ORIN 11
Ìṣẹ̀dá Ń Yin Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Sáàmù 19)
- 1. Àwọn ìṣẹ̀dá ń yìn ọ́, Jèhófà, - Wọ́n pọ̀ púpọ̀ lójú sánmà lókè. - Wọ́n ń ròyìn ògo àtagbára rẹ - Fún aráyé láìsọ ọ̀rọ̀ kankan. - Wọ́n ń ròyìn ògo àtagbára rẹ - Fún aráyé láìsọ ọ̀rọ̀ kankan. 
- 2. Àwọn àṣẹ rẹ ńsọni d’ọlọ́gbọ́n, - Wọ́n ń dáàbò bò wá ní gbogbo ọ̀nà. - Wọ́n ń ṣe tọmọdé tàgbà láǹfààní; - Wọ́n wúlò ju wúrà iyebíye. - Wọ́n ń ṣe tọmọdé tàgbà láǹfààní; - Wọ́n wúlò ju wúrà iyebíye. 
- 3. Asán kọ́ layé àwa tá a mọ̀ ọ́, - Ọ̀rọ̀ rẹ ń mú káyé wa nítumọ̀. - Ọlá ńlá lo dá àwọn tó mọ̀ ọ́, - Àwọn tó ń sorúkọ rẹ di mímọ́. - Ọlá ńlá lo dá àwọn tó mọ̀ọ́, - Àwọn tó ń sorúkọ rẹ di mímọ́. 
(Tún wo Sm. 12:6; 89:7; 144:3; Róòmù 1:20.)