SỌ WỌ́N DỌMỌ Ẹ̀YÌN
Ẹ̀KỌ́ 12
Má Bẹ̀rù Láti Sọ Òótọ́ Ọ̀rọ̀
Ìlànà: “Òróró àti tùràrí máa ń mú ọkàn yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni adùn ọ̀rẹ́ máa ń wá látinú ìmọ̀ràn àtọkànwá.”—Òwe 27:9.
Ohun Tí Jésù Ṣe
1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Máàkù 10:17-22. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
- Àwọn ìwà dáadáa wo ló ṣeé ṣe kí Jésù rí lára ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ náà? 
- Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ọkùnrin náà, kí nìdí tí kò fi yẹ kó bẹ̀rù láti bá a sòótọ́ ọ̀rọ̀? 
Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
2. Ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ó tún yẹ ká máa bá wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
3. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ ohun tó yẹ kó ṣe àti bó ṣe máa ṣe é.
- a. Ẹ máa jíròrò apá tá a pè ní “Ohun tó yẹ kó o ṣe” ní ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! 
- b. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ mọ àwọn nǹkan pàtó tó yẹ kó ṣe, kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ̀ ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. 
- d. Máa gbóríyìn fún un bó ṣe ń tẹ̀ síwájú. 
4. Mọ àwọn ohun tí kò jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ tẹ̀ síwájú, kó o sì ràn án lọ́wọ́ kó lè borí wọn.
- Bi ara ẹ pé: - ‘Kí ló ń dí ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ tí kò fi gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèrìbọmi?’ 
- ‘Kí ni mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́?’ 
 
- Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fìfẹ́ tọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ẹ sọ́nà, kó o má sì bẹ̀rù láti bá a sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. 
5. Tẹ́nì kan ò bá fẹ́ tẹ̀ síwájú, fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.
- Kó o lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, bi ara ẹ pé: - ‘Ṣé ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń fi ohun tó ń kọ́ sílò?’ 
- ‘Ṣó máa ń wá sípàdé, ṣó sì máa ń sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì?’ 
- ‘Lẹ́yìn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì débì kan, ṣó wù ú láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’ 
 
- Tí kò bá wu ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì tó máa jẹ́ kó tẹ̀ síwájú: - Ní kó ronú lórí ohun tí kò jẹ́ kó tẹ̀ síwájú. 
- Fìfẹ́ ṣàlàyé ìdí tó o fi fẹ́ fòpin sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. 
- Jẹ́ kó mọ àwọn ohun tó yẹ kó ṣe, kó tó lè pa dà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀.