ORIN 68
Máa Fún Irúgbìn Ìjọba Náà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọ̀gá wa ń pè ọ́ pé kóo máa bọ̀, - Kó o wá ṣe nínú iṣẹ́ rẹ̀. - Fọkàn balẹ̀, yóò tọ́ ẹ sọ́nà, - Ó sì tún máa dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́. - Inú ọkàn àwọn onírẹ̀lẹ̀ - Nirúgbìn òótọ́ ti máa ń hù. - Torí náà, rí i pé o sa gbogbo ‘pá rẹ - Kó o lè ṣiṣẹ́ tá a yàn fún ọ yìí. 
- 2. Tíṣẹ́ rẹ bá máa sèso rere, - Nígbà míì, ọwọ́ rẹ ló wà. - Fìfẹ́ kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ - Kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. - Kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa kojú ‘ṣòro - Àt’àdánwò tó bá yọjú. - Inú rẹ máa dùn tó o bá rí bí wọ́n ṣe - Ń fi òótọ́ tí wọ́n ń kọ́ yìí sílò. 
(Tún wo Mát. 13:19-23; 22:37.)