Ǹjẹ́ O Lè Fi Ìyàtọ̀ Sáàárín Ohun Tí Ó Tọ́ àti Ohun Tí Kò tọ́?
“Mo pa ènìyàn bí 25. . . . Mo máa ń rántí rẹ̀ lóròòru, lójoojúmọ́. Mo máa ń lálàá burúkú. . . . Mo lè lọ síbì kan kí n rí ojú ẹnì kan tí yóò mú mi rántí àwọn ènìyàn tí mo ti pa. Ó hàn gbangba sí mi pé ó ń ṣẹlẹ̀ sí mi, bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ sí mi lónìí yìí, nísinsìnyí. . . . N kò lè dárí ji ara mi nítorí àwọn ohun tí mo ti ṣe.”—V.S.
“Wọ́n pàṣẹ fún mi láti wọ ibẹ̀, kí n sì pa àwọn ọ̀tá. . . . N kò rò ó wò pé ẹ̀dá ènìyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin àti ọmọdé ni àwọn ọ̀tá náà jẹ́. . . . Nígbà yẹn, èrò mi ni pé ohun tí wọ́n pa láṣẹ fún mi láti ṣe ni mo ṣe, àti pé n kò rò pé ohun tí mo ṣe yẹn kò tọ́, èrò tí mo ní yẹn kò sì tíì yí padà dòní.”—W.C.
NÍ March 16, 1968, àwọn ọkùnrin méjì tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ lókè lọ́wọ́ nínú ohun tí a óò wá dájọ́ pé ó jẹ́ ìwà ọ̀daràn bíburú jáì nígbà ogun. Àwọn àti àwọn sójà mìíràn wọ abúlé kékeré kan ní Vietnam, wọ́n sì pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn—títí kan àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé, àti àwọn arúgbó ọkùnrin. Àmọ́, wo ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ọ̀rọ̀ tí àwọn sójà méjì náà sọ. Ó hàn gbangba pé ohun tí sójà àkọ́kọ́ náà ṣe ti kó wàhálà bá a. Èkejì lérò pé ohun tí òun ṣe tọ́. Báwo ni ènìyàn méjì ṣe lè ronú lọ́nà yíyàtọ̀síra bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ pé ohun kan náà ni ó ṣẹlẹ̀ sí wọn?
Ìdáhùn sí ìbéèrè náà ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn—agbára tí Ọlọ́run fún wa, tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi òtítọ́ inú yẹ ara wa wò, kí a sì pinnu àwọn ìgbésẹ̀ àti èrò wa. Ẹ̀rí ọkàn ni èrò inú wa lọ́hùn-ún, tí ń jẹ́ kí a mọ ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́.
Nígbà tí àwọn kan bá fẹ́ ṣe ìpinnu, wọ́n máa ń gbé e karí òwe náà pé, “Ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ bá ní kí o ṣe.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn kì í fìgbà gbogbo ṣeé tẹ̀ lé. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fàyè gba àwọn ìwà ìkà bíburújáì, wọ́n tilẹ̀ ti hù ú níwà, ẹ̀rí ọkàn wọn kò sì yọ wọ́n lẹ́nu páàpáà. (Jòhánù 16:2; Ìṣe 8:1) Òǹkọ̀wé eléré ìtàn, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Samuel Butler, sọ nígbà kan rí pé, ẹ̀rí ọkàn “àwọn tí wọn kì í fẹ́ gbọ́ tirẹ̀ kì í pẹ́ kú.”
Báwo ni o ṣe lè gbára lé ẹ̀rí ọkàn rẹ? Ìdáhùn sí ìbéèrè náà fi púpọ̀ púpọ̀ sinmi lé bí a bá ṣe kọ́ ọ dáradára sí, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí yóò ṣe fi hàn.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwòrán ogun ló wà lókè: Fọ́tò U.S. Signal Corps