ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ie ojú ìwé 30-31
  • Ìrètí Àrà Ọ̀tọ̀ Kan!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrètí Àrà Ọ̀tọ̀ Kan!
  • Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwọ Náà Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • A Pa Wọn Mọ́ Láàyè La Ìpọ́njú Ńlá Já
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ayé Tuntun Ọlọ́run, Ayé Àlàáfíà—Ìwọ Lè Wà Níbẹ̀
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Níwájú Ìtẹ́ Jèhófà
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
Àwọn Míì
Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
ie ojú ìwé 30-31

Ìrètí Àrà Ọ̀tọ̀ Kan!

“Olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.”—JÒHÁNÙ 11:26.

1. Irú àyíká wo ni a óò jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ó ti kú báyìí dìde sí?

NÍGBÀ tí a bá jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn dìde nígbà àjíǹde, ayé tí ó ṣófo kọ́ ni a máa mú wọn padà wá gbé. (Ìṣe 24:15) Wọn yóò jí sí àyíká ẹlẹ́wà tí a ti mú sunwọ̀n sí i, wọn yóò sì rí i pé a ti pèsè ibùgbé, aṣọ àti ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ dè wọ́n. Ta ni yóò ṣe gbogbo ìwọ̀nyí sílẹ̀? Dájúdájú, àwọn ènìyàn yóò ti máa gbé nínú ayé tuntun kí àjíǹde ti ilẹ̀ ayé tó bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn wo?

2-4. Ìrètí àrà ọ̀tọ̀ wo ní ń dúró de àwọn tí ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?

2 Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí.a (2 Tímótì 3:1) Láìpẹ́ sí ìsinsìnyí, Jèhófà Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn aráyé, yóò sì mú ìwà ibi kúrò ní ayé. (Sáàmù 37:10, 11; Òwe 2:21, 22) Ní ìgbà yẹn, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run?

3 Jèhófà kò ní pa olódodo run pọ̀ mọ́ ẹni burúkú. (Sáàmù 145:20) Kò ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ṣeé nígbà tí ó bá fọ ìwà ibi kúrò nínú ayé. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 18:22, 23, 26.) Ní tòótọ́, ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì sọ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” tí ó jáde wá láti inú “ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣípayá 7:9-14) Bẹ́ẹ̀ ni, ògìdìgbó ńláǹlà yóò la ìpọ́njú ńlá, nínú èyí tí ayé burúkú ìsinsìnyí yóò ti dópin, já, wọn yóò sì wọnú ayé tuntun Ọlọ́run. Ní ibẹ̀, aráyé onígbọràn yóò lè jàǹfààní ní kíkún nínú ìpèsè àgbàyanu Ọlọ́run tí yóò tú aráyé sílẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Ìṣípayá 22:1, 2) Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe dandan pé kí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” kú. Ẹ wo irú ìrètí àrà ọ̀tọ̀ tí èyí jẹ́!

4 A ha lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìrètí àgbàyanu yìí bí? Dájúdájú! Jésù Kristi fúnra rẹ̀ fi hàn pé ìgbà kan yóò wà tí àwọn ènìyàn yóò máa wà láàyè láìní kú láé. Kété kí Jésù tó jí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde, ó sọ fún Màtá pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.”—Jòhánù 11:26.

Ìwọ Náà Lè Wà Láàyè Títí Láé

5, 6. Bí o bá fẹ́ gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé, kí ni ó ní láti ṣe?

5 O ha fẹ́ láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé bí? O ha ń yán hànhàn láti tún padà rí àwọn olólùfẹ́ rẹ bí? Nígbà náà, o ní láti gba ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ sínú. Nínú àdúrà sí Ọlọ́run, Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.

6 Ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Àkókò gan-an nìyí fún ọ láti kọ́ nípa bí ìwọ, àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn tí ó ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ṣe lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run àti àwọn ohun tí ó ń béèrè. O kò ṣe kàn sí wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó bá wà nítòsí rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ nínú èyí tí a kọ sí ojú ìwé tí ó tẹ̀ lé e?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ìmọ̀ Tí Ń Sini Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ojú ìwé 98 sí 107, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kì í ṣe dandan pé kí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” kú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́