ORIN 62
Orin Tuntun
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Sáàmù 98)
- 1. Kọ orin tuntun, orin ìyìn s’Ọ́lọ́run wa - Sọ àwọn nǹkan tó ṣe, àtèyí tó máa ṣe. - Ní gbogbo ọ̀nà, Onídàájọ́ òdodo ni. - Yin Olódùmarè, - Ọlọ́run aṣẹ́gun. - (ÈGBÈ) - Kọ orin! - Gbé ohùn rẹ sókè. - Kọrin pé: - Jèhófà lọba wa! 
- 2. Bú sórin ayọ̀, fayọ̀ kọrin sí Ọlọ́run! - Gbé orúkọ rẹ̀ ga, kó o sì máa fògo fúnun. - Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kọrin ìyìn sí Ọlọ́run - Ìwọ náà, dara pọ̀, - Kí gbogbo wa jọ yìn ín. - (ÈGBÈ) - Kọ orin! - Gbé ohùn rẹ sókè. - Kọrin pé: - Jèhófà lọba wa! 
- 3. Kí omi òkun àtàwọn ẹ̀dá inú rẹ̀ - Fìyìn f’Ọ́lọ́run wa, kí wọ́n sì fò fáyọ̀. - Kí ilẹ̀ ayé àti àwọn òkè máa yọ̀. - Jẹ́ kí gbogbo odò - Máa fìyìn f’Ọ́lọ́run. - (ÈGBÈ) - Kọ orin! - Gbé ohùn rẹ sókè. - Kọrin pé: - Jèhófà lọba wa! 
(Tún wo Sm. 96:1; 149:1; Àìsá. 42:10.)