ORIN 14
Ẹ Yin Ọba Tuntun Tó Jẹ Lórí Ayé
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jésù Kristi àti àwọn - ẹni àmì òróró - Ń kó ọ̀pọ̀ èèyàn jọ láti - inú gbogbo ‘rílẹ̀-èdè. - Ìjọba náà ti wà lọ́run, - yóò mú ìfẹ́ Jáà ṣẹ láyé. - Ìrètí yìí mà ṣeyebíye! - Ó ń tù wá nínú, à ń láyọ̀. - (ÈGBÈ) - Ẹ yin Ọlọ́run wa; Ẹ yin Jésù Kristi, - Olúwa, Ọba àwọn ọba. - Gbogbo wa kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀, - A ó sì máa yìn ín níṣọ̀kan. 
- 2. À ń fìyìn f’Ónídàájọ́ wa - tí yóò mú ìgbàlà wá. - Ọmọ Aládé Àlàáfíà - ti ń ṣàkóso ní ọ̀run. - Yóò jí àwọn òkú dìde; - Yóò mú ‘bẹ̀rù kúrò láyé. - À ń retí àkókò yìí, kó dé. - Gbogbo ayé ló máa láyọ̀! - (ÈGBÈ) - Ẹ yin Ọlọ́run wa; Ẹ yin Jésù Kristi, - Olúwa, Ọba àwọn ọba. - Gbogbo wa kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀, - A ó sì máa yìn ín níṣọ̀kan. 
(Tún wo Sm. 2:6; 45:1; Àìsá. 9:6; Jòh. 6:40.)