ORIN 143
Tẹpá Mọ́ṣẹ́, Wà Lójúfò, Kó O sì Máa Retí
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Àmì tá à ń rí jẹ́ ká mọ̀ pé - Jèhófà Olódùmarè - Máa sorúkọ rẹ̀ di mímọ́; - Àkókò náà kò ní yẹ̀. - (ÈGBÈ) - Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò; - Máa fayọ̀ retí àkókò - Tá ó wà láàyè títí láé. 
- 2. Ọmọ Ọlọ́run ti ṣe tán; - Àkókò tó láti ṣígun - Bo àwọn ọ̀tá tó ń gbógun, - Ìṣẹ́gun sì ti dájú. - (ÈGBÈ) - Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò; - Máa fayọ̀ retí àkókò - Tá ó wà láàyè títí láé. 
- 3. Ìrora ti pọ̀ jù láyé, - A mọ̀ pé ìtura dé tán. - Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé; - A máa fìgbàgbọ́ dúró. - (ÈGBÈ) - Tẹpá mọ́ṣẹ́, kó o sì wà lójúfò; - Máa fayọ̀ retí àkókò - Tá ó wà láàyè títí láé. 
(Tún wo Mát. 25:13; Lúùkù 12:36.)