ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 7A
Àwọn Orílẹ̀-èdè Tó Yí Jerúsálẹ́mù Ká
n. 650 sí 300 Ṣ.S.K.
DÉÈTÌ ÌṢẸ̀LẸ̀ (GBOGBO DÉÈTÌ JẸ́ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI)
- 620: Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso Jerúsálẹ́mù - Nebukadinésárì fi ọba Jerúsálẹ́mù sábẹ́ àkóso ara rẹ̀ 
- 617: Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bábílónì mú àwọn èèyàn lẹ́rú láti Jerúsálẹ́mù - Wọ́n mú àwọn alákòóso, àwọn jagunjagun tó lákíkanjú àtàwọn oníṣẹ́ ọ̀nà lọ sí Bábílónì 
- 607: Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run - Wọ́n dáná sun ìlú náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ 
- Lẹ́yìn 607: Tírè, ti orí ilẹ̀ - Nebukadinésárì gbógun ti Tírè fún ọdún mẹ́tàlá (13). Ó ṣẹ́gun Tírè orí ilẹ̀, àmọ́ Tírè orí omi ò tíì pa run 
- 602: Ámónì àti Móábù - Nebukadinésárì gbógun ja Ámónì àti Móábù 
- 588: Bábílónì ṣẹ́gun Íjíbítì - Nebukadinésárì gbógun ja Íjíbítì ní ọdún kẹtàdínlógójì (37) ìjọba rẹ̀ 
- 332: Tírè, ti orí omi - Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gíríìsì tí Alẹkisáńdà Ńlá jẹ́ olórí wọn, pa Tírè orí omi run 
- 332 tàbí ṣáájú: Filísíà - Alẹkisáńdà ṣẹ́gun Gásà, olú ìlú àwọn Filísínì 
Àwọn ibi tó wà lórí Àwòrán Ilẹ̀
- GÍRÍÌSÌ 
- ÒKUN ŃLÁ 
- (ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ) 
- TÍRÈ 
- Sídónì 
- Tírè 
- Samáríà 
- Jerúsálẹ́mù 
- Gásà 
- FILÍSÍÀ 
- ÍJÍBÍTÌ 
- BÁBÍLÓNÌ 
- ÁMÓNÌ 
- MÓÁBÙ 
- ÉDÓMÙ