ORIN 19
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
- 1. Jèhófà, Bàbá wa ní ọ̀run, - Alẹ́ mímọ́ jù lọ nìyí, - Tó o pinnu láti fagbára àtìfẹ́ hàn - Pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo. - Ẹ̀jẹ̀ àgùntàn Ìrékọjá - Lo fi gbàwọn èèyàn rẹ là. - Alẹ́ yìí kan náà ni Kristi kú torí wa - Kó lè mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ. 
- 2. Búrẹ́dì tó wà níwájú wa - Àti wáìnì ń rán wa létí - Pé Jésù jólóòótọ́ - títí dójú ikú; - Ohun ńlá lo san, Jèhófà. - A ó máa ṣèrántí ikú Jésù. - Alẹ́ yìí ń rán wa létí pé - Ikú Ọmọ rẹ yìí - lo fi rà wá pa dà. - A moore ńlá tó o ṣe fún wa yìí. 
- 3. O pè wá, a sì dá ọ lóhùn. - A pé jọ ká lè jọ́sìn rẹ. - O fìfẹ́ yọ̀ǹda Kristi - Láti kú fún wa; - A yìn ọ́, a yin Ọmọ rẹ. - Ìrántí tá à ńṣe ńfògo fún ọ, - Ó ń fún àwa náà nígbàgbọ́. - A ó máa tẹ̀ lápẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ - Ká lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. 
(Tún wo Lúùkù 22:14-20; 1 Kọ́r. 11:23-26.)