Ẹ̀KỌ́ 17
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Yéni
1 Kọ́ríńtì 14:9
KÓKÓ PÀTÀKÌ: Ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ lọ́nà tó fi máa yé àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
- Ṣàyẹ̀wò ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa. Jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yé ẹ débi pé wàá lè fi ọ̀rọ̀ ara rẹ ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó rọrùn. 
- Lo àwọn gbólóhùn tí kò gùn àtàwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn. Òótọ́ ni pé kò sóhun tó burú nínú kí èèyàn lo gbólóhùn gígùn, àmọ́ ọ̀rọ̀ ṣókí ni kó o fi ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì. 
- Ṣàlàyé ohun tí kò yé àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Tó bá ṣeé ṣe, má ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ní yé àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀. Tó bá pọn dandan láti lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí tí o fẹ́ dárúkọ ẹnì kan nínú Bíbélì táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ àbí o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa òṣùwọ̀n kan tí wọ́n ń lò láyé àtijọ́ tàbí àṣà àtijọ́ kan, rí i pé o ṣàlàyé rẹ̀.