ORIN 81
Ìgbésí Ayé Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
- 1. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, tí oòrùn kò tí ì yọ, - Ọkàn wa wà níbi - iṣẹ́ Jáà tá a pinnu láti ṣe. - À ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáyé, pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́; - Àwọn kan ń gbọ́rọ̀ wa, - báwọn kan kò tiẹ̀ wobi tá a wà. - (ÈGBÈ) - Iṣẹ́ tá a yàn nìyí, - Ìfẹ́ Jáà la fẹ́ ṣe. - Ohun tó fẹ́ ká ṣe la ó máa ṣe. - Bóòrùn ń ràn, bójò ń rọ̀, - Kò ṣèdíwọ́ fún wa. - Èyí la fi ń fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. 
- 2. Nígbà tílẹ̀ bá ṣú, tá a bojú wẹ̀yìn wò, - bó tiẹ̀ lè ti rẹ̀ wá, - Inú wa ń dùn, a sì ń gbàdúrà. - Jèhófà ń bù kún wa lójoojúmọ́ ayé. - À ń sun oorun ayọ̀, - à ń jí sáyé, a fọpẹ́ fún Jáà. - (ÈGBÈ) - Iṣẹ́ tá a yàn nìyí, - Ìfẹ́ Jáà la fẹ́ ṣe. - Ohun tó fẹ́ ká ṣe lá ó máa ṣe. - Bóòrùn ń ràn, bójò ń rọ̀, - Kò ṣèdíwọ́ fún wa. - Èyí la fi ń fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. 
(Tún wo Jóṣ. 24:15; Sm. 92:2; Róòmù 14:8.)