ORIN 29
À Ń Jẹ́ Kí Orúkọ Wa Máa Rò Wá
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà ológo, Olódùmarè, - Orísun òótọ́, ọlọ́gbọ́n pípé. - Òdodo, agbára àtìfẹ́ rẹ pọ̀; - Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run. - Àwa èèyàn rẹ ń láyọ̀ báa ṣe ńsìn ọ́. - À ń fayọ̀ sọ òótọ́ Ìjọba rẹ. - (ÈGBÈ) - Àǹfààní ńlá ni pé a j’Ẹlẹ́rìí rẹ. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí orúkọ wa máa rò wá. 
- 2. Ìfẹ́ ń mú ká máa ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́. - Ó ń mú ká ṣiṣẹ́ pọ̀ lálàáfíà. - Ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń mú káyé wa dára; - Inú wa ń dùn bá a ṣe ń gbógo rẹ yọ. - Ẹlẹ́rìí Jèhófà laráyé ń pè wá, - Èyí ń jẹ́ ká lè fi kún iyì rẹ. - (ÈGBÈ) - Àǹfààní ńlá ni pé a j’Ẹlẹ́rìí rẹ. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí orúkọ wa máa rò wá. 
(Tún wo Diu. 32:4; Sm. 43:3; Dán. 2:20, 21.)