ORIN 51
A Ti Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run!
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọlọ́run ló fà wá sọ́dọ̀ Jésù Kristi. - A dọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ látòní. - Jáà tan ìmọ́lẹ̀ òótọ́ - Láti orí ìtẹ́ rẹ̀. - Ìgbàgbọ́ wa ń lágbára; - A dé láti ṣèfẹ́ Jáà. - (ÈGBÈ) - A yàn láti yara wa sí mímọ́ fún Jáà. - À ń yọ̀ torí a ní Jésù pẹ̀lú. 
- 2. A gbàdúrà sí Jèhófà pé a ó máa sìnín. - Aó máa gbọ́ràn sí i títí ayé. - Ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ ni. - À ń forúkọ Jáà pè wá. - A ó fayọ̀ sọ fáráyé, - A ó wàásù Ìjọba náà. - (ÈGBÈ) - A yàn láti yara wa sí mímọ́ fún Jáà. - À ń yọ̀ torí a ní Jésù pẹ̀lú.