ORIN 111
Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
- 1. Bí a ṣe ń rí tí àwọn èèyàn - Tó ń dara pọ̀ mọ́ wa ń pọ̀ sí i, - Látinú gbogbo ‘rílẹ̀-èdè - Mú káyọ̀ wa pọ̀ púpọ̀ gan-an. - À ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ - Tí à ń kọ́ nínú Bíbélì. - À ń fi àwọn ẹ̀kọ́ yìí sílò; - Èyí ń mú káyọ̀ wa pọ̀ sí i. - Ayọ̀ ti wá kúnnú ọkàn wa, - Ayọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà. - Bí ‘ṣòro àtìpọ́njú bá dé, - Jèhófà yóò fún wa lókun. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, ìwọ layọ̀ wa, - Àwọn iṣẹ́ rẹ ń dùn mọ́ wa. - Èrò rẹ jinlẹ̀, iṣẹ́ rẹ tóbi; - Oore àtagbára rẹ pọ̀! 
- 2. Ayọ̀ wa kún bá a ṣe ń ríṣẹ́ rẹ - Lójú ọ̀run, lórí ilẹ̀; - Omi òkun sì lọ salalu, - A fìyìn fún ọ, Jèhófà. - A ti bí Ìjọba Ọlọ́run, - Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló ń mú bọ̀. - À ń wàásù rẹ̀ lọ bí aṣẹ́gun, - À ń fayọ̀ kéde fáráyé. - Ayọ̀ àìlópin wọlé dé tán, - Ìgbà ọ̀tun sì ti dé tán. - Ọ̀run àtayé tuntun yóò mú - Ìdùnnú ayérayé wá. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, ìwọ layọ̀ wa, - Àwọn iṣẹ́ rẹ ńdùn mọ́ wa. - Èrò rẹ jinlẹ̀, iṣẹ́ rẹ tóbi; - Oore àtagbára rẹ pọ̀! 
(Tún wo Diu. 16:15; Àìsá. 12:6; Jòh. 15:11.)