ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍRÀ 6-10
Àwọn Tó Ń Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn Ni Jèhófà Fẹ́
Ẹ́sírà ṣètò láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù
- Ẹ́sírà gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ Atasásítà Ọba kó lè pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú 
- Ọba “yọ̀ǹda gbogbo” ohun tí Ẹ́sírà “béèrè” láti fi kọ́ ilé Jèhófà, àwọn nǹkan bíi wúrà, fàdákà, àlìkámà, wáìnì, òróró, àti iyọ̀, ìṣirò gbogbo wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún [20] bílíọ̀nù náírà 
Ẹ́sírà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀
- Ìrìn àjò wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù máa nira 
- Ọ̀nà tó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà, ojú ọ̀nà yẹn sì tún léwu 
- Ìrìn àjò náà gbà tó oṣù mẹ́rin 
- Ó gba pé kí àwọn tó pa dà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ìtara fún ìjọsìn tòótọ́ àti ìgboyà 
ÀWỌN NǸKAN TÍ Ẹ́SÍRÀ KÓ DÁNÍ NI . . .
Wúrà àti fàdákà tó wúwo tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlá [513] àpò sìmẹ́ǹtì Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó akọ erin ńlá mẹ́ta!
ÌṢÒRO TÍ ÀWỌN TÓ PA DÀ KOJÚ . . .
Àwọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí, ojú ọjọ́ nínú aṣálẹ̀, àwọn ẹranko eléwu