ORIN 149
Orin Ìṣẹ́gun
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ẹ kọrin ìyìn sí Jèhófà Bàbá wa lọ́run. - Ó pa Ọba Fáráò, àtàwọn ‘mọ ogun rẹ̀. - Olódùmarè; - Kò sí ẹni tó lè dojú kọ ọ́. - Jèhófà lokọ rẹ̀; - Òun ni ajagunṣẹ́gun. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, Ọba ayérayé, - Gbogbo ayé máa rí agbára rẹ, - Nígbà tó o bá pàwọn ọ̀tá rẹ run, - Wàá sọrúkọ rẹ di mímọ́. 
- 2. Gbogbo ìjọba, ti kóra jọ, wọ́n sì ńta ko Jáà. - Bí wọ́n ṣe lágbára tó, - Ìtìjú yóò bá wọn. - Bíi ti Fáráò, - Wọ́n máa pa run l’Ámágẹ́dọ́nì. - Gbogbo wa yóò gbà pé - Jèhófà lorúkọ rẹ. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, Ọba ayérayé, - Gbogbo ayé máa rí agbára rẹ, - Nígbà tóo bá pàwọn ọ̀tá rẹ run, - Wàá sọrúkọ rẹ di mímọ́. 
(Tún wo Sm. 2:2, 9; 92:8; Mál. 3:6; Ìfi. 16:16.)