Ìdí Tí Ìsìn Ayé Yóò Fi Dópin
“Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹlu rẹ̀ ninu awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára awọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.”—ÌṢÍPAYÁ 18:4.
1. (a) Ní ọ̀nà wo ni Babiloni Ńlá gbà ṣubú? (b) Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
“BABILONI ŃLÁ ti ṣubú!” Bẹ́ẹ̀ ni, ní ojú ìwòye Jehofa, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ti ṣubú. Èyí ti jẹ́ òtítọ́ láti ọdún 1919 wá, nígbà tí àṣẹ́kù àwọn arákùnrin Kristi jáde kúrò lábẹ́ agbára ìdarí Kirisẹ́ńdọ̀mù, apá tí ó hàn gbangba jù lọ nínú Babiloni onísìn awo. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, wọ́n ti lómìnira láti fi ìsìn èké bú, kí wọ́n sì kéde ìṣàkóso òdodo Ọlọrun nípasẹ̀ Ìjọba Messia náà. Jálẹ̀ ọ̀rúndún yìí, àwọn adúróṣinṣin Ẹlẹ́rìí fún Jehofa ti tú àṣírí àkójọpọ̀ àwọn ìsìn, tí Satani ń darí tí ó ti dọ́gbọ́n lò láti “ṣi gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—Ìṣípayá 12:9; 14:8; 18:2.
Báwo Ni Babiloni Ńlá Ṣe Ṣubú?
2. Báwo ni àwọn ìsìn ayé ti ń ṣe sí lónìí?
2 Ṣùgbọ́n, ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Báwo ni o ṣe lè sọ pé Babiloni ti ṣubú, nígbà tí ó dà bíi pé ìsìn ń gbèrú sí i ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀?’ Ìsìn Kátólíìkì àti ìsìn Islam ní àwọn ọmọlẹ́yìn tí ó ju bílíọ̀nù kọ̀ọ̀kan lọ. Ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ṣì ń gbèrú ní ilẹ̀ America, níbi tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ńlá àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kéékèèké ti ń jẹ yọ nígbà gbogbo. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń tẹ̀ lé àwọn ààtò àṣà ìsìn Buddha àti Hindu. Síbẹ̀, dé ìwọ̀n àyè wo ni ìsìn yìí fi ń nípa ìdarí tí ó dara lórí ìwà ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù wọ̀nyí? Ó ha ti ṣèdíwọ́ fún àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì láti má ṣe pa ara wọn ní Àríwá Ireland bí? Ó ha ti mú àlàáfíà tòótọ́ bá àwọn Júù àti àwọn Mùsùlùmí ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn bí? Ó ha ti yọrí sí ìṣọ̀kan láàárín àwọn onísìn Hindu àti àwọn Mùsùlùmí ní India bí? Àti, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ha ti ṣèdíwọ́ fún Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Serbia, Kátólíìkì ní Croatia, àti àwọn Mùsùlùmí ní Bosnia láti má ṣe lépa “pípa ẹ̀yà ìran run,” gbígbé sùnmọ̀mí, fífipá báni lò pọ̀, àti pípa ara wọn ní ìpakúpa bí? Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ìsìn wulẹ̀ máa ń jẹ́ ohun tí a fi ń júwe ẹnì kan, ìbòjú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan tí hílàhílo díẹ̀ lè já kúrò.—Galatia 5:19-21; fi wé Jakọbu 2:10, 11.
3. Èé ṣe tí ìsìn fi dojú kọ ìdájọ́ Ọlọrun?
3 Lójú ìwòye Ọlọrun, ní ti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe agbátẹrù ìsìn kò yí òkodoro òtítọ́ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ náà padà—gbogbo ìsìn ni yóò jẹ́jọ́ níwájú Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn rẹ̀ ti fi hàn, Babiloni Ńlá yẹ ní dídá lẹ́bi tí kò bára dé nítorí “awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́jọpọ̀ títí dé ọ̀run, Ọlọrun sì ti pe awọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí.” (Ìṣípayá 18:5) Hosea kọ̀wé ní ọ̀nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Nítorí wọ́n ti gbin ẹ̀fúùfù, wọ́n óò sì ká àjà.” Gbogbo ìsìn èké àgbáyé ti Satani ni a óò pa run fún dída Ọlọrun, ìfẹ́ rẹ̀, orúkọ rẹ̀, àti Ọmọkùnrin rẹ̀.—Hosea 8:7; Galatia 6:7; 1 Johannu 2:22, 23.
O Ní Láti Yàn
4, 5. (a) Irú ipò wo ni a ń gbé lónìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a gbọ́dọ̀ dáhùn?
4 A ń gbé ní apá tí ó kẹ́yìn nínú “awọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àti gẹ́gẹ́ bíi Kristian tòótọ́, a ń jìjàkadì láti la “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò” wọ̀nyí já. (2 Timoteu 3:1-5) Àwọn Kristian tòótọ́ jẹ́ olùgbé fún ìgbà díẹ̀ nínú ayé Satani, èyí tí ó fi àkópọ̀ ìwà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apànìyàn, òpùrọ́, àti abanijẹ́ hàn ní tòótọ́. (Johannu 8:44; 1 Peteru 2:11, 12; Ìṣípayá 12:10) Ìwà ipá, ẹ̀tàn, jìbìtì, ìwà ìbàjẹ́, àti ìwà pálapàla lílé kenkà ni ó yí wa ká. A ti pa ìlànà tì. Ìgbésí ayé aláfẹ́ àti àǹfààní ojú ẹsẹ̀ ni ó ṣàpèjúwe bí ipò náà ti rí gan-an. Àti ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwùjọ àlùfáà ń fàyè gba ìwà ìbàjẹ́ nípa bíbu omi la dídá tí Bibeli dá ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, àgbèrè, àti panṣágà lẹ́bi lọ́nà tí ó hàn kedere. Nípa báyìí, ìbéèrè náà ni pé, O ha ń ti ìjọsìn èké lẹ́yìn, tí o sì ń fàyè gbà á, tàbí o ha ń fi aápọn lọ́wọ́ nínú ìjọsìn tòótọ́ bí?—Lefitiku 18:22; 20:13; Romu 1:26, 27; 1 Korinti 6:9-11.
5 Àkókò sísẹ́mọ́ nìyí. Nítorí náà, ìdí púpọ̀ sí i wà láti fìyàtọ̀ sáàárín ìjọsìn èké àti ìjọsìn tòótọ́. Kí tún ni àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe tí wọ́n fi yẹ fún ìbáwí tó bẹ́ẹ̀?—Malaki 3:18; Johannu 4:23, 24.
A Fẹ̀sùn Kan Ìsìn Èké
6. Báwo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe da Ìjọba Ọlọrun?
6 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù ń lo Àdúrà Oluwa déédéé, nínú èyí tí wọ́n ń gbàdúrà kí Ìjọba Ọlọrun dé, wọ́n ti fìtara ṣètìlẹyìn fún gbogbo oríṣiríṣi ètò òṣèlú, wọn kò sì ṣú já àkóso àtọ̀runwá. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn “àwọn ọmọ aládé” ti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, irú àwọn bíi Kádínà Richelieu, Mazarin, àti Wolsey, pẹ̀lú ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣáájú òṣèlú ti ayé, àwọn mínísítà ìjọba.
7. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe tú àṣírí àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ní èyí tí ó lé ní 50 ọdún sẹ́yìn?
7 Ní èyí tí ó ju 50 ọdún sẹ́yìn, nínú ìwé pẹlẹbẹ tí a pè ní Religion Reaps the Whirlwind, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tú àṣírí bí Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú.a Ohun tí wọ́n sọ nígbà náà lọ́hùn-ún rí bákan náà gẹ́lẹ́ lónìí pé: “Ìwádìí tòótọ́ nípa ìwà àwùjọ àlùfáà ìsìn nínú gbogbo ẹ̀ya ìsìn yóò ṣí i payá pé àwọn aṣáájú ìsìn ní gbogbo ‘Kirisẹ́ńdọ̀mù’ ń fi ìfẹ́-ọkàn lílágbára lọ́wọ́ nínú ìṣèlú ‘ètò ayé búburú yìí,’ wọ́n sì ń lọ́wọ́ sí àwọn àlámọ̀rí ayé.” Nígbà náà lọ́hùn-ún, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe lámèyítọ́ Póòpù Pius Kejìlá kíkankíkan fún àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Nazi ti Hitler (1933) àti Ìjọba Bòńbàtà ti Franco (1941), àti bí póòpù àti orílẹ̀-èdè òfinràn náà Japan ní March 1942, ṣe ń ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn aṣojú olùṣemẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀, ní kìkì oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìkọlù bíburú jáì náà ní ibùdókọ̀ ojú omi Pearl Harbor. Póòpù kùnà láti kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jakọbu pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹlu ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹlu Ọlọrun? Nitori naa, ẹni yòówù tí ó bá fẹ́ lati jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọrun.”—Jakọbu 4:4.
8. Báwo ni Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ṣe lọ́wọ́ nínú ìṣèlú lónìí?
8 Báwo ni nǹkan ti rí lónìí? Póòpù ṣì ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú, nípasẹ̀ àwùjọ àlùfáà rẹ̀ àti nípasẹ̀ àwọn ọmọ ìjọ tí ń ṣojú fún un. Àwọn póòpù àìpẹ́ yìí ti fọwọ́ sí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè nípa fífi ọ̀rọ̀ àlàáfíà àgbáyé lọ ayédèrú náà tí ènìyàn gbé kalẹ̀. Nínú ìtẹ̀jáde L’Osservatore Romano ti àìpẹ́ yìí, ìwé agbéròyìnjáde àfàṣẹtìlẹ́yìn ti Vatican, kéde pé àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè méje tuntun, “àwọn ikọ̀ ìjọba tí a rán lọ sí Ibùjókòó Ọlá Àṣẹ Póòpù” mú àwọn ìwé ẹ̀rí wọn wá fún “Baba Mímọ́” náà. A ha lè ronú kí Jesu àti Peteru lọ́wọ́ nínú pàṣípààrọ̀ onímẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ bẹ́ẹ̀ bí? Jesu kọ̀ kí àwọn Júù fi í jọba, ó sì wí pé Ìjọba òun kì í ṣe ti ayé yìí.—Johannu 6:15; 18:36.
9. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àwọn ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì kò sàn ju àwọn Kátólíìkì ẹlẹgbẹ́ wọn lọ?
9 Àwọn aṣáájú Pùròtẹ́sítáǹtì ha sàn ju àwọn ti Kátólíìkì ẹlẹgbẹ́ wọn bí? Ní United States, ọ̀pọ̀ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì tí ń tẹ̀ lé ìlànà àtọwọ́dọ́wọ́, àti àwọn Mormon pẹ̀lú, ni a fi àjọṣe òṣèlú kan pàtó dá mọ̀ yàtọ̀. Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan Kristian ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú United States. Àwùjọ àlùfáà Pùròtẹ́sítáǹtì míràn fara hàn kedere bí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn. A máa ń gbàgbé nígbà míràn pé àwọn agbẹnusọ olóṣèlú United States, bíi Pat Robertson àti Jesse Jackson ni a mọ̀ sí “Àwọn Ẹni Ọ̀wọ̀,” tàbí pé a mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú ọmọ ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ti ilẹ̀ Britain, Ian Paisley, tí ó jẹ́ ará Àríwá Ireland. Àwíjàre wo ni wọ́n lè ní fún àwọn ipò wọn?—Ìṣe 10:34, 35; Galatia 2:6.
10. Ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kedere wo ni a sọ ní ọdún 1944?
10 Gẹ́gẹ́ bí ìwé pẹlẹbẹ Religion Reaps the Whirlwind ṣe béèrè ní 1944, bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú nísinsìnyí ṣe béèrè pé: “Ǹjẹ́ ètò àjọ kankan tí ó kó wọnú àdéhùn pẹ̀lú àwọn agbára ayé tí ó sì ń fi torítọrùn ki ara rẹ̀ bọnú àwọn àlámọ̀rí ayé yìí, tí ń wá ojú rere àti ààbò láti ọ̀dọ̀ ayé yìí . . . ha lè jẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì Ọlọrun tàbí aṣojú Kristi Jesu lórí ilẹ̀ ayé bí? . . . Ní kedere, gbogbo àwọn onísìn tí wọ́n ní góńgó kan náà pẹ̀lú àwọn ìjọba ayé yìí kò lè ṣojú fún ìjọba Ọlọrun nípasẹ̀ Kristi Jesu.”
Ẹ̀mí Kaini Tí Ìsìn Èké Ní
11. Báwo ni ìsìn èké ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kaini?
11 Jálẹ̀ ìtàn, ìsìn èké ti ṣàfihàn ẹ̀mí pípa ọmọ ìyá ẹni tí Kaini ní, ẹni tí ó pa Abeli, àbúrò rẹ̀. “Awọn ọmọ Ọlọrun ati awọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òkodoro òtítọ́ yii: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo kò pilẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀. Nitori èyí ni ìhìn-iṣẹ́ tí ẹ̀yin ti gbọ́ lati ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, pé a níláti ní ìfẹ́ fún ara wa lẹ́nìkínní kejì; kì í ṣe bí Kaini, ẹni tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ ẹni burúkú naa tí ó sì fikúpa arákùnrin rẹ̀. Nitori kí ni oun sì ṣe fikúpa á? Nitori pé awọn iṣẹ́ tirẹ̀ burú pin, ṣugbọn awọn ti arákùnrin rẹ̀ jẹ́ òdodo.” Nítorí àìlèfaramọ́ ìjọsìn mímọ́ gaara tí Ọlọrun tẹ́wọ́ gbà tí àbúrò rẹ̀ ń ṣe, Kaini yíjú sí ìwà ipá—ohun tí àwọn tí kò mọ ojútùú tí ó mọ́gbọ́n dání máa ń yíjú sí nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—1 Johannu 3:10-12.
12. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé ìsìn ti ń lọ́wọ́ nínú ogun àti gbọ́nmisi-omi-òto?
12 Àwọn òkodoro òtítọ́ ha ti ẹ̀sùn tí a fi kan ìsìn èké lẹ́yìn bí? Nínú ìwé náà, Preachers Present Arms, òǹkọ̀wé náà sọ pé: “Nínú ìtàn ọ̀làjú, . . . ipá méjì ni a sábà máa ń so pọ̀ nínú àjọṣepọ̀ alápá méjì. Àwọn ni ogun àti ìsìn. Àti, nínú gbogbo ìsìn ńláńlá ní àgbáyé, . . . kò tí ì sí èyí tí ó fi ara rẹ̀ fún [ogun] ju bí [Kirisẹ́ńdọ̀mù] ti ṣe lọ.” Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìwé agbéròyìnjáde The Sun ti Vancouver, ní Kánádà, ṣàlàyé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àléébù gbogbo ètò ìsìn pé kí ṣọ́ọ̀ṣì máa tẹ̀ lé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè . . . Ogun wo ni a tí ì jà rí, tí wọn kò wí pé Ọlọrun wà ní ìhà kọ̀ọ̀kan?” O ti lè rí ẹ̀rí èyí ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ní àdúgbò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sábà máa ń jẹ́ pé, àsíá orílẹ̀-èdè ni a fi ṣe pẹpẹ lọ́ṣọ̀ọ́. Lábẹ́ àsíá wo ni o rò pé Jesu yóò wà? A ti sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àsọtúnsọ jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apákan ayé yii”!—Johannu 18:36.
13. (a) Báwo ni ìsìn èké ṣe kùnà ní Áfíríkà? (b) Àmì tí a fi lè dá ìsìn Kristian mọ̀ wo ni Jesu fúnni?
13 Àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù kò fi òtítọ́ ojúlówó ìfẹ́ni ará kọ́ agbo wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìyàtọ̀ ní ti orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, àti ẹ̀yà ìran ni wọ́n yọ̀ọ̀da fún láti pín àwọn mẹ́ḿbà wọn níyà. Ìròyìn fi hàn pé àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì àti ti Anglican kópa nínú ìpínyà tí ó yọrí sí pípa ẹ̀yà ìran kan run ní Rwanda. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Ìpakúpa tí ó wáyé ní Rwanda ti mú ọ̀pọ̀ àwọn Roman Kátólíìkì ronú pé ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà olùṣàkóso ti dà wọ́n. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n ti fi ẹ̀yà ìran pín ṣọ́ọ̀ṣì níyà, láàárín àwọn Hutu àti Tutsi.” Ìwé agbéròyìnjáde kan náà fa ọ̀rọ̀ àlùfáà Maryknoll yọ ní sísọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì kùnà lọ́nà gígadabú ní Rwanda ní 1994. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Rwanda ti pa ṣọ́ọ̀ṣì tì. Wọn kò gbà á gbọ́ mọ́.” Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ Jesu tó, wí pé: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Johannu 13:35.
14. Àkọsílẹ̀ ìwà wo ni àwọn ìsìn tí kì í ṣe ti Kristian pèsè?
14 Àwọn ìsìn pàtàkì míràn nínú Babiloni Ńlá kò fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Ìpakúpa tí ó burú jáì ti 1947, nígbà tí a pín India sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, fi hàn pé àwọn ìsìn pàtàkì níbẹ̀ kò rí ara gba nǹkan sí. Ìwà ipá àwùjọ tí ń bá a lọ ní India jẹ́rìí sí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn kò tí ì yí padà. Abájọ tí ìwé ìròyìn India Today fi parí rẹ̀ pé: “Orúkọ ìsìn ni a fi ń hu ìwà ọ̀daràn bíbani lẹ́rù tí ó pọ̀ jù lọ. . . . Ó ń fàyè gba ìwà ipá tí ó lé kenkà, ó sì jẹ́ ipá tí ń ba nǹkan jẹ́ gidigidi.”
“Ẹ̀dà Ọ̀rọ̀ Yíyani Lẹ́nu”
15. Ipò wo ni ìsìn wà ní ìwọ̀ oòrùn ayé?
15 Àwọn alálàyé nínú ayé pàápàá ti ṣàkíyèsí ìkùnà ìsìn láti mú ọ̀ràn ṣe kedere, láti gbin àwọn ìlànà tòótọ́ sí àwọn ènìyàn lọ́kàn, àti láti dènà gbígbé ọ̀nà ìwà híhù àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ karí ìsìn. Nínú ìwé rẹ̀, Out of Control, olùgbaninímọ̀ràn lórí ààbò orílẹ̀-èdè United States tẹ́lẹ̀ rí, Zbigniew Brzezinski, kọ̀wé pé: “Ó jẹ́ ẹ̀dà ọ̀rọ̀ yíyani lẹ́nu pé ìjagunmólú tí ó ga jù lọ fún ọ̀rọ̀ náà pé ‘Ọlọrun ti kú’ kò jẹ yọ nínú àwọn ìpínlẹ̀ tí ìjọba Afẹ́nifẹ́re ti gbilẹ̀ . . . ṣùgbọ́n nínú àwùjọ dẹmọ afẹ́dàáfẹ́re ti Ìwọ̀ Oòrùn ayé, níbi tí àṣà ìbílẹ̀ wọn ti fi ẹ̀mí ìdágunlá ní ti ìwà híhù kọ́ni. Nínú àwùjọ tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yìí, òkodoro òtítọ́ náà ni pé ìsìn ti ṣíwọ́ jíjẹ́ ipá pàtàkì tí ń darí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.” Ó tẹ̀ síwájú pé: “Ipa tí ìsìn ní lórí àṣà ìbílẹ̀ Europe ti dín kù gidigidi, àti pé Europe lónìí—àní lọ́nà tí ó ju ti America lọ fíìfíì—jẹ́ àwùjọ tí kò gbé ọ̀nà ìwà híhù àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ karí ìsìn ní pàtàkì.”
16, 17. (a) Ìmọ̀ràn wo ni Jesu fúnni ní ti àwùjọ àlùfáà ọjọ́ rẹ̀? (b) Ìlànà àtàtà wo ni Jesu sọ jáde nípa ìmésojáde?
16 Kí ni Jesu sọ nípa àwùjọ àlùfáà Júù ti ọjọ́ rẹ̀? “Awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi mú ara wọn jókòó ní ìjókòó Mose [láti fi Torah, Òfin kọ́ni]. Nitori naa gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún yín, ni kí ẹ ṣe kí ẹ sì pamọ́, ṣugbọn ẹ máṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí awọn ìṣe wọn, nitori wọn a máa wí ṣugbọn wọn kì í ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni, àgàbàgebè ìsìn kì í ṣe tuntun.—Matteu 23:2, 3.
17 Èso ìsìn èké bẹnu àtẹ́ lù ú. Ìlànà tí Jesu fi lélẹ̀ ṣe déédéé gan-an pé: “Gbogbo igi rere a máa mú eso àtàtà jáde, ṣugbọn gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò níláárí jáde; igi rere kò lè so èso tí kò níláárí, bẹ́ẹ̀ ni igi jíjẹrà kò lè mú èso àtàtà jáde. Gbogbo igi tí kò ń mú èso àtàtà jáde ni a óò ké lulẹ̀ tí a óò sì sọ sínú iná. Níti tòótọ́, nígbà naa, nipa awọn èso wọn ni ẹ̀yin yoo fi dá awọn ènìyàn wọnnì mọ̀.”—Matteu 7:17-20.
18. Báwo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ì bá ti mú kí àwùjọ rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní?
18 Bí àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù bá fi pẹ̀lú òtítọ́ inú ṣàmúlò àwọn ìbáwí Kristian ní ti ìyọlẹ́gbẹ́, tàbí gbígba àǹfààní jíjẹ́ mẹ́ḿbà ìjọ lọ́wọ́ ẹni, nítorí àwọn ìṣe tí kò bá òfin mu tí àwọn tí wọ́n fẹnu lásán jẹ́ mẹ́ḿbà ń ṣe, kí ni yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn òpùrọ́, àgbèrè, panṣágà, abẹ́ya-kan-náà-lòpọ̀, arẹ́nijẹ, ọ̀daràn, àwọn oníṣòwò oògùn olóró àti àwọn ajòògùnyó, àti àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ oníwà ipá tí wọn kò ronú pìwà dà? Láìṣe àníàní, èso jíjẹrà Kirisẹ́ńdọ̀mù mú kí ó yẹ fún kìkì ìparun láti ọwọ́ Ọlọrun.—1 Korinti 5:9-13; 2 Johannu 10, 11.
19. Àwọn ìjẹ́wọ́ wo ni a ti ṣe nípa ìṣàkóso ìsìn?
19 Ẹgbẹ́ olùṣàkóso gíga jù lọ fún Ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian ní United States jẹ́wọ́ pé: “A ń dojú kọ yánpọnyánrin tí ó burú jáì ní ti bí ó ti ń ṣẹlẹ̀ àti ìyọrísí rẹ̀. . . . Láàárín ìpín 10 sí 23 nínú ọgọ́rùn-ún àwùjọ àlùfáà káàkiri àgbáyé ti lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla tàbí ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ, àwọn tí ń wá ìmọ̀ràn wá sọ́dọ̀ wọn, àwọn tí wọ́n gbà síṣẹ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.” Ọkùnrin oníṣòwò kan ní United States ṣàkópọ̀ kókó náà dáradára pé: “Àwọn ìgbékalẹ̀ ìsìn ti kùnà láti ta àwọn ìlànà ìwà réré wọn àtayébáyé ní àtaré, àti ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n ti di apá kan ìṣòro náà.”
20, 21. (a) Báwo ni Jesu àti Paulu ṣe fi àgàbàgebè bú? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni ó ṣì wà láti dáhùn?
20 Bí Jesu ṣe fi ìsìn àgàbàgebè bú ṣì jẹ́ òtítọ́ lónìí gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ìgbà tirẹ̀ pé: “Ẹ̀yin alágàbàgebè, Isaiah sọtẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nipa yín, nígbà tí ó wí pé, ‘Awọn ènìyàn yii ń fi ètè wọn bọlá fún mi, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọ́n jìnnà réré sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nitori pé wọ́n ń fi awọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.’” (Matteu 15:7-9) Àwọn ọ̀rọ̀ Paulu sí Titu pẹ̀lú ṣàpèjúwe bí ipò wa ṣe rí ní òde òní pé: “Wọ́n polongo ní gbangba pé awọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹlu rẹ̀ nipa awọn iṣẹ́ wọn, nitori tí wọ́n jẹ́ ẹni ìṣe-họ́ọ̀-sí ati aláìgbọràn a kò sì fi ojúrere tẹ́wọ́gbà wọ́n fún iṣẹ́ rere èyíkéyìí.”—Titu 1:16.
21 Jesu sọ pé bí afọ́jú bá ń fọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì yóò já sínú kòtò. (Matteu 15:14) O ha fẹ́ láti parun pẹ̀lú Babiloni Ńlá bí? Àbí o ha fẹ́ láti rìn ní ọ̀nà tààrà pẹ̀lú ojú rẹ ní lílà sílẹ̀, kí o sì gbádùn ìbùkún Jehofa? Àwọn ìbéèrè tí ó dojú kọ wá nísinsìnyí ni pé: Ìsìn wo, bí ó bá tilẹ̀ wà rárá, ní ń mú èso ìwà-bí-Ọlọ́run jáde? Bawo ni a ṣe lè dá ìjọsìn tòótọ́ tí Ọlọrun fọwọ́ sí mọ̀ yàtọ̀?—Orin Dafidi 119:105.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ní 1944; a kò tẹ̀ ẹ́ mọ́ nísinsìnyí.
Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni ìdúró Babiloni Ńlá lónìí pẹ̀lú Ọlọrun?
◻ Ẹ̀sùn wo ni a fi kan ìsìn èké?
◻ Báwo ni ìsìn èké ṣe fi ẹ̀mí Kaini hàn?
◻ Ìlànà wo ni Jesu sọ fún ṣíṣe ìdájọ́ ìsìn èyíkéyìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jálẹ̀ ìtàn, àwọn aṣáájú ìsìn ti lọ́wọ́ nínú ìṣèlú
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn àlùfáà wọ̀nyí tún jẹ́ àwọn ògbóǹtarìgì aṣáájú òṣèlú
Kádínà Mazarin
Kádínà Richelieu
Kádínà Wolsey
[Picture Credit Line]
Kádínà Mazarin àti Kádínà Richelieu: Láti inú ìwé náà, Ridpath’s History of the World, (Ìdìpọ̀ Kẹfà àti Ìdìpọ̀ Karùn-ún ní ìtòtẹ̀léra wọn). Kádínà Wolsey: Láti inú iwé náà, The History of Protestantism, (Ìdìpọ̀ Kìíní).