ORIN 156
Mo Ní Ìgbàgbọ́
- 1. Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ - Bí ọ̀tá tilẹ̀ ń gbógun. - Jèhófà wà lẹ́yìn mi, - Èmi kò ní bẹ̀rù. - Atófaratì ni Baba. - (ÈGBÈ) - Ó dá mi lójú pé - ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. - Kò sí ìbẹ̀rù kankan - lọ́rọ̀ mi. - Jèhófà Ọlọ́run ni - Alátìlẹ́yìn mi. - Mo mọ̀ pé - kò ní já mi kulẹ̀; - Mo nígbàgbọ́. 
- 2. Àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà - Tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn; - Wọ́n máa gba èrè wọn - Torí ìgbàgbọ́ wọn. - Jèhófà máa jí wọn dìde. - (ÈGBÈ) - Ó dá mi lójú pé - ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. - Kò sí ìbẹ̀rù kankan - lọ́rọ̀ mi. - Jèhófà Ọlọ́run ni - Alátìlẹ́yìn mi. - Mo mọ̀ pé - kò ní já mi kulẹ̀; - Mo nígbàgbọ́. - (ÀSOPỌ̀) - Ìgbàgbọ́ ló - jẹ́ kí n ṣọkàn akin. - Mo nírètí - tó dájú gan-an. - Ìgbàgbọ́ mi - Ló jẹ́ kí n máa - fara dà á lọ - Bí ìṣòro tilẹ̀ pọ̀ gan-an. 
- 3. Jèhófà ló ṣèlérí - Pé ayé tuntun ń bọ̀. - Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán. - Jèhófà kì í parọ́. - Baba, jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́ dópin. - (ÈGBÈ) - Ó dá mi lójú pé - ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. - Kò sí ìbẹ̀rù kankan - lọ́rọ̀ mi. - Jèhófà Ọlọ́run ni - Alátìlẹ́yìn mi. - Mo mọ̀ pé - kò ní já mi kulẹ̀; - Mo nígbàgbọ́. - Mo nígbàgbọ́. 
(Tún wo Héb. 11:1-40.)