OHUN TÓ O KỌ́ NÍ APÁ 2
Kí ìwọ àti ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:
- Kí ni Ọlọ́run máa ṣe sí ẹ̀sìn èké? - (Wo Ẹ̀kọ́ 13.) 
- Ka Ẹ́kísódù 20:4-6. - Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà táwọn èèyàn bá ń lo ère nínú ìjọsìn wọn? - (Wo Ẹ̀kọ́ 14.) 
 
- Ta ni Jésù? - (Wo Ẹ̀kọ́ 15.) 
- Èwo nínú àwọn ìwà àti ìṣe Jésù lo fẹ́ràn jù? - (Wo Ẹ̀kọ́ 17.) 
- Ka Jòhánù 13:34, 35 àti Ìṣe 5:42. - Àwọn wo ni Kristẹni tòótọ́ lóde òní? Kí ló mú kó o gbà pé Kristẹni tòótọ́ ni wọ́n? 
 
- Ta ni orí ìjọ Kristẹni, báwo ló sì ṣe ń darí rẹ̀? - (Wo Ẹ̀kọ́ 20.) 
- Ka Mátíù 24:14. - Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ lónìí? 
- Àwọn wo lo ti wàásù ìhìn rere fún? 
 
- Ṣé o rò pé ìrìbọmi ṣe pàtàkì? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀? - (Wo Ẹ̀kọ́ 23.) 
- Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara ẹ lọ́wọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù? - (Wo Ẹ̀kọ́ 24.) 
- Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa? - (Wo Ẹ̀kọ́ 25.) 
- Kí nìdí táwa èèyàn fi ń jìyà tá a sì ń kú? - (Wo Ẹ̀kọ́ 26.) 
- Ka Jòhánù 3:16. - Kí ni Jèhófà ṣe fún wa ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú? - (Wo Ẹ̀kọ́ 27.) 
 
- Ka Oníwàásù 9:5. - Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? 
- Kí ni Jésù máa ṣe fún àìmọye èèyàn tó ti kú? 
 
- Kí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run dáa ju gbogbo ìjọba èèyàn lọ? 
- Ṣé o gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìgbà wo ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso? - (Wo Ẹ̀kọ́ 32.)