ORIN 55
Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
- 1. Èèyàn mi, ẹ tẹ̀ síwájú, - Ẹ wàásù Ìjọba náà. - Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọ̀tá. - Ẹ jẹ́ kí aráyé mọ̀ - Pé Jésù Ọmọ mi, Ọba - Ti lé ọ̀tá jù sáyé. - Láìpẹ́, yóò mú Èṣù, yóò sì - Tú àwọn tó dè sílẹ̀. - (ÈGBÈ) - Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá - Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín. - Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́ - Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi. 
- 2. Bí àwọn ọ̀tá yín tiẹ̀ pọ̀, - Tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ yín, - Tí wọ́n ń fi yín ṣẹlẹ́yà, - Kí wọ́n lè ṣì yín lọ́nà, - Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin tèmi - Bí wọ́n tiẹ̀ ń fìyà jẹ yín. - Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́ - Títí wọn yóò fi ṣẹ́gun. - (Ègbè) - Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá - Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín. - Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́ - Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi. 
- 3. Má ṣe rò pé mo pa ọ́ tì, - Èmi ṣì ni ààbò rẹ. - Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o kú, - Èmi yóò jí ọ dìde. - Má bẹ̀rù àwọn tó ń para, - Tí wọn kò lè pa ọkàn. - Jẹ́ olóòótọ́ títí dópin, - Màá fún ọ ládé ìyè! - (Ègbè) - Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá - Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín. - Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́ - Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi. 
(Tún wo Diu. 32:10; Neh. 4:14; Sm. 59:1; 83:2, 3.)