Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Dáníẹ́lì Fi Ìdúró Gbọn-in Ṣiṣẹ́ Sin Ọlọ́run
ÓṢỌ̀WỌ́N pé kí ipa ìtàn yí padà ní ọ̀sán-kan-òru-kan. Síbẹ̀, ìyẹ́n ṣẹlẹ̀ ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn ará Mídíà àti Páṣíà bi Ilẹ̀ Ọba Bábílónì wó láàárín wákàtí díẹ̀ péré. Ní ọdún yẹn, wòlíì Jèhófà, Dáníẹ́lì, ti gbé gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn Júù ní Bábílónì fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 80 ọdún. Ó kù díẹ̀ báyìí kí Dáníẹ́lì, ẹni tí ó ṣeé ṣe kí ó ti lé ní 90 ọdún, dojú kọ ọ̀kan nínú àwọn ìdánwò gíga jù lọ ní ti ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.
Lẹ́yìn tí Bábílónì ṣubú, ó kọ́kọ́ dà bíi pé nǹkan ń dán mọ́rán fún Dáníẹ́lì. Dáríúsì ará Mídíà ni ọba tuntun, ọkùnrin ẹni ọdún 62 tí ó fojú rere wo Dáníẹ́lì. Ọ̀kan nínú àwọn ìgbésẹ̀ tí Dáríúsì kọ́kọ́ gbé gẹ́gẹ́ bí ọba jẹ́ láti yan àwọn 120 alákòóso, kí ó sì gbé àwọn ọkùnrin mẹ́ta ga sí ipò ọ̀gá àgbà lẹ́nu iṣẹ́ ọba.a Dáníẹ́lì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí a ṣojú rere sí wọ̀nyẹn. Ní mímọ àwọn ànímọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Dáníẹ́lì ní, Dáríúsì tilẹ̀ ní in lọ́kàn láti fún un ní ipò olórí ìjọba pàápàá! Ṣùgbọ́n, nígbà náà gan-an ni nǹkan kan ṣẹlẹ̀, tí ó yí ìwéwèé ọba padà láìrò tẹ́lẹ̀.
Ìwéwèé Alárèékérekè
Àwọn ọ̀gá àgbà lẹ́nu iṣẹ́ ọba tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Dáníẹ́lì, tí àwùjọ ńlá ti àwọn alákòóso tẹ̀ lé lẹ́yìn, tọ ọba lọ pẹ̀lú èrò kan tí ń fani lọ́kàn mọ́ra. Wọ́n bẹ Dáríúsì láti fìdí òfin kan múlẹ̀ tí yóò pàṣẹ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run tàbí ènìyànkénìyàn níwọ̀n ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe pé lọ́wọ́ rẹ, ọba, a óò gbé e sọ sínú ihò kìnnìún.” (Dáníẹ́lì 6:8) Lójú Dáríúsì, ó ti lè dà bí i pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń kéde ìdúróṣinṣin wọn fún un ní gbangba. Ó ti lè ronú pẹ̀lú pé òfin yìí yóò ran òun, tí ó jẹ́ àjèjì kan lọ́wọ́, láti fún ipò òun gẹ́gẹ́ bí olórí Ìjọba lókun sí i.
Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀gá àgbà lẹ́nu iṣẹ́ ọba àti àwọn alákòóso náà kò wéwèé òfin yìí nítorí ti ọba. Wọ́n “ń wá ọ̀nà láti bá Dáníẹ́lì fẹ́fẹ̀ẹ́ ní ti ohun ìjọba, ṣùgbọ́n wọn kò lè rí ẹ̀fẹ́kẹ́fẹ̀ẹ́ tàbí ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; níwọ̀n bí òún ti jẹ́ olódodo ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì rí ìṣìnà tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.” Nítorí náà, àwọn ọkùnrin alárèékérekè wọ̀nyí ronú pé: “Àwa kì yóò lè rí ẹ̀fẹ́kẹ́fẹ̀ẹ́ kan sí Dáníẹ́lì bí kò ṣe pé a bá rí sí i nípasẹ̀ òfin Ọlọ́run rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 6:5, 6) Bí wọ́n ti mọ̀ pé Dáníẹ́lì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́, wọ́n wá ọ̀nà láti sọ èyí di ẹ̀ṣẹ̀ tí ó yẹ sí ikú.
Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀gá àgbà lẹ́nu iṣẹ́ ọba àti àwọn alákòóso náà ní ìkùnsínú sí Dáníẹ́lì nítorí pé ó “borí gbogbo [wọn] . . . , nítorí pé ẹ̀mí títa yọ wà lára rẹ̀: ọba sì ń gbèrò láti fi í ṣe olórí gbogbo ìjọba.” (Dáníẹ́lì 6:4) Àìlábòsí Dáníẹ́lì ti lè ṣèdíwọ́ fún ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà jẹgúdújẹrá, lọ́nà tí inú wọn kò dùn sí. Ohun yòó wù kí ọ̀ràn náà jẹ́, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí yí ọba lérò padà láti fí ọwọ́ sí òfin náà, ní sísọ ọ́ dí apá kan “òfin àwọn ará Mídíánì àti Páṣíà, èyí tí a kò gbọdọ̀ pa dà.”—Dáníẹ́lì 6:9, 10.
Dáníẹ́lì Dúró Ṣinṣin
Lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ nípa òfin tuntun náà, Dáníẹ́lì ha dẹ́kun gbígbàdúrà sí Jèhófà bí? Àgbẹdọ̀! Ní kíkúnlẹ̀ nínú òrùlé yàrá ilé rẹ̀, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹ́ta lóòjọ́, “gẹ́gẹ́ bí òún ti í ṣe nígbà àtijọ́ rí.” (Dáníẹ́lì 6:11) Bí ó ti ń gbàdúrà, àwọn ọ̀tá rẹ̀ “rọ́ wọlé, wọ́n sì rí Dáníẹ́lì ń gbàdúrà, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 6:12) Nígbà tí wọ́n mú ọ̀ràn náà wá sí àfiyèsí ọba, Dáríúsì banú jẹ́ pé òfin tí òún fọwọ́ sí yóò mú Dáníẹ́lì. Ìròyìn náà sọ fún wa pé: “Ó . . . ṣe làálàá àtigbà á sílẹ̀ títí fi di ìgbà tí oòrùn wọ̀.” Ṣùgbọ́n ọba pàápàá kò lè fagi lé òfin tí òún ti ṣe. Nítorí náà, a mú Dáníẹ́lì lọ sínú ihò kìnnìún, tí ó hàn gbangba pé ó jẹ́ kòtò tàbí àjàalẹ̀ kan. Ọba mú un dá Dáníẹ́lì lójú pé: “Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ìwọ́ ń fi [ìdúró gbọn-in, NW] sìn, òun óò gbà ọ́ là.”—Dáníẹ́lì 6:13-17.
Lẹ́yìn ààwẹ̀ àti àìsùn títí di ojúmọ́, Dáríúsì súré tete lọ sí ibi ihò náà. Dáníẹ́lì wà láàyè, a kò sì pa á lára! Ọbá hùwà padà lọ́gán. Ó mú kí a ju àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì àti ìdílé wọn sínú ihò kìnnìún gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san. Dáríúsì tún sọ ọ́ di mímọ̀ jákèjádò ilẹ̀ àkóso náà pé “ní gbogbo ìgbèríko ìjọba mi, kí àwọn ènìyàn kí ó máa wá rìrì, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run Dáníẹ́lì.”—Dáníẹ́lì 6:18-28.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Dáníẹ́lì jẹ́ àpẹẹrẹ dáradára ní ti ìṣòtítọ́. Kódà ọba, tí kò jọ́sìn Jèhófà pàápàá, kíyè sí i pé Dáníẹ́lì fi “ìdúró gbọn-in” ṣiṣẹ́ sìn Ín. (Dáníẹ́lì 6:17, 21, NW) Ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ Árámáíkì tí a túmọ̀ sí “ìdúró gbọn-in” ní pàtàkì túmọ̀ sí láti “máa yípo.” Ó túmọ̀ sí bíbá a nìṣó. Ẹ wo bí èyí ti ṣàpèjúwe ìwà títọ́ tí kò ṣe é bà jẹ́ tí Dáníẹ́lì ní sí Jèhófà dáradára tó!
Dáníẹ́lì mú ànímọ́ tí ń fi ìdúró gbọn-in hàn dàgbà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí a tó jù ú sínú ihò kìnnìún. Gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn ọ̀dọ́ ní Bábílónì, ó kọ̀ láti jẹ oúnjẹ tàbí mu ohun mímu tí Òfin Mósè kà léèwọ̀ tàbí tí ààtò ìsìn ìbọ̀rìṣà sọ di ẹlẹ́gbin. (Dáníẹ́lì 1:8) Lẹ́yìn náà, ó fi tìgboyàtìgboyà polongo ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run fún ọba àwọn ará Bábílónì, Nebukadinésárì. (Dáníẹ́lì 4:19-25) Ní kìkì wákàtí díẹ̀ ṣáájú ìṣubú Bábílónì, Dáníẹ́lì fi tìgboyàtìgboyà polongo ìdájọ́ Ọlọ́run fún Ọba Bẹliṣásárì. (Dáníẹ́lì 5:22-28) Nítorí náà, nígbà tí Dáníẹ́lì dojú kọ ihò kìnnìún, ó ń bá a nìṣó ní ipa ìṣòtítọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀.
Ìwọ pẹ̀lú lè fi ìdúró gbọn-in ṣiṣẹ́ sin Jèhófà. Ìwọ́ ha jẹ́ ọ̀dọ́ bí? Nígbà náà, gbégbèésẹ̀ nísinsìnyí láti mú ànímọ́ tí ń fi ìdúró gbọn-in hàn dàgbà nípa kíkọ ẹgbẹ́ búburú àti ìwà tí ń sọni dìbàjẹ́ ti ayé yìí. Bí o bá ti ń ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run fún àkókò kan, pa ipa ìfaradà oníṣòtítọ́ mọ́. Má ṣe juwọ́ sílẹ̀, nítorí pé àdánwò kọ̀ọ̀kan tí a ń dojú kọ ń fún wa ní àǹfààní láti fi han Jèhófà pé a pinnu láti fi ìdúró gbọn-in ṣiṣẹ́ sìn ín.—Fílípì 4:11-13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà “alákòóso” (tí ó túmọ̀ lówuuru sí “olùdáàbòbò Ìjọba”) ń tọ́ka sí gómìnà tí ọba Páṣíà yàn láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alákòóso gíga jù lọ lórí àgbègbè ìpínlẹ̀ kan. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà tí ó jẹ́ aṣojú fún ọba, òun ni ó ni ẹrù iṣẹ́ gbígba owó orí àti sísan owó òde sí ààfin ọba.