MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní làwọn ọ̀dọ́ ní nínú ètò Jèhófà. Wo fídíò Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ kó o lè rí bí Cameron ṣe fi ọgbọ́n lo ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí. (Lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́.)
- Kí ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé Cameron? 
- Ìgbà wo ló ti pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, báwo ló sì ṣe ṣeé? 
- Báwo ló ṣe múra sílẹ̀ kó lè lọ sìn lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run? 
- Àwọn nǹkan wo ni Cameron fara dà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lórílẹ̀-èdè tó lọ? 
- Kí nìdí tó fi máa ṣàǹfààní láti sin Jèhófà níbi tí a kò tíì ṣiṣẹ́ sìn rí? 
- Àwọn ìbùkún wo ni Cameron rí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀? 
- Kí nìdí tí ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fi jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ? 
- Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì wo làwọn ọ̀dọ́ lè ní nínú ètò Jèhófà?