ORIN 42
Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Alágbára, Jèhófà Bàbá wa, - Kórúkọ ńlá rẹ di sísọ di mímọ́. - Alèwílèṣe, jọ̀ọ́, à ń bẹ̀ ọ́. - À ń gbàdúrà kí Ìjọba rẹ dé - Lákòókò tó o ti ṣètò, - Ká lè rí ìbùkún gbà. 
- 2. O ṣé tó ò ń bù kún wa lójoojúmọ́. - Àwọn ẹ̀bùn rere tó ò ńfún wa pọ̀ gan-an. - Ò ń fún wa níyè àt’ìmọ́lẹ̀. - Ò ń fún wa lọ́gbọ́n, ìmọ̀ àtòye. - A ó máa dúpẹ́, a ó yìn ọ́ - Lójoojúmọ́ ayé wa. 
- 3. Ìpọ́njú pọ̀ gan-an nínú ayé yìí. - À ń wojú rẹ, jọ̀wọ́ wá tù wá nínú. - Gbogbo àníyàn wa là ń kó wá. - Fún wa lókun, má ṣe jẹ́ ká bọ́hùn. - Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ṣèfẹ́ rẹ, - Ká sì mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. 
(Tún wo Sm. 36:9; 50:14; Jòh. 16:33; Jém. 1:5.)