ORIN 128
Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé - A nílò ‘faradà. - Ojúlówó ni ìfẹ́ wa, - Ẹ̀kọ́ wa jinlẹ̀ púpọ̀. - Àwọn ìdánwò ‘gbàgbọ́ wa, - Ń mú ká lè fẹsẹ̀ múlẹ̀. - Kígbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀, - Ọjọ́ Jèhófà dé tán. 
- 2. Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà - Kò gbọ́dọ̀ tutù láé. - Bá a ti ń dojú kọ àdánwò, - Má ṣe bẹ̀rù, má fòyà. - Ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Jáà, - Yóò mú kó o lè fara dà á. - Ìgbàgbọ́ rẹ máa lágbára - Tó o bá lè ní ‘faradà. 
- 3. Mọ̀ dájú pé àwọn tó bá - Fara dà á dé òpin - Ni yóò la ètò búburú - Ayé Sátánì kọjá - Sínú ayé tuntun tó ń bọ̀, - Orúkọ wọn yóò tàn yòò. - Máa bá a lọ ní fífara dà á - Kó o lè gba adé ògo. 
(Tún wo Héb. 6:19; Jém. 1:4; 2 Pét. 3:12; Ìfi. 2:4.)