ORIN 92
Ibi Tá À Ń Fi Orúkọ Rẹ Pè
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Àǹfààní ńlá lèyí jẹ́ fún wa - Láti kọ́ ilé yìí fún ọ! - Gbogbo ohun tá a ní, tìrẹ ni. - A fi ń buyì fórúkọ rẹ. - Tọkàntọkàn la ń fi iṣẹ́ wa, - Okun wa, ohun ìní wa, - Bọlá fún orúkọ mímọ́ rẹ. - Ọlọ́run wa, jọ̀ọ́ tẹ́wọ́ gbà á. - (ÈGBÈ) - Ilé náà rè é níwájú rẹ, - Tá ó máa forúkọ rẹ pè. - A ti yà á sí mímọ́ fún ọ; - Tìrẹ ni títí láéláé. 
- 2. Ní báyìí, a gbórúkọ rẹ ga, - Kógo àtìyìn jẹ́ tìrẹ. - Kí àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ - Máa pọ̀ sí i nínú ilé yìí. - A ó máa jọ́sìn rẹ nínú ‘lé yìí, - A ó sì máa tọ́jú rẹ̀ dáadáa. - Kó lè máa jẹ́rìí fáwọn èèyàn, - Kó tiṣẹ́ ‘wàásù wa lẹ́yìn. - (ÈGBÈ) - Ilé náà rè é níwájú rẹ, - Tá ó máa forúkọ rẹ pè. - A ti yà á sí mímọ́ fún ọ; - Tìrẹ ni títí láéláé. 
(Tún wo 1 Ọba 8:18, 27; 1 Kíró. 29:11-14; Ìṣe 20:24.)