‘A Ń Fẹ́ Àwọn Aláìlábòsí’
ÀÌLÁBÒSÍ ṣọ̀wọ́n nínú ayé òde òní. Síbẹ̀, ó jẹ́ ohun pàtàkì kan tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristẹni. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘A dàníyàn láti máa mú ara wa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.’ (Hébérù 13:18) Èyí ni ohun tí Wilma, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Faenza, Ítálì, fẹ́ ṣe.
Ìwé agbéròyìnjáde náà, Il Resto del Carlino, ròyìn pé, nígbà tí ó rí pọ́ọ̀sì, tí ọ̀pọ̀ owó wà nínú rẹ̀, níwájú ilé ìtajà ńlá kan ní ìlú rẹ̀, ó mú un lọ fún àwọn ọlọ́pàá, “láìlọ́tìkọ̀ rárá,” kí wọ́n baà lè dá a pa dà fún ẹni tí ó ni ín.
Nígbà tí olórí ìlú gbọ́ nípa èyí, ó fi ìwé ìdúpẹ́ kékeré kan ránṣẹ́ sí Wilma lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ní orúkọ Ìlú wa, mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ rẹ fún ìgbésẹ̀ àtàtà tí o gbé. Faenza, ìlú wa olókìkí, ń fẹ́ àwọn ènìyàn rere, aláìlábòsí.”
Yálà iṣẹ́ rere di mímọ̀ tàbí kò di mímọ̀, a gbọ́dọ̀ máa gbìyànjú nígbà gbogbo láti jẹ́ aláìlábòsí. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti gbani níyànjú, “a ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó tọ́, kì í ṣe níwájú Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n níwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú.”—Kọ́ríńtì Kejì 8:21, The Jerusalem Bible.