ORIN 138
Ẹwà Orí Ewú
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A ní àwọn tó dàgbà - Ní ọjọ́ orí. - Wọ́n fara da ọ̀pọ̀ nǹkan - Nígbà ọ̀dọ́ wọn. - Àwọn kan ti pàdánù - Ẹnì kejì wọn. - Wọn kò lókun tó pọ̀ mọ́, - Wọ́n sì jólóòótọ́. - (ÈGBÈ) - Bàbá, jọ̀ọ́ kà wọ́n yẹ, - Jọ̀wọ́, rántí wọn. - Mú kí wọ́n gbóhùn rẹ - Pé, “O káre láé!” 
- 2. Ẹwà ni orí ewú - Lọ́nà òdodo. - Àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ - Jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n. - Ó yẹ káwa náà mọ̀ pé - Wọ́n ti ṣọ̀dọ́ rí. - Ẹni tó rẹwà ni wọ́n - Lójú Jèhófà. - (ÈGBÈ) - Bàbá, jọ̀ọ́ kà wọ́n yẹ, - Jọ̀wọ́, rántí wọn. - Mú kí wọ́n gbóhùn rẹ - Pé, “O káre láé!” 
(Tún wo Sm. 71:9, 18; Òwe 20:29; Mát. 25:21, 23; Lúùkù 22:28; 1 Tím. 5:1.)