Orin 137
Fún Wa Ní Ìgboyà
(Ìṣe 4:29)
- Báa ṣe ń sọ̀rọ̀ Ìjọba náà, - Táà ń jẹ́rìí orúkọ rẹ, - Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ta kò wá - Wọ́n fẹ́ kótìjú bá wa. - Dípò ká bẹ̀rù èèyàn, - Ìwọ la máa ṣègbọràn sí. - Torí náà fún wa ní ẹ̀mí rẹ; - Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. - (ÈGBÈ) - Fún wa nígboyà ká wàásù; - Mú ìbẹ̀rù wa kúrò. - Fún wa nígbàgbọ́, ìgboyà - Káráyé lè gbọ́ wàásù. - Amágẹ́dọ́nì ti dé tán, - Títí ọjọ́ ńlá náà yóò dé, - Fún wa nígboyà ká wàásù. - Làdúrà wa. 
- Bí ẹ̀rù tilẹ̀ ń bà wá, - O rántí péèpẹ̀ ni wá. - O sọ pé wàá tì wá lẹ́yìn - ‘Lérí rẹ la gbẹ́kẹ̀ lé. - Fiyè síhàlẹ̀ àwọn - Tó ń ṣenúnibíni sí wa. - Ràn wá lọ́wọ́ Baba ká lè máa fi - Ìgboyà sọ̀rọ̀ lóókọ rẹ. - (ÈGBÈ) - Fún wa nígboyà ká wàásù; - Mú ìbẹ̀rù wa kúrò. - Fún wa nígbàgbọ́, ìgboyà - Káráyé lè gbọ́ wàásù. - Amágẹ́dọ́nì ti dé tán, - Títí ọjọ́ ńlá náà yóò dé, - Fún wa nígboyà ká wàásù. - Làdúrà wa. 
(Tún wo 1 Tẹs. 2:2; Héb. 10:35.)