Orin151
Ọlọ́run Máa Ṣí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Payá
Bíi Ti Orí Ìwé
	- Jáà ti yan àwọn ọmọ rẹ̀ - Ó máa ṣí wọn payá. - Wọ́n máa jọba pẹ̀lú Kristi - Ẹ̀dá ẹ̀mí ni wọ́n. - (ÈGBÈ) - Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá - Kristi l’Olúwa wọn. - Wọ́n máa ṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi - Wọ́n máa jọ gba èrè. 
- Láìpẹ́ àwọn ìyókù wọn - Máa gbọ́ ohùn ìpè. - Jésù Ọba àwọn ọba - Máa kó gbogbo wọn jọ. - (Ègbè) - Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá - Kristi l’Olúwa wọn. - Wọ́n máa ṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi - Wọ́n máa jọ gba èrè. - (ÌSOPỌ̀) - Kristi àti àwọn ‘mọ Jáà - Máa jagun ìkẹyìn. - ’Gbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn - Máa wà pẹ́ títí láé. - (Ègbè) - Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá - Kristi l’Olúwa wọn. - Wọ́n máa ṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi - Wọ́n máa jọ gba èrè.