ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 38-42
Inú Jèhófà Máa Ń Dùn Tá A Bá Gbàdúrà Fáwọn Ẹlòmíì
Jèhófà sọ pé kí Jóòbù gbàdúrà fún Élífásì, Bílídádì àti Sófár
- Jèhófà sọ fún Élífásì, Bílídádì àti Sófárì pé kí wọ́n lọ bá Jóòbù pé kó rú ẹbọ sísun fún wọn 
- Jèhófà fẹ́ kí Jóòbù gbàdúrà fún wọn 
- Jèhófà bù kún Jóòbù lẹ́yìn tó gbàdúrà fún wọn 
Jèhófà bù kún Jóòbù lọ́pọ̀lọpọ̀ torí ìgbàgbọ́ àti ìfaradà rẹ̀
- Jèhófà mú ìpọ́njú Jóòbù kúrò, ó sì jẹ́ kó ní ìlera pípé 
- Àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Jóòbù tù ú nínú lọ́nà tó yẹ torí gbogbo nǹkan tí ojú rẹ̀ ti rí 
- Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù ní ọrọ̀, ó fún un ní ìlọ́po méjì àwọn ohun tó pàdánù 
- Jóòbù àti ìyàwó rẹ̀ ní àwọn ọmọ mẹ́wàá míì 
- Jóòbù tún lo ogóje ọdún [140] míì láyé, ó sì wá rí ìran àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ mẹ́rin