Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀—Ohun Kan Ha Ṣàìtọ́ Bi?
“ÌJẸ́WỌ́ jẹ ìwẹ̀nùmọ́ tẹmi kan, ọ̀nà kan lati bẹrẹ lẹẹkan sii, ọna kan lati pa aṣiṣe atijọ rẹ́. Mo nifẹẹ lilọ si Ijẹwọ, sisọ awọn ẹ̀ṣẹ̀ mi fun alufaa, jijẹ ki o dari ji mi ati imọlara ayọ ti o tẹle e.” Bẹẹ ni Katoliki olufọkansin kan wi.—Bless Me, Father, for I Have Sinned.
Gẹgẹ bi New Catholic Encyclopedia ti wi, “alufaa nikan ni Kristi fún tabi gbé agbara dídè ati titusilẹ, didariji ati mimu ki” awọn ẹ̀ṣẹ̀ “wa niṣo” lé lọwọ. Iṣẹ itọkasi kan naa wipe ìjẹ́wọ́ deedee ni a pete “lati mu ijẹmimọ igbesi-aye ti a ti padanu nipasẹ ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo padabọsipo ati . . . lati sọ ẹ̀rí-ọkàn ẹnikan di mimọgaara.” Sibẹ, ipo ti iwahihu ni ọpọlọpọ ilẹ̀ wà fihan pe ìjẹ́wọ́ deedee ko mu ki ọpọlọpọ ti wọn ńṣe é “yipada kuro ninu ohun buburu, ki wọn sì ṣe ohun ti o jẹ rere.” (Saamu 34:14, New World Translation) Nitori naa ohun kan ha ṣàìtọ́ bi?
O Ha Wulẹ Jẹ Ààtò Isin Bi?
Ijẹwọ le bẹrẹ gẹgẹ bi ààtò isin kan lasan. Ni Ireland, ìjẹ́wọ́ akọkọ waye ni kete ṣaaju Ìdàpọ̀ Tẹ̀mí akọkọ. Njẹ o ha si jẹ iyalẹnu lọnakọna pe ọdọmọbinrin ọlọdun meje yoo ronu pupọ nipa aṣọ iyawo, ti o kere ti o si rẹwa ti oun yoo wọ̀ ju nipa ‘mimu ijẹmimọ igbesi-aye ti a ti padanu nipasẹ ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo padabọ sipo’?
“Ohun ti o ru mi soke julọ ni aṣọ naa, yatọ si rírí owó gbà lọwọ awọn ibatan mi,” ni Ramona jẹ́wọ́, ẹni ti o ṣe ìjẹ́wọ́ rẹ̀ akọkọ nigba ti oun jẹ ẹni ọdun meje. Oun nbaa lọ pe, “Laaarin gbogbo awọn ọdọmọbinrin ti mo mọ̀, ko si imọlara tẹmi kankan. Ko si ọkankan ninu wa ti o ronu nipa Ọlọrun ni akoko naa.”
Nitootọ, rírọ̀ awọn ọdọmọde lati jẹwọ ẹ̀ṣẹ̀ deedee le ṣamọna si àkàtúnkà alafaraṣe máfọkànṣe. Michael, ẹni ti o bẹrẹ àṣà ìjẹ́wọ́ ní ẹni ọdun meje tún wipe, “mo kan ńlò awọn ọ̀rọ̀ kan naa leralera ni.”
Ilohunsi awọn Katoliki melookan ti a kọsilẹ ninu iwe naa Bless Me, Father, for I Have Sinned fihan pe ìjẹ́wọ́ ni ijẹpataki tẹmi ti o kere jọjọ fun wọn ani lẹhin ti wọn ti dàgbà paapaa. “Ìjẹ́wọ́ kọ́ ọ lati purọ, nitori pe awọn ohun kan wà ti iwọ kò lè wulẹ fúnraàrẹ sọ fun alufaa,” ni ẹnikan jẹ́wọ́. Aisi ifohunṣọkan laaarin awọn alufaa ni a lè konifa fun iṣẹ ironupiwada mimọniwọn. Awọn kan maa nṣe iwakiri fun alufaa “rere” ti a lè jẹwọ ẹ̀ṣẹ̀ fun ki wọn baa lè rí imọran ti wọn fẹ́ gbọ́ gba. “Lẹhin ti mo ti ṣe ìdíyelé kaakiri fun oṣu mẹta, mo ri alufaa ti mo lè jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fun. Mo maa nri i loṣooṣu, ni ojukoju ninu iyara ibanilaja, oun si jẹ́ ẹni rere,” ni ọdọbinrin kan wi. “Bi iwọ ba jafafa, iwọ yoo ri alufaa kan ti o dití ti ko si lè sọ Gẹẹsi ayafi awọn ọrọ naa ‘ìdámúsò mẹta fun Maria,’” ni Katoliki miiran wi.
Lọna ti o han gbangba, nigba naa, ohun kan ṣàìtọ́ pẹlu ìjẹ́wọ́ gẹgẹ bi awọn eniyan kan ti nṣe e. Ṣugbọn Bibeli fihan pe o pọndandan lati jẹwọ ẹ̀ṣẹ̀, nitori o wipe: “Ko si ẹni ti nfi awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pamọ ti yoo láásìkí, ẹni yoowu ti o ba jẹwọ ti o si kọ̀ wọn silẹ ni yoo ri aanu.”—Owe 28:13, The New Jerusalem Bible.
Njẹ eyi ha tumọsi pe Kristian kan nilati jẹwọ gbogbo awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Bi o ba ri bẹẹ, fun ta ni? Ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e yoo ṣayẹwo awọn ibeere wọnyi.