ORIN 40
Ti Ta Ni A Jẹ́?
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ti ta ni ìwọ jẹ́? - Ọlọ́run wo ni ò ń sìn? - Ẹni tí o bá ń ṣègbọràn sí - L’ọlọ́run rẹ, tó ń darí rẹ. - Kò ṣeé ṣe láti sin - Ọlọ́run méjì pa pọ̀. - Ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ ló máa - Pinnu èyí tó o máa yàn. 
- 2. Ti ta ni ìwọ jẹ́? - Ọlọ́run wo ni ò ń sìn? - Ọ̀kan jẹ́ òótọ́, ọ̀kan jékèé. - Yan èyí tó o fẹ́ fúnra rẹ. - Ṣé Ọba ayé yìí - Lo ṣì ń fi ọkàn rẹ sìn? - Àbí wàá sin Ọlọ́run òtítọ́, - Kó o sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀? 
- 3. Ti ta ni èmi jẹ́? - Jáà ni màá ṣègbọràn sí. - Bàbá mi ọ̀run lèmi yóò sìn. - Màá san gbogbo ẹ̀jẹ́ mi fún un. - Iye ńlá ló rà mí; - Tọkàntọkàn ni màá sìn ín. - Gbogbo ọjọ́ ayé mi ni màá fi - Gbé orúkọ ńlá rẹ̀ ga. 
(Tún wo Jóṣ. 24:15; Sm. 116:14, 18; 2 Tím. 2:19.)