ORIN 45
Àṣàrò Ọkàn Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Kí àwọn èrò ọkàn mi, - Tí mò ń ṣàṣàrò lé lórí - Máa múnú rẹ dùn, Jèhófà, - Kó sì mú kí n dúró ṣinṣin. - T’àníyàn bá bò mí mọ́lẹ̀, - Tí kò jẹ́ kí n lè sùn lóru, - Kí n máa rántí rẹ, Jèhófà, - Àti àwọn ohun tó tọ́. 
- 2. Gbogbo ohun tó jẹ́ mímọ́ - Àti àwọn ìwà rere; - Ohun tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, - Ni mo fẹ́ máa rò lọ́kàn mi. - Jáà, ìrònú rẹ dára gan-an! - Ó pọ̀ kọjá àfẹnusọ. - Màá ṣàṣàrò lé ọ̀rọ̀ rẹ, - Jọ̀ọ́, jẹ́ kó máa gbà mí lọ́kàn. 
(Tún wo Sm. 49:3; 63:6; 139:17, 23; Fílí. 4:7, 8; 1 Tím. 4:15.)