ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 12-13
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́ Lára Nehemáyà
Nehemáyà fìtara gbèjà ìjọsìn tòótọ́
- Élíáṣíbù àlùfáà àgbà jẹ́ kí Tobáyà tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ àti alátakò ní ipa burúkú lórí òun 
- Élíáṣíbù gba Tobáyà láàyè láti máa gbé nínú yàrá ìjẹun tó wà nínú tẹ́ńpìlì 
- Nehemáyà da gbogbo àga àti tábìlì Tobáyà síta, ó sọ inú gbọ̀ngàn náà di mímọ́, ó sì jẹ́ kó pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ 
- Nehemáyà túbọ̀ ń mú àwọn nǹkan tí kò mọ́ kúrò ní Jerúsálẹ́mù