ORIN 114
Ẹ Máa Ní Sùúrù
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà Ọlọ́run wa - Nítara f’óókọ mímọ́ rẹ̀. - Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni pé - Kí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́. - Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà - Ti ń fara da ọ̀pọ̀ nǹkan. - Ó ń finúure hàn sí wa; - Ó ń fìfẹ́ ní sùúrù. - Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni pé - Kí ọ̀pọ̀ èèyàn rígbàlà. - Sùúrù tí Jèhófà ní - Látọjọ́ yìí kò já sásán. 
- 2. Tá a bá jẹ́ onísùúrù, - Ó máa tọ́ wa sọ́nà tó dáa. - Ó máa fọkàn wa balẹ̀. - Kò ní jẹ́ ká bínú sódì. - Kò ní jẹ́ kí a máa ṣọ́ - Àṣìṣe àwọn mìíràn. - Yóò jẹ́ ká nífaradà - Bí a tiẹ̀ níṣòro. - Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run - Yóò jẹ́ ká lè máa ní sùúrù. - Tá a bá jẹ́ onísùúrù, - A máa fìwà jọ Ọlọ́run. 
(Tún wo Ẹ́kís. 34:14; Àìsá. 40:28; 1 Kọ́r. 13:4, 7; 1 Tím. 2:4.)