṣàlàyé pé Ádámù “bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:4) Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀kan lára àwọn àbúrò rẹ̀ tàbí ọmọ àbúrò rẹ̀ ni Kéènì fẹ́.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe làwọn olùṣelámèyítọ́ máa ń tanná wá ìtakora kiri, nítorí náà, wọ́n lè ṣàdédé sọ pé: ‘Mátíù, òǹkọ̀wé Bíbélì, sọ pé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan wá bẹ Jésù fún nǹkan kan, ṣùgbọ́n Lúùkù sọ pé ońṣẹ́ ló rán lọ bá Jésù. Èwo ló wá tọ̀nà?’ (Mátíù 8:5, 6; Lúùkù 7:2, 3) Ní tòdodo, ṣé ibí yìí takora?

Bí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan ló ṣe kinní kan tàbí iṣẹ́ kan, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ní ti gidi, ṣe lẹni náà pàṣẹ fún àwọn èèyàn kan láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, olóye ènìyàn kì í ka ìyẹn sí ìtakora. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá sọ nínú ìròyìn pé olórí ìlú kan la ọ̀nà sí ibì kan, nígbà tó ṣe pé àwọn ẹnjiníà àti lébìrà ló ṣe iṣẹ́ yẹn ní ti gidi, ṣé wàá sọ pé oníròyìn yẹn ṣàṣìṣe? Rárá o! Bákan náà, kò sí ìtakora nínú bí Mátíù ṣe sọ pé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun wá bẹ Jésù fún nǹkan kan, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí Lúùkù ṣe kọ ọ́, àwọn aṣojú kan ló rán wá láti sọ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún Jésù.

Béèyàn bá ṣe túbọ̀ ń mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ inú Bíbélì sí i tó ni àwọn àìbáramu tó dà bíi pé ó wà nínú rẹ̀ yóò máa pòórá.

Ìtàn àti Sáyẹ́ǹsì

Nígbà kan rí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ń ṣiyè méjì ní ti bóyá àwọn ìtàn inú Bíbélì ṣẹlẹ̀ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùṣelámèyítọ́ jiyàn pé bóyá làwọn èèyàn kan tí Bíbélì mẹ́nu kàn fi wà rí, àwọn bíi Ságónì ọba Ásíríà, Bẹliṣásárì ọba Bábílónì, àti Pọ́ńtíù Pílátù, ará Róòmù náà, tó jẹ́ gómìnà. Àmọ́, léraléra ni àwọn àwárí ẹnu àìpẹ́ yìí ń jẹ́rìí ti àkọsílẹ̀ Bíbélì ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ìyẹn ni Moshe Pearlman tó jẹ́ òpìtàn fi sọ pé: “Lójijì ni àwọn oníyèmejì tó ti ń ṣiyè méjì ní ti bóyá Májẹ̀mú Láéláé jóòótọ́, títí kan àwọn apá kan nínú ìtàn inú rẹ̀ pàápàá, wá bẹ̀rẹ̀ sí yí èrò wọn padà.”

Bí a óò bá gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó jẹ́ ti sáyẹ́ǹsì ní láti jẹ́ èyí tó péye pẹ̀lú. Ṣé bẹ́ẹ̀ ló rí? Kò tíì pẹ́ púpọ̀ sẹ́yìn táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń sọ pé àgbáálá ayé kò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ rárá, wọ́n ń fi èyí tako Bíbélì ni o. Àmọ́, Robert Jastrow, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà, tọ́ka sí ìsọfúnni tuntun kan tó já wọn nírọ́, ó ṣàlàyé pé: “Wàyí o, a wá rí i bí ẹ̀rí látinú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà ṣe ń fàbọ̀ sórí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Òótọ́ ni pé kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé wọn yàtọ̀ síra o, ṣùgbọ́n kókó kan náà ni ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà àti àlàyé tí Bíbélì ṣe nínú Jẹ́nẹ́sísì jọ ń sọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

Àwọn èèyàn tún yí èrò wọn padà nípa ìrísí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Àwọn ìrìn àjò ìṣàwárí táwọn èèyàn rìn lójú òkun fi hàn pé róbótó layé rí, kò tẹ́ pẹrẹsẹ bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ṣe gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀.” Bẹ́ẹ̀, àtayébáyé mà ni Bíbélì ti sòótọ́ ọ̀rọ̀ yìí o! Lóhun tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ṣáájú àwọn ìrìn àjò ojú òkun wọ̀nyẹn, Bíbélì sọ nínú Aísáyà orí ogójì, ẹsẹ kejìlélógún pé: “Ẹnì kan wà tí ń gbé orí òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé,” tàbí gẹ́gẹ́ bí àwọn ìtumọ̀ mìíràn ṣe sọ, “òbìrí ilẹ̀ ayé” (Douay), “ayé róbótó.” (Moffatt)

Nípa báyìí, bí àwọn èèyàn bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, ni wọ́n ṣe ń rí ẹ̀rí púpọ̀ sí i pé Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Alàgbà Frederic Kenyon, tó fìgbà kan rí jẹ́ olùdarí Ibi Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé Sí ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kọ̀wé pé: “Àwọn àbájáde tó ti tẹ̀ wá lọ́wọ́ ń ṣètìlẹyìn fún èrò tí ìgbàgbọ́ máa ń jẹ́ kí èèyàn ní, ìyẹn ni pé, bí ìmọ̀ ṣe ń pọ̀ sí i yìí gan-an ni yóò tún máa ṣe Bíbélì láǹfààní.”

Sísọtẹ́lẹ̀ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la

Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ a tiẹ̀ lè gbẹ́kẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, títí kan ‘ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun òdodo’ tó sọ pé ó ń bọ̀? (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Ó dára, kí ni àkọsílẹ̀ àtẹ̀yìnwá fi hàn ní ti bóyá Bíbélì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé? Léraléra ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ti ṣẹ bó ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́, láìyingin, àtàwọn tó tiẹ̀ sọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú pàápàá!

Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Bábílónì alágbára ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú kó tó ṣẹlẹ̀. Àní ó tiẹ̀ dárúkọ àwọn ará Mídíà, tí wọ́n wá pawọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Páṣíà, pé àwọn ló máa ṣẹ́gun rẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tiẹ̀ tíì bí Kírúsì ọba Páṣíà nígbà yẹn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò kó ipa pàtàkì nínú ìṣẹ́gun yẹn. Ó ní omi tó dáàbò bo Bábílónì, ìyẹn odò Yúfírétì, yóò ‘gbẹ táútáú,’ àti pé “àwọn ẹnubodè [Bábílónì] pàápàá ni a kì yóò tì.”—Jeremáyà 50:38; Aísáyà 13:17-19; 44:27–45:1.

Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ pàtó wọ̀nyí sì ṣẹ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn náà, Hẹrodótù, ṣe sọ. Síwájú sí i, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Bábílónì yóò di òkìtì àlàpà tí kò ní olùgbé. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Lónìí, èkìdá òkìtì àlàpà tó dá páropáro ni Bábílónì jẹ́. (Aísáyà 13:20-22; Jeremáyà 51:37, 41-43) Bíbélì sì kún fún àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tó ti ṣẹ lọ́nà tó kàmàmà.

Kí ni Bíbélì wá sọ tẹ́lẹ̀ nípa ètò àwọn nǹkan inú ayé ìsinsìnyí? Ó sọ pé: “Sànmánì ìkẹyìn ayé yìí yóò jẹ́ àkókò ìjàngbọ̀n. Ara wọn nìkan àti owó ni àwọn èèyàn yóò fẹ́ràn; wọn yóò jẹ́ awúfùkẹ̀, afúnnu, àti ẹlẹ́ẹ̀kẹ́-èébú; láìní ọ̀wọ̀ fún òbí, láìmoore, láìní ìwà funfun, láìní ìfẹ́ni lọ́nà ti ẹ̀dá . . . Wọn yóò jẹ́ ẹni tó fi fàájì rọ́pò Ọlọ́run, àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn ojú lásán, ṣùgbọ́n tí àwọn fúnra wọn ń fi hàn pé ẹ̀sìn ò jámọ́ nǹkan kan.”—2 Tímótì 3:1-5, The New English Bible.

Dájúdájú, à ń rí i pé èyí ń ṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí! Ṣùgbọ́n Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà “sànmánì ìkẹyìn ayé yìí,” àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò máa ṣẹlẹ̀: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ . . . yóò sì wà.” Ẹ̀wẹ̀, “ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn . . . láti ibì kan dé ibòmíràn.”—Mátíù 24:7; Lúùkù 21:11.

Ní tòótọ́, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mà ń ṣẹ lóde òní o! Ó dára, àwọn tí kò tíì wá ṣẹ ńkọ́, irú èyí tó sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀,” àti, “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀ . . . , bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́”?—Sáàmù 37:29; Aísáyà 2:4.

Àwọn kan lè sọ pé: ‘Ìyẹn ti dára ju ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.’ Àmọ́, ká sòótọ́, kò sí ìdí tó fi yẹ ká ṣiyè méjì nípa ohunkóhun tí Ẹlẹ́dàá wa bá ṣèlérí. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé! (Títù 1:2) Bóo bá ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí síwájú sí i, ìdánilójú tóo máa ní nípa rẹ̀ yóò túbọ̀ pọ̀ sí i.

Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí a fà yọ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Àwọn àbájáde tó ti tẹ̀ wá lọ́wọ́ ń ṣètìlẹyìn fún èrò tí ìgbàgbọ́ máa ń jẹ́ kí èèyàn ní, ìyẹn ni pé, bí ìmọ̀ ṣe ń pọ̀ sí i yìí gan-an ni yóò tún máa ṣe Bíbélì láǹfààní”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́